Joh 5:1-23

Joh 5:1-23 Bibeli Mimọ (YBCV)

LẸHIN nkan wọnyi ajọ awọn Ju kan kò; Jesu si gòke lọ si Jerusalemu. Adagun omi kan si wà ni Jerusalemu, leti bodè agutan, ti a npè ni Betesda li ède Heberu, ti o ni iloro marun. Ninu wọnyi li ọ̀pọ awọn abirùn enia gbé dubulẹ si, awọn afọju, arọ ati awọn gbigbẹ, nwọn si nduro dè rirú omi. Nitori angẹli a ma digbà sọkalẹ lọ sinu adagun na, a si ma rú omi: lẹhin igbati a ba ti rú omi na tan ẹnikẹni ti o ba kọ́ wọ̀ inu rẹ̀, a di alaradidá ninu arùnkárun ti o ni. Ọkunrin kan si wà nibẹ̀, ẹniti o wà ni ailera rẹ̀ li ọdún mejidilogoji. Bi Jesu ti ri i ni idubulẹ, ti o si mọ̀ pe, o pẹ ti o ti wà bẹ̃, o wi fun u pe, Iwọ fẹ ki a mu ọ larada bi? Abirùn na da a lohùn wipe, Ọgbẹni, emi kò li ẹni, ti iba gbé mi sinu adagun, nigbati a ba nrú omi na: bi emi ba ti mbọ̀ wá, ẹlomiran a sọkalẹ sinu rẹ̀ ṣiwaju mi. Jesu wi fun u pe, Dide, gbé akete rẹ, ki o si mã rin. Lọgan a si mu ọkunrin na larada, o si gbé akete rẹ̀, o si nrìn. Ọjọ na si jẹ ọjọ isimi. Nitorina awọn Ju wi fun ọkunrin na ti a mu larada pe, Ọjọ isimi li oni: kò tọ́ fun ọ lati gbé akete rẹ. O si da wọn lohùn wipe, Ẹniti o mu mi larada, on li o wi fun mi pe, Gbé akete rẹ, ki o si mã rìn. Nigbana ni nwọn bi i lẽre wipe, Ọkunrin wo li ẹniti o wi fun ọ pe, Gbé akete rẹ, ki o si mã rìn? Ẹniti a mu larada nã kò si mọ̀ ẹniti iṣe: nitori Jesu ti kuro nibẹ̀, nitori awọn enia pipọ wà nibẹ̀. Lẹhinna Jesu ri i ni tẹmpili o si wi fun u pe, Wo o, a mu ọ larada: máṣe dẹṣẹ mọ́, ki ohun ti o buru jù yi lọ ki o má bà ba ọ. Ọkunrin na lọ, o si sọ fun awọn Ju pe, Jesu li ẹniti o mu on larada. Nitori eyi li awọn Ju si nṣe inunibini si Jesu, nwọn si nwá ọ̀na ati pa a, nitoriti a nṣe nkan wọnyi li ọjọ isimi. Ṣugbọn Jesu da wọn lohùn wipe, Baba mi nṣiṣẹ titi di isisiyi, emi si nṣiṣẹ. Nitori eyi li awọn Ju tubọ nwá ọ̀na ati pa a, ki iṣe nitoripe o ba ọjọ isimi jẹ nikan ni, ṣugbọn o wi pẹlu pe, Baba on li Ọlọrun iṣe, o nmu ara rẹ̀ ba Ọlọrun dọgba. Nigbana ni Jesu dahùn, o si wi fun wọn pe, Lõtọ, lõtọ ni mo wi fun nyin, Ọmọ kò le ṣe ohunkohun fun ara rẹ̀, bikoṣe ohun ti o ba ri pe Baba nṣe: nitori ohunkohun ti o ba nṣe, wọnyi li Ọmọ si nṣe bẹ̃ gẹgẹ. Nitori Baba fẹràn Ọmọ, o si fi ohun gbogbo ti on tikararẹ̀ nṣe hàn a: on ó si fi iṣẹ ti o tobi ju wọnyi lọ hàn a, ki ẹnu ki o le yà nyin. Nitoripe gẹgẹ bi Baba ti njí okú dide, ti o si nsọ wọn di ãye; bẹ̃li Ọmọ si nsọ awọn ti o fẹ di ãye. Nitoripe Baba ki iṣe idajọ ẹnikẹni, ṣugbọn o ti fi gbogbo idajọ le Ọmọ lọwọ: Ki gbogbo enia ki o le mã fi ọlá fun Ọmọ gẹgẹ bi nwọn ti nfi ọlá fun Baba. Ẹniti kò ba fi ọlá fun Ọmọ, kò fi ọlá fun Baba ti o rán a.

