Joh 6:1-6
Joh 6:1-6 Bibeli Mimọ (YBCV)
LẸHIN nkan wọnyi, Jesu kọja si apakeji okun Galili, ti iṣe okun Tiberia. Ọpọ ijọ enia si tọ̀ ọ lẹhin, nitoriti nwọn ri iṣẹ àmi rẹ̀, ti o nṣe lara awọn alaisàn. Jesu si gùn ori òke lọ, nibẹ̀ li o si gbé joko pẹlu awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀. Ajọ irekọja, ọdun awọn Ju, si sunmọ etile. Njẹ bi Jesu ti gbé oju rẹ̀ soke, ti o si ri ọ̀pọ enia wá sọdọ rẹ̀, o wi fun Filippi pe, Nibo li a o ti rà akara, ki awọn wọnyi le jẹ? O si sọ eyi lati dán a wò; nitoriti on tikararẹ̀ mọ̀ ohun ti on ó ṣe.
Joh 6:1-6 Yoruba Bible (YCE)
Lẹ́yìn èyí, Jesu lọ sí òdìkejì òkun Galili tí ó tún ń jẹ́ òkun Tiberiasi. Ọ̀pọ̀ eniyan ń tẹ̀lé e nítorí wọ́n rí iṣẹ́ ìyanu tí ó ń ṣe lára àwọn aláìsàn. Jesu bá gun orí òkè lọ, ó jókòó níbẹ̀ pẹlu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀. Ó fẹ́rẹ̀ tó àkókò Àjọ̀dún Ìrékọjá, tíí ṣe àjọ̀dún pataki láàrin àwọn Juu. Nígbà tí Jesu gbé ojú sókè, ó rí ọ̀pọ̀ eniyan tí ó wá sọ́dọ̀ rẹ̀, ó wá bi Filipi pé, “Níbo ni a ti lè ra oúnjẹ fún àwọn eniyan yìí láti jẹ?” Ó fi èyí wá Filipi lẹ́nu wò ni, nítorí òun fúnrarẹ̀ ti mọ ohun tí òun yóo ṣe.
Joh 6:1-6 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí, Jesu kọjá sí apá kejì Òkun Galili, tí í ṣe Òkun Tiberia. Ọ̀pọ̀ ìjọ ènìyàn sì tọ̀ ọ́ lẹ́yìn, nítorí tí wọ́n rí iṣẹ́ ààmì rẹ̀ tí ó ń ṣe lára àwọn aláìsàn. Jesu sì gun orí òkè lọ, níbẹ̀ ni ó sì gbé jókòó pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀. Àjọ ìrékọjá ọdún àwọn Júù sì súnmọ́ etílé. Ǹjẹ́ bí Jesu ti gbé ojú rẹ̀ sókè, tí ó sì rí ọ̀pọ̀ ènìyàn wá sọ́dọ̀ rẹ̀, ó wí fún Filipi pé, “Níbo ni a ó ti ra àkàrà, kí àwọn wọ̀nyí lè jẹ?” Ó sì sọ èyí láti dán an wò; nítorí tí òun fúnrarẹ̀ mọ ohun tí òun ó ṣe.