Joh 6:25-40
Joh 6:25-40 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nigbati nwọn si ri i li apakeji okun nwọn wi fun u pe, Rabbi, nigbawo ni iwọ wá sihinyi? Jesu da wọn lohùn o si wipe, Lõtọ, lõtọ ni mo wi fun nyin, Ẹnyin nwá mi, ki iṣe nitoriti ẹnyin ri iṣẹ àmi, ṣugbọn nitori ẹnyin jẹ iṣu akara wọnni, ẹnyin si yó. Ẹ máṣe ṣiṣẹ fun onjẹ ti iṣegbé, ṣugbọn fun onjẹ ti iwà ti di ìye ainipẹkun, eyiti Ọmọ-enia yio fifun nyin: nitoripe on ni, ani Ọlọrun Baba ti fi edidi dí. Nigbana ni nwọn wi fun u pe, Kili awa o ha ṣe, ki a le ṣe iṣẹ Ọlọrun? Jesu dahùn o si wi fun wọn pe, Eyi ni iṣẹ Ọlọrun pe, ki ẹnyin ki o gbà ẹniti o rán gbọ́. Nigbana ni nwọn wi fun u pe, Iṣẹ ami kini iwọ nṣe, ki awa le ri, ki a si gbà ọ gbọ́? Iṣẹ kini iwọ ṣe? Awọn baba wa jẹ manna li aginjù; gẹgẹ bi a ti kọ ọ́ pe, O fi onjẹ fun wọn jẹ lati ọrun wá. Nigbana ni Jesu wi fun wọn pe, Lõtọ, lõtọ ni mo wi fun nyin, kì iṣe Mose li o fi onjẹ nì fun nyin lati ọrun wá; ṣugbọn Baba mi li o fi onjẹ otitọ nì fun nyin lati ọrun wá. Nitoripe onjẹ Ọlọrun li ẹniti o ti ọrun sọkalẹ wá, ti o si fi ìye fun araiye. Nigbana ni nwọn wi fun u pe, Oluwa, mã fun wa li onjẹ yi titi lai. Jesu wi fun wọn pe, Emi li onjẹ ìye: ẹnikẹni ti o ba tọ̀ mi wá, ebi kì yio pa a; ẹniti o ba si gbà mi gbọ́, orungbẹ kì yio gbẹ ẹ mọ́ lai. Sugbọn mo wi fun nyin pe, Ẹnyin ti ri mi, ẹ kò si gbagbọ́. Ohun gbogbo ti Baba fifun mi, yio tọ̀ mi wá; ẹniti o ba si tọ̀ mi wá, emi kì yio ta a nù, bi o ti wù ki o ri. Nitori emi sọkalẹ lati ọrun wá, ki iṣe lati mã ṣe ifẹ ti emi tikarami, bikoṣe ifẹ ti ẹniti o rán mi. Eyi si ni ifẹ Baba ti o rán mi, pe ohun gbogbo ti o fifun mi, ki emi ki o máṣe sọ ọkan nù ninu wọn, ṣugbọn ki emi ki o le ji wọn dide nikẹhin ọjọ. Eyi si ni ifẹ ẹniti o rán mi, pe ẹnikẹni ti o ba rí Ọmọ, ti o ba si gbà a gbọ́, ki o le ni iye ainipẹkun: Emi ó si jí i dide nikẹhin ọjọ.
Joh 6:25-40 Yoruba Bible (YCE)
Nígbà tí wọ́n rí i ní òdìkejì òkun, wọ́n bi í pé, “Olùkọ́ni, nígbà wo ni o ti dé ìhín?” Jesu dá wọn lóhùn pé, “Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé, kì í ṣe nítorí pé ẹ rí iṣẹ́ ìyanu mi ni ẹ ṣe ń wá mi, ṣugbọn nítorí ẹ jẹ oúnjẹ àjẹyó ni. Ẹ má ṣe làálàá nítorí oúnjẹ ti yóo bàjẹ́, ṣugbọn ẹ ṣiṣẹ́ fún oúnjẹ tí ọmọ eniyan yóo fun yín, tí yóo wà títí di ìyè ainipẹkun, nítorí ọmọ eniyan ni Ọlọrun Baba fún ní àṣẹ.” Wọ́n wá bi í pé, “Kí ni kí á ṣe kí á lè máa ṣe iṣẹ́ Ọlọrun?” Jesu dá wọn lóhùn pé, “Iṣẹ́ Ọlọrun ni pé kí ẹ gba ẹni tí ó rán gbọ́.” Wọ́n wá bi í pé, “Iṣẹ́ ìyanu wo ni ìwọ óo ṣe, tí a óo rí i, kí á lè gbà ọ́ gbọ́? Iṣẹ́ wo ni o óo ṣe? Àwọn baba wa jẹ mana ní aṣálẹ̀, gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ pé, ‘Ó fún wọn ní oúnjẹ láti ọ̀run wá jẹ.’ ” Jesu wí fún wọn pé, “Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé, kì í ṣe Mose ni ó fun yín ní oúnjẹ láti ọ̀run wá. Baba mi ni ó ń fun yín ní oúnjẹ láti ọ̀run wá; nítorí oúnjẹ Ọlọrun ni ẹni tí ó ń ti ọ̀run sọ̀kalẹ̀ wá, tí ó ń fi ìyè fún aráyé.” Wọ́n bá sọ fún un pé, “Alàgbà, máa fún wa ní oúnjẹ yìí nígbà gbogbo.” Jesu dá wọn lóhùn pé, “Èmi gan-an ni oúnjẹ tí ń fún eniyan ní ìyè, ẹni tí ó bá wá sọ́dọ̀ mi, ebi kò ní pa á, ẹni tí ó bá sì gbà mí gbọ́, òùngbẹ kò ní gbẹ ẹ́ laelae. Ṣugbọn mo wí fun yín pé ẹ̀yin ti rí mi, sibẹ ẹ kò gbàgbọ́. Gbogbo ẹni tí Baba ti fi fún mi yóo wá sọ́dọ̀ mi. Ẹnikẹ́ni tí ó bá wá sọ́dọ̀ mi, n kò ní ta á nù; nítorí pé mo sọ̀kalẹ̀ láti ọ̀run wá, kì í ṣe láti ṣe ìfẹ́ ti ara mi, bíkòṣe láti ṣe ìfẹ́ ẹni tí ó rán mi níṣẹ́. Èyí ni ìfẹ́ ẹni tí ó rán mi níṣẹ́, pé kí n má ṣe sọ ẹnikẹ́ni nù ninu àwọn tí ó fi fún mi, ṣugbọn kí n jí wọn dìde ní ọjọ́ ìkẹyìn. Nítorí ìfẹ́ Baba mi ni pé, kí ẹnikẹ́ni tí ó bá rí Ọmọ rẹ̀, tí ó bá gbà á gbọ́, lè ní ìyè ainipẹkun. Èmi fúnra mi yóo jí wọn dìde ní ọjọ́ ìkẹyìn.”