Joh 5:1-23 Yoruba Bible (YCE)

Lẹ́yìn èyí, ó tó àkókò fún ọ̀kan ninu àjọ̀dún àwọn Juu: Jesu bá lọ sí Jerusalẹmu. Ẹnu ọ̀nà kan wà ní Jerusalẹmu tí wọn ń pè ní ẹnu ọ̀nà Aguntan. Adágún omi kan wà níbẹ̀ tí ń jẹ́ Betisata ní èdè Heberu. Adágún yìí ní ìloro marun-un tí wọn fi òrùlé bò. Níbẹ̀ ni ọpọlọpọ àwọn aláìsàn ti máa ń jókòó: àwọn afọ́jú, àwọn arọ, ati àwọn tí ó ní àrùn ẹ̀gbà. Wọn a máa retí ìgbà tí omi yóo rú pọ̀; [ nítorí angẹli Oluwa a máa wá lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan láti rú omi adágún náà pọ̀. Ẹnikẹ́ni tí ó bá kọ́kọ́ bọ́ sinu adágún náà lẹ́yìn tí omi náà bá ti rú pọ̀, àìsànkáìsàn tí ó lè máa ṣe é tẹ́lẹ̀, yóo san.] Ọkunrin kan wà níbẹ̀ tí ó ti ń ṣàìsàn fún ọdún mejidinlogoji. Nígbà tí Jesu rí i tí ó dùbúlẹ̀ níbẹ̀, tí ó sì mọ̀ pé ó ti pẹ́ tí ó ti wà níbẹ̀, ó bi í pé, “Ṣé o fẹ́ ìmúláradá?” Aláìsàn náà dáhùn pé, “Alàgbà, n kò ní ẹni tí yóo gbé mi sinu adágún nígbà tí omi bá rú pọ̀, nígbà tí n óo bá fi dé ibẹ̀, ẹlòmíràn á ti wọ inú omi ṣiwaju mi.” Jesu wí fún un pé, “Dìde, ká ẹní rẹ, kí o máa rìn.” Lẹsẹkẹsẹ ara ọkunrin náà dá, ó ká ẹni rẹ̀, ó bá ń rìn. Ọjọ́ náà jẹ́ Ọjọ́ Ìsinmi. Àwọn Juu sọ fún ọkunrin tí ara rẹ̀ ti dá yìí pé, “Ọjọ́ Ìsinmi ni òní! Èèwọ̀ ni pé kí o ru ẹní rẹ!” Ó dá wọn lóhùn pé, “Ẹni tí ó mú mi lára dá ni ó sọ pé kí n ká ẹní mi, kí n máa rìn.” Wọ́n bi í pé, “Ta ni ẹni náà tí ó sọ fún ọ pé kí o ru ẹni, kí o máa rìn?” Ṣugbọn ọkunrin náà tí Jesu wòsàn kò mọ ẹni tí ó wo òun sàn, nítorí pé eniyan pọ̀ níbẹ̀, ati pé Jesu ti yẹra kúrò níbẹ̀. Lẹ́yìn èyí, Jesu rí ọkunrin náà ninu Tẹmpili, ó wí fún un pé, “O rí i pé ara rẹ ti dá nisinsinyii, má dẹ́ṣẹ̀ mọ́ kí ohun tí ó burú ju èyí lọ má baà bá ọ.” Ọkunrin náà pada lọ sọ fún àwọn Juu pé, Jesu ni ẹni tí ó wo òun sàn. Nítorí èyí àwọn Juu dìtẹ̀ sí Jesu, nítorí ó ń ṣe nǹkan wọnyi ní Ọjọ́ Ìsinmi. Ṣugbọn Jesu dá wọn lóhùn pé, “Baba mi ń ṣiṣẹ́ títí di