Joh 4:16-26
Joh 4:16-26 Bibeli Mimọ (YBCV)
Jesu wi fun u pe, Lọ ipè ọkọ rẹ, ki o si wá si ihinyi. Obinrin na dahùn, o si wi fun u pe, Emi kò li ọkọ. Jesu wi fun u pe, Iwọ wi rere pe, emi kò li ọkọ: Nitoriti iwọ ti li ọkọ marun ri; ẹniti iwọ si ni nisisiyi kì iṣe ọkọ rẹ; iwọ sọ otitọ li eyini. Obinrin na wi fun u pe, Ọgbẹni, mo woye pe, woli ni iwọ iṣe. Awọn baba wa sìn lori òke yi; ẹnyin si wipe, Jerusalemu ni ibi ti o yẹ ti a ba ma sìn. Jesu wi fun u pe, Gbà mi gbọ́, obinrin yi, wakati na mbọ̀, nigbati kì yio ṣe lori òke yi, tabi Jerusalemu, li ẹnyin o ma sìn Baba. Ẹnyin nsìn ohun ti ẹnyin kò mọ̀: awa nsìn ohun ti awa mọ̀: nitori igbala ti ọdọ awọn Ju wá. Ṣugbọn wakati mbọ̀, o si de tan nisisiyi, nigbati awọn olusin tõtọ yio ma sìn Baba li ẹmí ati li otitọ: nitori irú wọn ni Baba nwá ki o ma sìn on. Ẹmí li Ọlọrun: awọn ẹniti nsìn i ko le ṣe alaisìn i li ẹmí ati li otitọ. Obinrin na wi fun u pe, Mo mọ̀ pe Messia mbọ̀ wá, ti a npè ni Kristi: nigbati on ba de, yio sọ ohun gbogbo fun wa. Jesu wi fun u pe, Emi ẹniti mba ọ sọ̀rọ yi li on.
Joh 4:16-26 Yoruba Bible (YCE)
Jesu wí fún un pé, “Lọ pe ọkọ rẹ wá ná.” Obinrin náà dáhùn pé, “Èmi kò ní ọkọ.” Jesu wí fún un pé, “O wí ire pé o kò ní ọkọ, nítorí o ti ní ọkọ marun-un rí, ẹni tí o wà lọ́dọ̀ rẹ̀ nisinsinyii kì í sì í ṣe ọkọ rẹ. Òtítọ́ ni o sọ.” Obinrin náà sọ fún un pé, “Alàgbà, mo wòye pé wolii ni ọ́. Ní orí òkè tí ó wà lọ́hùn-ún yìí ni àwọn baba wa ń sin Ọlọrun, ṣugbọn ẹ̀yin wí pé Jerusalẹmu ni ibi tí a níláti máa sìn ín.” Jesu wí fún un pé, “Arabinrin, gbà mí gbọ́! Àkókò ń bọ̀ tí ó jẹ́ pé, ati ní orí òkè yìí ni, ati ní Jerusalẹmu ni, kò ní sí ibi tí ẹ óo ti máa sin Baba mọ́. Ẹ̀yin ará Samaria kò mọ ẹni tí ẹ̀ ń sìn. Àwa Juu mọ ẹni tí à ń sìn, nítorí láti ọ̀dọ̀ wa ni ìgbàlà ti wá. Ṣugbọn àkókò ń bọ̀, ó tilẹ̀ dé tán báyìí, nígbà tí àwọn tí ń jọ́sìn tòótọ́ yóo máa sin Baba ní ẹ̀mí ati ní òtítọ́, nítorí irú àwọn bẹ́ẹ̀ ni Baba ń wá kí wọ́n máa sin òun. Ẹ̀mí ni Ọlọrun, àwọn tí ó bá ń sìn ín níláti sìn ín ní ẹ̀mí ati ní òtítọ́.” Obinrin náà sọ fún un pé, “Mo mọ̀ pé Mesaya, tí ó ń jẹ́ Kristi, ń bọ̀. Nígbà tí ó bá dé, yóo fi ohun gbogbo hàn wá.” Jesu wí fún un pé, “Èmi tí mò ń bá ọ sọ̀rọ̀ yìí ni Mesaya náà.”
Joh 4:16-26 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Jesu wí fún un pé, “Lọ pe ọkọ rẹ, kí ó sì padà wá sí ìhín yìí.” Obìnrin náà dáhùn, ó sì wí fún un pé, “Èmi kò ní ọkọ.” Jesu wí fún un pé, “Ìwọ́ dáhùn dáradára pé, èmi kò ní ọkọ: Nítorí tí ìwọ ti ní ọkọ márùn-ún rí; ọkùnrin tí ìwọ sì ní báyìí kì í ṣe ọkọ rẹ. Ohun tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ tán yìí, òtítọ́ ni.” Obìnrin náà wí fún un pé, “Alàgbà, mo wòye pé, wòlíì ni ìwọ ń ṣe. Àwọn baba wa sìn lórí òkè yìí; ẹ̀yin sì wí pé, Jerusalẹmu ni ibi tí ó yẹ tí à bá ti máa sìn.” Jesu wí fún un pé, “Gbà mí gbọ́ obìnrin yìí, àkókò náà ń bọ̀, nígbà tí kì yóò ṣe lórí òkè yìí tàbí ní Jerusalẹmu ni ẹ̀yin ó máa sin Baba. Ẹ̀yin ń sin ohun tí ẹ̀yin kò mọ̀: àwa ń sin ohun tí àwa mọ̀: nítorí ìgbàlà ti ọ̀dọ̀ àwọn Júù wá. Ṣùgbọ́n àkókò ń bọ̀, ó sì dé tán nísinsin yìí, nígbà tí àwọn olùsìn tòótọ́ yóò máa sin Baba ní Ẹ̀mí àti ní òtítọ́: nítorí irú wọn ni Baba ń wá kí ó máa sin òun. Ẹ̀mí ni Ọlọ́run: àwọn ẹni tí ń sìn ín kò lè ṣe aláìsìn ín ní Ẹ̀mí àti ní òtítọ́.” Obìnrin náà wí fún un pé, mo mọ̀ pé, “Messia ń bọ̀ wá, tí a ń pè ní Kristi: Nígbà tí Òun bá dé, yóò sọ ohun gbogbo fún wa.” Jesu sọ ọ́ di mí mọ̀ fún un pé, “Èmi ẹni tí ń bá ọ sọ̀rọ̀ yìí ni Òun.”