Joh 4:27-38

Joh 4:27-38 Yoruba Bible (YCE)

Ní àkókò yìí ni àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ dé. Ẹnu yà wọ́n pé obinrin ni ó ń bá sọ̀rọ̀. Ṣugbọn ẹnikẹ́ni ninu wọn kò bi obinrin náà pé kí ni ó ń wá? Bẹ́ẹ̀ ni wọn kò bi òun náà pé kí ló dé tí ó fi ń bá obinrin sọ̀rọ̀? Obinrin náà fi ìkòkò omi rẹ̀ sílẹ̀, ó lọ sí ààrin ìlú, ó sọ fún àwọn eniyan pé, “Ẹ wá wo ọkunrin tí ó sọ gbogbo ohun tí mo ti ṣe fún mi. Ǹjẹ́ Mesaya tí à ń retí kọ́?” Wọ́n bá jáde láti inú ìlú lọ sọ́dọ̀ Jesu. Lẹ́yìn tí obinrin náà ti lọ sí ààrin ìlú, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jesu ń bẹ̀ ẹ́ pé, “Rabi, jẹun.” Ṣugbọn ó dá wọn lóhùn pé, “Mo ní oúnjẹ láti jẹ tí ẹ̀yin kò mọ̀ nípa rẹ̀.” Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí bèèrè láàrin ara wọn pé, “Àbí ẹnìkan ti gbé oúnjẹ wá fún un ni?” Jesu wí fún wọn pé, “Ní tèmi, oúnjẹ mi ni láti ṣe ìfẹ́ ẹni tí ó rán mi níṣẹ́ ati láti parí iṣẹ́ tí ó fún mi ṣe. Ṣé ẹ máa ń sọ pé, ‘Ìkórè ku oṣù mẹrin.’ Mo sọ fun yín, ẹ gbé ojú yín sókè kí ẹ sì rí i bí oko ti pọ́n fun ìkórè. Ẹni tí ń kórè a máa rí èrè gbà, ó ń kó irè jọ sí ìyè ainipẹkun, kí inú ẹni tí ń fúnrúgbìn ati ti ẹni tí ń kórè lè jọ máa dùn pọ̀. Òtítọ́ ni ọ̀rọ̀ yìí pé, ‘Ọ̀tọ̀ ni ẹni tí ń fúnrúgbìn, ọ̀tọ̀ ni ẹni tí ń kórè.’ Mo ran yín láti kórè níbi tí ẹ kò ti ṣiṣẹ́ ọ̀gbìn. Àwọn ẹnìkan ti ṣiṣẹ́, ẹ̀yin wá ń jèrè iṣẹ́ wọn.”

Joh 4:27-38 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Lákokò yí ni àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ dé, ẹnu sì yà wọ́n pé ó ń bá obìnrin sọ̀rọ̀: ṣùgbọ́n kò sí ẹnìkan tí ó wí pé, “Kí ni ìwọ ń wá?” tàbí “Èéṣe tí ìwọ fi ń bá a sọ̀rọ̀?” Nígbà náà ni obìnrin náà fi ládugbó rẹ̀ sílẹ̀, ó sì mú ọ̀nà rẹ̀ pọ̀n lọ sí ìlú, ó sì wí fún àwọn ènìyàn pé, “Ẹ wá wò ọkùnrin kan, ẹni tí ó sọ ohun gbogbo tí mo ti ṣe rí fún mi: èyí ha lè jẹ́ Kristi náà?” Nígbà náà ni wọ́n ti ìlú jáde, wọ́n sì tọ̀ ọ́ wá. Láàrín èyí, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ ń rọ̀ ọ́ wí pé, “Rabbi, jẹun.” Ṣùgbọ́n ó wí fún wọn pé, “Èmi ní oúnjẹ láti jẹ, tí ẹ̀yin kò mọ̀.” Nítorí náà ni àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ ń bi ara wọn lérè wí pé, “Ẹnìkan mú oúnjẹ fún un wá láti jẹ bí?” Jesu wí fún wọn pé, “Oúnjẹ mi ni láti ṣe ìfẹ́ ẹni tí ó rán mi, àti láti parí iṣẹ́ rẹ̀. Ẹ̀yin kò ha wí pé, ‘Ó ku oṣù mẹ́rin, ìkórè yóò sì dé?’ Wò ó, mo wí fún un yín, Ẹ ṣí ojú yín sókè, kí ẹ sì wo oko; nítorí tí wọn ti pọ́n fún ìkórè. Kódà báyìí, ẹni tí ó ń kórè ń gba owó ọ̀yà rẹ̀, ó si ń kó èso jọ sí ìyè àìnípẹ̀kun: kí ẹni tí ó ń fúnrúgbìn àti ẹni tí ń kórè lè jọ máa yọ̀ pọ̀. Nítorí nínú èyí ni ọ̀rọ̀ náà fi jẹ́ òtítọ́: Ẹnìkan ni ó fúnrúgbìn, ẹlòmíràn ni ó sì ń kórè jọ. Mo rán yín lọ kórè ohun tí ẹ kò ṣiṣẹ́ fún. Àwọn ẹlòmíràn ti ṣiṣẹ́, ẹ̀yin sì kórè èrè làálàá wọn.”