ìsinsìnyìí, èmi náà sì ń ṣiṣẹ́.” Nítorí èyí àwọn Juu túbọ̀ ń wá ọ̀nà láti pa á, nítorí kì í ṣe pé ó ba Ọjọ́ Ìsinmi jẹ́ nìkan ni, ṣugbọn ó pe Ọlọrun ní Baba rẹ̀, ó sọ ara rẹ̀ di ọ̀kan náà pẹlu Ọlọrun. Nígbà náà ni Jesu dá wọn lóhùn pé, “Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé, Ọmọ kò lè dá nǹkankan ṣe yàtọ̀ sí ohun tí ó bá rí tí Baba ń ṣe. Àwọn ohun tí Ọmọ rí pé Baba ń ṣe ni òun náà ń ṣe. Nítorí Baba fẹ́ràn Ọmọ rẹ̀, ó sì fi ohun gbogbo tí ó ń ṣe hàn án. Yóo tún fi àwọn iṣẹ́ tí ó tóbi jù wọnyi lọ hàn án, kí ẹnu lè yà yín. Nítorí bí Baba ti ń jí àwọn òkú dìde, tí ó ń sọ wọ́n di alààyè, bẹ́ẹ̀ gan-an ni, ẹnikẹ́ni tí Ọmọ bá fẹ́ ni ó ń sọ di alààyè. Nítorí Baba kò ṣe ìdájọ́ ẹnikẹ́ni, ṣugbọn ó ti fi gbogbo ìdájọ́ lé Ọmọ lọ́wọ́, kí gbogbo eniyan lè bu ọlá fún Ọmọ bí wọ́n ti ń bu ọlá fún Baba. Ẹni tí kò bá bu ọlá fún Ọmọ kò bu ọlá fún Baba tí ó rán an wá sí ayé.

Joh 5:1-23 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí, àjọ àwọn Júù kan kò; Jesu sì gòkè lọ sí Jerusalẹmu. Adágún omi kan sì wà ní Jerusalẹmu, létí bodè àgùntàn, tí a ń pè ní Betisaida ní èdè Heberu, tí ó ní ẹnu-ọ̀nà márùn-ún. Ní ẹ̀gbẹ́ odò yìí ni ọ̀pọ̀ àwọn abirùn ènìyàn máa ń gbé dùbúlẹ̀ sí, àwọn afọ́jú, arọ àti aláàrùn ẹ̀gbà, wọ́n sì ń dúró de rírú omi. Nítorí angẹli a máa sọ̀kalẹ̀ lọ sínú adágún náà, a sì máa rú omi rẹ̀: lẹ́yìn ìgbà tí ó bá ti rú omi náà tan ẹnikẹ́ni tí ó bá kọ́kọ́ wọ inú rẹ̀ a di alára dídá kúrò nínú ààrùnkárùn tí ó ní. Ọkùnrin kan wà níbẹ̀, ẹni tí ó tí wà ní àìlera fún ọdún méjì-dínlógójì. Bí Jesu ti rí i ní ìdùbúlẹ̀, tí ó sì mọ̀ pé ó pẹ́ tí ó ti wà bẹ́ẹ̀, ó wí fún un pé, “Ìwọ fẹ́ kí a mú ọ láradá bí?” Abirùn náà dá a lóhùn wí pé, “Arákùnrin, èmi kò ní ẹni tí ìbá gbé mi sínú adágún, nígbà tí a bá ń rú omi náà: bí èmi bá ti ń bọ̀ wá, ẹlòmíràn a sọ̀kalẹ̀ sínú rẹ̀ síwájú mi.” Jesu wí fún un pé, “Dìde, gbé àkéte rẹ, kí o sì máa