Joh 4:32-34
Joh 4:32-34 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ṣugbọn o wi fun wọn pe, Emi li onjẹ lati jẹ, ti ẹnyin kò mọ̀. Nitorina li awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ mbi ara wọn lère wipe, Ẹnikan mú onjẹ fun u wá lati jẹ bi? Jesu wi fun wọn pe, Onjẹ mi ni lati ṣe ifẹ ẹniti o rán mi, ati lati pari iṣẹ rẹ̀.
Joh 4:32-34 Yoruba Bible (YCE)
Ṣugbọn ó dá wọn lóhùn pé, “Mo ní oúnjẹ láti jẹ tí ẹ̀yin kò mọ̀ nípa rẹ̀.” Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí bèèrè láàrin ara wọn pé, “Àbí ẹnìkan ti gbé oúnjẹ wá fún un ni?” Jesu wí fún wọn pé, “Ní tèmi, oúnjẹ mi ni láti ṣe ìfẹ́ ẹni tí ó rán mi níṣẹ́ ati láti parí iṣẹ́ tí ó fún mi ṣe.
Joh 4:32-34 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ṣùgbọ́n ó wí fún wọn pé, “Èmi ní oúnjẹ láti jẹ, tí ẹ̀yin kò mọ̀.” Nítorí náà ni àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ ń bi ara wọn lérè wí pé, “Ẹnìkan mú oúnjẹ fún un wá láti jẹ bí?” Jesu wí fún wọn pé, “Oúnjẹ mi ni láti ṣe ìfẹ́ ẹni tí ó rán mi, àti láti parí iṣẹ́ rẹ̀.