Joh 5:17-29

Joh 5:17-29 Bibeli Mimọ (YBCV)

Ṣugbọn Jesu da wọn lohùn wipe, Baba mi nṣiṣẹ titi di isisiyi, emi si nṣiṣẹ. Nitori eyi li awọn Ju tubọ nwá ọ̀na ati pa a, ki iṣe nitoripe o ba ọjọ isimi jẹ nikan ni, ṣugbọn o wi pẹlu pe, Baba on li Ọlọrun iṣe, o nmu ara rẹ̀ ba Ọlọrun dọgba. Nigbana ni Jesu dahùn, o si wi fun wọn pe, Lõtọ, lõtọ ni mo wi fun nyin, Ọmọ kò le ṣe ohunkohun fun ara rẹ̀, bikoṣe ohun ti o ba ri pe Baba nṣe: nitori ohunkohun ti o ba nṣe, wọnyi li Ọmọ si nṣe bẹ̃ gẹgẹ. Nitori Baba fẹràn Ọmọ, o si fi ohun gbogbo ti on tikararẹ̀ nṣe hàn a: on ó si fi iṣẹ ti o tobi ju wọnyi lọ hàn a, ki ẹnu ki o le yà nyin. Nitoripe gẹgẹ bi Baba ti njí okú dide, ti o si nsọ wọn di ãye; bẹ̃li Ọmọ si nsọ awọn ti o fẹ di ãye. Nitoripe Baba ki iṣe idajọ ẹnikẹni, ṣugbọn o ti fi gbogbo idajọ le Ọmọ lọwọ: Ki gbogbo enia ki o le mã fi ọlá fun Ọmọ gẹgẹ bi nwọn ti nfi ọlá fun Baba. Ẹniti kò ba fi ọlá fun Ọmọ, kò fi ọlá fun Baba ti o rán a. Lõtọ, lõtọ ni mo wi fun nyin, Ẹnikẹni ti o ba gbọ́ ọ̀rọ mi, ti o ba si gbà ẹniti o rán mi gbọ́, o ni iye ti kò nipẹkun, on kì yio si wá si idajọ; ṣugbọn o ti ré ikú kọja bọ si ìye. Lõtọ, lõtọ ni mo wi fun nyin, Wakati na mbọ̀, o si de tan nisisiyi, nigbati awọn okú yio gbọ́ ohùn Ọmọ Ọlọrun: awọn ti o ba gbọ yio si yè. Nitoripe gẹgẹ bi Baba ti ni iye ninu ara rẹ̀; gẹgẹ bẹ̃li o si fifun Ọmọ lati ni iye ninu ara rẹ̀; O si fun u li aṣẹ lati mã ṣe idajọ pẹlu, nitoriti on iṣe Ọmọ-enia. Ki eyi ki o máṣe yà nyin li ẹnu; nitoripe wakati mbọ̀, ninu eyiti gbogbo awọn ti o wà ni isà okú yio gbọ́ ohùn rẹ̀. Nwọn o si jade wá; awọn ti o ṣe rere, si ajinde ìye; awọn ti o si ṣe buburu, si ajinde idajọ.

Joh 5:17-29 Yoruba Bible (YCE)

Ṣugbọn Jesu dá wọn lóhùn pé, “Baba mi ń ṣiṣẹ́ títí di ìsinsìnyìí, èmi náà sì ń ṣiṣẹ́.” Nítorí èyí àwọn Juu túbọ̀ ń wá ọ̀nà láti pa á, nítorí kì í ṣe pé ó ba Ọjọ́ Ìsinmi jẹ́ nìkan ni, ṣugbọn ó pe Ọlọrun ní Baba rẹ̀, ó sọ ara rẹ̀ di ọ̀kan náà pẹlu Ọlọrun. Nígbà náà ni Jesu dá wọn lóhùn pé, “Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé, Ọmọ kò lè dá nǹkankan ṣe yàtọ̀ sí ohun tí ó bá rí tí Baba ń ṣe. Àwọn ohun tí Ọmọ rí pé Baba ń ṣe ni òun náà ń ṣe. Nítorí Baba fẹ́ràn Ọmọ rẹ̀, ó sì fi ohun gbogbo tí ó ń ṣe hàn án. Yóo tún fi àwọn iṣẹ́ tí ó tóbi jù wọnyi lọ hàn án, kí ẹnu lè yà yín. Nítorí bí Baba ti ń jí àwọn òkú dìde, tí ó ń sọ wọ́n di alààyè, bẹ́ẹ̀ gan-an ni, ẹnikẹ́ni tí Ọmọ bá fẹ́ ni ó ń sọ di alààyè. Nítorí Baba kò ṣe ìdájọ́ ẹnikẹ́ni, ṣugbọn ó ti fi gbogbo ìdájọ́ lé Ọmọ lọ́wọ́, kí gbogbo eniyan lè bu ọlá fún Ọmọ bí wọ́n ti ń bu ọlá fún Baba. Ẹni tí kò bá bu ọlá fún Ọmọ kò bu ọlá fún Baba tí ó rán an wá sí ayé. “Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé ẹni tí ó bá gbọ́ ọ̀rọ̀ mi, tí ó bá gba ẹni tí ó rán mi níṣẹ́ gbọ́, olúwarẹ̀ ní ìyè ainipẹkun, kò ní wá sí ìdájọ́, ṣugbọn ó ti ré ikú kọjá, ó sì ti bọ́ sinu ìyè. Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé àkókò ń bọ̀, ó tilẹ̀ dé tán báyìí, tí àwọn òkú yóo gbọ́ ohùn Ọmọ Ọlọrun, àwọn tí ó bá gbọ́ yóo yè. Nítorí bí Baba ti ní ìyè ninu ara rẹ̀, bẹ́ẹ̀ gan-an ni ó ti fún ọmọ ní agbára láti ní ìyè. Ó ti fún un ní àṣẹ láti ṣe ìdájọ́, nítorí òun ni Ọmọ-Eniyan. Ẹ má ṣe jẹ́ kí èyí yà yín lẹ́nu, nítorí àkókò ń bọ̀ nígbà tí gbogbo àwọn òkú tí ó wà ní ibojì yóo gbọ́ ohùn rẹ̀, tí wọn yóo sì jáde. Àwọn tí ó ti ṣe rere yóo jí dìde sí ìyè, àwọn tí ó ti ṣe ibi yóo jí dìde sí ìdálẹ́bi.