rìn.” Lọ́gán, a sì mú ọkùnrin náà láradá, ó sì gbé àkéte rẹ̀, ó sì ń rìn. Ọjọ́ náà sì jẹ́ ọjọ́ ìsinmi. Nítorí náà àwọn Júù wí fún ọkùnrin náà tí a mú láradá pé, “Ọjọ́ ìsinmi ni òní; kò tọ́ fún ọ láti gbé àkéte rẹ.” Ó sì dá wọn lóhùn wí pé, “Ẹni tí ó mú mi láradá, ni ó wí fún mi pé, ‘Gbé àkéte rẹ, kí o sì máa rìn.’ ” Nígbà náà ni wọ́n bi í lérè wí pé, “Ọkùnrin wo ni ẹni tí ó wí fún ọ pé gbé àkéte rẹ, kí o sì máa rìn?” Ẹni tí a mú láradá náà kò sì mọ̀ ẹni tí ó jẹ́ nítorí Jesu ti kúrò níbẹ̀, àwọn ènìyàn púpọ̀ wà níbẹ̀. Lẹ́yìn náà, Jesu rí i nínú tẹmpili ó sì wí fún un pé, “Wò ó, a mú ọ láradá: má ṣe dẹ́ṣẹ̀ mọ́, kí ohun tí ó burú ju èyí lọ má ba à bá ọ!” Ọkùnrin náà lọ, ó sì sọ fún àwọn Júù pé, Jesu ni ẹni tí ó mú òun láradá. Nítorí èyí ni àwọn Júù ṣe inúnibíni sí Jesu, wọ́n sì ń wá ọ̀nà láti pa á, nítorí tí o ń ṣe nǹkan wọ̀nyí ní ọjọ́ ìsinmi. Ṣùgbọ́n Jesu dá wọn lóhùn pé, “Baba mi ń ṣiṣẹ́ títí di ìsinsin yìí, èmi náà sì ń ṣiṣẹ́.” Nítorí èyí ni àwọn Júù túbọ̀ ń wá ọ̀nà láti pa á, kì í ṣe nítorí pé ó ba ọjọ́ ìsinmi jẹ́ nìkan ni, ṣùgbọ́n ó wí pẹ̀lú pé, Baba òun ni Ọlọ́run jẹ́, ó ń mú ara rẹ̀ bá Ọlọ́run dọ́gba. Nígbà náà ni Jesu dáhùn, ó sì wí fún wọn pé, “Lóòótọ́, lóòótọ́ ni mo wí fún yín, ọmọ kò lè ṣe ohunkóhun fún ara rẹ̀, bí kò ṣe ohun tí ó bá rí pé Baba ń ṣe: nítorí ohunkóhun tí baba bá ń ṣe, ìwọ̀nyí ni ọmọ náà sì ń ṣe pẹ̀lú. Nítorí Baba fẹ́ràn ọmọ, ó sì ti fi ohun gbogbo tí ó ń ṣe hàn án, òun yóò sì fi iṣẹ́ tí ó tóbi jù wọ̀nyí lọ hàn án, kí ẹnu lè yà yín. Nítorí pé gẹ́gẹ́ bí Baba ti ń jí òkú dìde, tí ó sì ń sọ wọ́n di alààyè: bẹ́ẹ̀ ni ọmọ ń sọ àwọn tí ó fẹ́ di alààyè pẹ̀lú. Nítorí pé Baba kì í ṣe ìdájọ́ ẹnikẹ́ni, ṣùgbọ́n ó ti fi gbogbo ìdájọ́ lé ọmọ lọ́wọ́: Kí gbogbo ènìyàn lè máa fi ọlá fún ọmọ gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti ń fi ọlá fún Baba. Ẹnikẹ́ni tí kò bá fi ọlá fún ọmọ, kò fi ọlá fún Baba tí ó ran an.