Joh 4:23-25
Joh 4:23-25 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ṣugbọn wakati mbọ̀, o si de tan nisisiyi, nigbati awọn olusin tõtọ yio ma sìn Baba li ẹmí ati li otitọ: nitori irú wọn ni Baba nwá ki o ma sìn on. Ẹmí li Ọlọrun: awọn ẹniti nsìn i ko le ṣe alaisìn i li ẹmí ati li otitọ. Obinrin na wi fun u pe, Mo mọ̀ pe Messia mbọ̀ wá, ti a npè ni Kristi: nigbati on ba de, yio sọ ohun gbogbo fun wa.
Joh 4:23-25 Yoruba Bible (YCE)
Ṣugbọn àkókò ń bọ̀, ó tilẹ̀ dé tán báyìí, nígbà tí àwọn tí ń jọ́sìn tòótọ́ yóo máa sin Baba ní ẹ̀mí ati ní òtítọ́, nítorí irú àwọn bẹ́ẹ̀ ni Baba ń wá kí wọ́n máa sin òun. Ẹ̀mí ni Ọlọrun, àwọn tí ó bá ń sìn ín níláti sìn ín ní ẹ̀mí ati ní òtítọ́.” Obinrin náà sọ fún un pé, “Mo mọ̀ pé Mesaya, tí ó ń jẹ́ Kristi, ń bọ̀. Nígbà tí ó bá dé, yóo fi ohun gbogbo hàn wá.”
Joh 4:23-25 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ṣùgbọ́n àkókò ń bọ̀, ó sì dé tán nísinsin yìí, nígbà tí àwọn olùsìn tòótọ́ yóò máa sin Baba ní Ẹ̀mí àti ní òtítọ́: nítorí irú wọn ni Baba ń wá kí ó máa sin òun. Ẹ̀mí ni Ọlọ́run: àwọn ẹni tí ń sìn ín kò lè ṣe aláìsìn ín ní Ẹ̀mí àti ní òtítọ́.” Obìnrin náà wí fún un pé, mo mọ̀ pé, “Messia ń bọ̀ wá, tí a ń pè ní Kristi: Nígbà tí Òun bá dé, yóò sọ ohun gbogbo fún wa.”