Joh 5:17-29 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Ṣùgbọ́n Jesu dá wọn lóhùn pé, “Baba mi ń ṣiṣẹ́ títí di ìsinsin yìí, èmi náà sì ń ṣiṣẹ́.” Nítorí èyí ni àwọn Júù túbọ̀ ń wá ọ̀nà láti pa á, kì í ṣe nítorí pé ó ba ọjọ́ ìsinmi jẹ́ nìkan ni, ṣùgbọ́n ó wí pẹ̀lú pé, Baba òun ni Ọlọ́run jẹ́, ó ń mú ara rẹ̀ bá Ọlọ́run dọ́gba. Nígbà náà ni Jesu dáhùn, ó sì wí fún wọn pé, “Lóòótọ́, lóòótọ́ ni mo wí fún yín, ọmọ kò lè ṣe ohunkóhun fún ara rẹ̀, bí kò ṣe ohun tí ó bá rí pé Baba ń ṣe: nítorí ohunkóhun tí baba bá ń ṣe, ìwọ̀nyí ni ọmọ náà sì ń ṣe pẹ̀lú. Nítorí Baba fẹ́ràn ọmọ, ó sì ti fi ohun gbogbo tí ó ń ṣe hàn án, òun yóò sì fi iṣẹ́ tí ó tóbi jù wọ̀nyí lọ hàn án, kí ẹnu lè yà yín. Nítorí pé gẹ́gẹ́ bí Baba ti ń jí òkú dìde, tí ó sì ń sọ wọ́n di alààyè: bẹ́ẹ̀ ni ọmọ ń sọ àwọn tí ó fẹ́ di alààyè pẹ̀lú. Nítorí pé Baba kì í ṣe ìdájọ́ ẹnikẹ́ni, ṣùgbọ́n ó ti fi gbogbo ìdájọ́ lé ọmọ lọ́wọ́: Kí gbogbo ènìyàn lè máa fi ọlá fún ọmọ gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti ń fi ọlá fún Baba. Ẹnikẹ́ni tí kò bá fi ọlá fún ọmọ, kò fi ọlá fún Baba tí ó ran an. “Lóòótọ́, lóòótọ́ ni mo wí fún yín, ẹnikẹ́ni tí ó bá gbọ́ ọ̀rọ̀ mi, tí ó bá sì gba ẹni tí ó rán mi gbọ́, ó ní ìyè tí kò nípẹ̀kun, òun kì yóò sì wá sí ìdájọ́; ṣùgbọ́n ó ti ré ikú kọjá bọ́ sí ìyè. Lóòótọ́, lóòótọ́ ni mo wí fún yín, wákàtí náà ń bọ̀, ó sì dé tán nísinsin yìí, nígbà tí àwọn òkú yóò gbọ́ ohùn ọmọ Ọlọ́run: àwọn tí ó bá gbọ́ yóò sì yè. Nítorí pé gẹ́gẹ́ bí Baba ti ní ìyè nínú ara rẹ̀; gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ ni ó sì fi fún ọmọ láti ní ìyè nínú ara rẹ̀; Ó sì fún un ní àṣẹ láti máa ṣe ìdájọ́ pẹ̀lú, nítorí tí òun jẹ́ ọmọ ènìyàn. “Kí èyí má ṣe yà yín lẹ́nu; nítorí pé wákàtí ń bọ̀, nínú èyí tí gbogbo àwọn tí ó wà ní ibojì yóò gbọ́ ohun rẹ̀. Wọn ó sì jáde wá; àwọn tí ó ṣe rere, sí àjíǹde ìyè; àwọn tí ó sì ṣe búburú sí àjíǹde ìdájọ́.