Joh 6:25-40 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nígbà tí wọ́n sì rí i ní apá kejì Òkun, wọ́n wí fún un pé, “Rabbi, nígbà wo ni ìwọ wá síhìn-ín yìí?” Jesu dá wọn lóhùn ó sì wí pé, “Lóòótọ́ lóòótọ́ ni mo wí fún yín. Ẹ̀yin ń wá mi, kì í ṣe nítorí tí ẹ̀yin rí iṣẹ́ ààmì, ṣùgbọ́n nítorí ẹ̀yin jẹ àjẹyó ìṣù àkàrà. Ẹ má ṣe ṣiṣẹ́ fún oúnjẹ tí ń ṣègbé, ṣùgbọ́n fún oúnjẹ tí ó wà títí di ayé àìnípẹ̀kun, èyí tí Ọmọ ènìyàn yóò fi fún yín: nítorí pé òun ni, àní Ọlọ́run Baba ti fi èdìdì dì í.” Nígbà náà ni wọ́n wí fún wọn pé, “Kín ni àwa ó ha ṣe, kí a lè ṣe iṣẹ́ Ọlọ́run?” Jesu dáhùn, ó sì wí fún wọn pé, “Èyí ni iṣẹ́ Ọlọ́run pé, kí ẹ̀yin gba ẹni tí ó rán an gbọ́.” Nígbà náà ni wọ́n wí fún wọn pé, “Iṣẹ́ ààmì kín ní ìwọ ń ṣe, tí àwa lè rí, kí a sì gbà ọ́ gbọ́? Iṣẹ́ kín ní ìwọ ṣe? Àwọn baba wa jẹ manna ní aginjù; gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ pé, ‘Ó fi oúnjẹ láti ọ̀run wá fún wọn jẹ.’ ” Nígbà náà ni Jesu wí fún wọn pé, “Lóòótọ́ lóòótọ́ ni mo wí fún yín, kì í ṣe Mose ni ó fi oúnjẹ fún yín láti ọ̀run wá; ṣùgbọ́n Baba mi ni ó fi oúnjẹ òtítọ́ náà fún yín láti ọ̀run wá. Nítorí pé oúnjẹ Ọlọ́run ni èyí tí ó ti ọ̀run sọ̀kalẹ̀ wá, tí ó sì fi ìyè fún aráyé.” Nígbà náà ni wọ́n wí fún un pé, “Olúwa, máa fún wa ní oúnjẹ yìí títí láé.” Jesu wí fún wọn pé, “Èmi ni oúnjẹ ìyè: ẹnikẹ́ni tí ó bá tọ̀ mí wá, ebi kì yóò pa á; ẹni tí ó bá sì gbà mí gbọ́, òǹgbẹ kì yóò gbẹ ẹ́ mọ́ láé. Ṣùgbọ́n mo wí fún yín pé, Ẹ̀yin ti rí mi, ẹ kò sì gbàgbọ́. Gbogbo èyí tí Baba fi fún mi, yóò tọ̀ mí wá; ẹni tí ó bá sì tọ̀ mí wá, èmi kì yóò tà á nù, bí ó tí wù kó rí. Nítorí èmi sọ̀kalẹ̀ láti ọ̀run wá, kì í ṣe láti máa ṣe ìfẹ́ ti èmi fúnra mi, bí kò ṣe ìfẹ́ ti ẹni tí ó rán mi. Èyí sì ni ìfẹ́ Baba tí ó rán mi pé ohun gbogbo tí o fi fún mi, kí èmi má ṣe sọ ọ̀kan nù nínú wọn, ṣùgbọ́n kí èmi lè jí wọn dìde níkẹyìn ọjọ́. Èyí sì ni ìfẹ́ ẹni tí ó rán mi, pé ẹnikẹ́ni tí ó bá wo ọmọ, tí ó bá sì gbà á gbọ́, kí ó lè ní ìyè àìnípẹ̀kun: Èmi ó sì jí i dìde níkẹyìn ọjọ́.”