Joh 4:15-19
Joh 4:15-19 Bibeli Mimọ (YBCV)
Obinrin na si wi fun u pe, Ọgbẹni, fun mi li omi yi, ki orùngbẹ ki o màṣe gbẹ mi, ki emi ki o má si wá fà omi nihin. Jesu wi fun u pe, Lọ ipè ọkọ rẹ, ki o si wá si ihinyi. Obinrin na dahùn, o si wi fun u pe, Emi kò li ọkọ. Jesu wi fun u pe, Iwọ wi rere pe, emi kò li ọkọ: Nitoriti iwọ ti li ọkọ marun ri; ẹniti iwọ si ni nisisiyi kì iṣe ọkọ rẹ; iwọ sọ otitọ li eyini. Obinrin na wi fun u pe, Ọgbẹni, mo woye pe, woli ni iwọ iṣe.
Joh 4:15-19 Yoruba Bible (YCE)
Obinrin náà sọ fún un pé, “Alàgbà, fún mi ní omi yìí kí òùngbẹ má baà gbẹ mí mọ́, kí n má baà tún wá pọn omi níhìn-ín mọ́.” Jesu wí fún un pé, “Lọ pe ọkọ rẹ wá ná.” Obinrin náà dáhùn pé, “Èmi kò ní ọkọ.” Jesu wí fún un pé, “O wí ire pé o kò ní ọkọ, nítorí o ti ní ọkọ marun-un rí, ẹni tí o wà lọ́dọ̀ rẹ̀ nisinsinyii kì í sì í ṣe ọkọ rẹ. Òtítọ́ ni o sọ.” Obinrin náà sọ fún un pé, “Alàgbà, mo wòye pé wolii ni ọ́.
Joh 4:15-19 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Obìnrin náà sì wí fún u pé, “Alàgbà, fún mi ní omi yìí, kí òǹgbẹ kí ó má ṣe gbẹ mí, kí èmi kí ó má sì wá fa omi níbí mọ́.” Jesu wí fún un pé, “Lọ pe ọkọ rẹ, kí ó sì padà wá sí ìhín yìí.” Obìnrin náà dáhùn, ó sì wí fún un pé, “Èmi kò ní ọkọ.” Jesu wí fún un pé, “Ìwọ́ dáhùn dáradára pé, èmi kò ní ọkọ: Nítorí tí ìwọ ti ní ọkọ márùn-ún rí; ọkùnrin tí ìwọ sì ní báyìí kì í ṣe ọkọ rẹ. Ohun tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ tán yìí, òtítọ́ ni.” Obìnrin náà wí fún un pé, “Alàgbà, mo wòye pé, wòlíì ni ìwọ ń ṣe.