Joh 4:27-30
Joh 4:27-30 Bibeli Mimọ (YBCV)
Lori eyi li awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ de, ẹnu si yà wọn, pe o mba obinrin sọ̀rọ: ṣugbọn kò si ẹnikan ti o wipe, Kini iwọ nwá? tabi, Ẽṣe ti iwọ fi mba a sọ̀rọ? Nigbana li obinrin na fi ladugbo rẹ̀ silẹ, o si mu ọ̀na rẹ̀ pọ̀n lọ si ilu, o si wi fun awọn enia pe, Ẹ wá wò ọkunrin kan, ẹniti o sọ ohun gbogbo ti mo ti ṣe ri fun mi: eyi ha le jẹ Kristi na? Nigbana ni nwọn ti ilu jade, nwọn si tọ̀ ọ wá.
Joh 4:27-30 Yoruba Bible (YCE)
Ní àkókò yìí ni àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ dé. Ẹnu yà wọ́n pé obinrin ni ó ń bá sọ̀rọ̀. Ṣugbọn ẹnikẹ́ni ninu wọn kò bi obinrin náà pé kí ni ó ń wá? Bẹ́ẹ̀ ni wọn kò bi òun náà pé kí ló dé tí ó fi ń bá obinrin sọ̀rọ̀? Obinrin náà fi ìkòkò omi rẹ̀ sílẹ̀, ó lọ sí ààrin ìlú, ó sọ fún àwọn eniyan pé, “Ẹ wá wo ọkunrin tí ó sọ gbogbo ohun tí mo ti ṣe fún mi. Ǹjẹ́ Mesaya tí à ń retí kọ́?” Wọ́n bá jáde láti inú ìlú lọ sọ́dọ̀ Jesu.
Joh 4:27-30 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Lákokò yí ni àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ dé, ẹnu sì yà wọ́n pé ó ń bá obìnrin sọ̀rọ̀: ṣùgbọ́n kò sí ẹnìkan tí ó wí pé, “Kí ni ìwọ ń wá?” tàbí “Èéṣe tí ìwọ fi ń bá a sọ̀rọ̀?” Nígbà náà ni obìnrin náà fi ládugbó rẹ̀ sílẹ̀, ó sì mú ọ̀nà rẹ̀ pọ̀n lọ sí ìlú, ó sì wí fún àwọn ènìyàn pé, “Ẹ wá wò ọkùnrin kan, ẹni tí ó sọ ohun gbogbo tí mo ti ṣe rí fún mi: èyí ha lè jẹ́ Kristi náà?” Nígbà náà ni wọ́n ti ìlú jáde, wọ́n sì tọ̀ ọ́ wá.