Joh 3:4-8
Joh 3:4-8 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nikodemu wi fun u pe, A o ti ṣe le tún enia bí, nigbati o di agbalagba tan? o ha le wọ̀ inu iya rẹ̀ lọ nigba keji, ki a si bí i? Jesu dahùn wipe, Lõtọ, lõtọ ni mo wi fun ọ, Bikoṣepe a fi omi ati Ẹmi bi enia, on kò le wọ̀ ijọba Ọlọrun. Eyiti a bí nipa ti ara, ara ni; eyiti a si bí nipa ti Ẹmí, ẹmí ni. Ki ẹnu ki o máṣe yà ọ, nitori mo wi fun ọ pe, A kò le ṣe alaitún nyin bí. Afẹfẹ nfẹ si ibi ti o gbé wù u, iwọ si ngbọ́ iró rẹ̀, ṣugbọn iwọ kò mọ̀ ibi ti o ti wá, ati ibi ti o gbé nlọ: gẹgẹ bẹ̃ni olukuluku ẹniti a bí nipa ti Ẹmí.
Joh 3:4-8 Yoruba Bible (YCE)
Nikodemu bi í pé, “Báwo ni a ti ṣe lè tún ẹni tí ó ti di àgbàlagbà bí? Kò sá tún lè pada wọ inú ìyá rẹ̀ lẹẹkeji kí á wá tún un bí!” Jesu dáhùn pé, “Mo fẹ́ kí o mọ̀ dájúdájú pé, ẹnikẹ́ni tí a kò bá fi omi ati Ẹ̀mí bí, kò lè wọ ìjọba Ọlọrun. Ẹni tí a bá bí ní bíbí ti ẹran-ara, ẹran-ara ni. Ẹni tí a bá bí ní bíbí ti Ẹ̀mí, ẹ̀mí ni. Má ṣe jẹ́ kí ẹnu yà ọ́ nítorí mo wí fún ọ pé: dandan ni kí á tún yín bí. Afẹ́fẹ́ ń fẹ́ sí ibikíbi tí ó bá wù ú; ò ń gbọ́ ìró rẹ̀, ṣugbọn o kò mọ ibi tí ó ti ń bọ̀, tabi ibi tí ó ń lọ. Bẹ́ẹ̀ gan-an ni ó rí pẹlu gbogbo ẹni tí a bí ní bíbí ti Ẹ̀mí.”
Joh 3:4-8 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nikodemu wí fún un pé, a ó ti ṣe lè tún ènìyàn bí nígbà tí ó di àgbàlagbà tan? Ó ha lè wọ inú ìyá rẹ̀ lọ nígbà kejì, kí a sì bí i? Jesu dáhùn wí pé, “Lóòótọ́ lóòótọ́ ni mo wí fún ọ, bí kò ṣe pé a fi omi àti Ẹ̀mí bí ènìyàn, òun kò lè wọ ìjọba Ọlọ́run. Èyí tí a bí nípa ti ara, ti ara ni; èyí tí a sì bí nípa ti Ẹ̀mí, ti Ẹ̀mí ni. Kí ẹnu kí ó má ṣe yà ọ́, nítorí mo wí fún ọ pé, ‘A kò lè ṣe aláìtún yín bí.’ Afẹ́fẹ́ ń fẹ́ sí ibi tí ó gbé wù ú, ìwọ sì ń gbọ́ ìró rẹ̀, ṣùgbọ́n ìwọ kò mọ ibi tí ó gbé ti wá, àti ibi tí ó gbé ń lọ: gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ ni olúkúlùkù ẹni tí a bí nípa ti Ẹ̀mí.”