Joh 21:20-23
Joh 21:20-23 Yoruba Bible (YCE)
Nígbà tí Peteru bojú wẹ̀yìn, ó rí ọmọ-ẹ̀yìn tí Jesu fẹ́ràn tí ó ń tẹ̀lé e. Òun ni ó súnmọ́ Jesu pẹ́kípẹ́kí nígbà tí wọn ń jẹun, tí ó bi Jesu pé, “Oluwa, ta ni yóo fi ọ́ lé àwọn ọ̀tá lọ́wọ́ rí?” Nígbà tí Peteru rí i, ó bi Jesu pé, “Oluwa, eléyìí ńkọ́?” Jesu dá a lóhùn pé, “Bí mo bá fẹ́ kí ó wà títí n óo fi dé, èwo ni ó kàn ọ́? Ìwọ sá máa tẹ̀lé mi ní tìrẹ.” Nígbà tí gbolohun yìí dé etí àwọn onigbagbọ, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí sọ pé ọmọ-ẹ̀yìn náà kò ní kú. Ṣugbọn kò sọ fún un pé kò ní kú. Ohun tí ó wí ni pé, “Bí mo bá fẹ́ kí ó wà títí n óo fi dé, èwo ni ó kàn ọ́?”
Joh 21:20-23 Bibeli Mimọ (YBCV)
Peteru si yipada, o ri ọmọ-ẹhin nì, ẹniti Jesu fẹràn, mbọ̀ lẹhin; ẹniti o si rọ̀gun si àiya rẹ̀ nigba onjẹ alẹ ti o si wi fun u pe, Oluwa, tali ẹniti yõ fi ọ hàn? Nigbati Peteru ri i, o wi fun Jesu pe, Oluwa, Eleyi ha nkọ́? Jesu wi fun u pe, Bi emi ba fẹ ki o duro titi emi o fi de, kili eyini si ọ? Ìwọ mã tọ̀ mi lẹhin. Nitorina ọ̀rọ yi si tàn ka lãrin awọn arakunrin pe, ọmọ-ẹhin nì kì yio kú: ṣugbọn Jesu kò wi fun u pe, On kì yio kú; ṣugbọn, Bi emi ba fẹ ki o duro titi emi o fi de, kili eyinì si ọ?
Joh 21:20-23 Yoruba Bible (YCE)
Nígbà tí Peteru bojú wẹ̀yìn, ó rí ọmọ-ẹ̀yìn tí Jesu fẹ́ràn tí ó ń tẹ̀lé e. Òun ni ó súnmọ́ Jesu pẹ́kípẹ́kí nígbà tí wọn ń jẹun, tí ó bi Jesu pé, “Oluwa, ta ni yóo fi ọ́ lé àwọn ọ̀tá lọ́wọ́ rí?” Nígbà tí Peteru rí i, ó bi Jesu pé, “Oluwa, eléyìí ńkọ́?” Jesu dá a lóhùn pé, “Bí mo bá fẹ́ kí ó wà títí n óo fi dé, èwo ni ó kàn ọ́? Ìwọ sá máa tẹ̀lé mi ní tìrẹ.” Nígbà tí gbolohun yìí dé etí àwọn onigbagbọ, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí sọ pé ọmọ-ẹ̀yìn náà kò ní kú. Ṣugbọn kò sọ fún un pé kò ní kú. Ohun tí ó wí ni pé, “Bí mo bá fẹ́ kí ó wà títí n óo fi dé, èwo ni ó kàn ọ́?”
Joh 21:20-23 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Peteru sì yípadà, ó rí ọmọ-ẹ̀yìn náà, ẹni tí Jesu fẹ́ràn, ń bọ̀ lẹ́yìn; ẹni tí ó gbara le súnmọ́ àyà rẹ̀ nígbà oúnjẹ alẹ́ tí ó sì wí fún un pé, “Olúwa, ta ni ẹni tí yóò fi ọ́ hàn?” Nígbà tí Peteru rí i, ó wí fún Jesu pé, “Olúwa, Eléyìí ha ńkọ́?” Jesu wí fún un pé, “Bí èmi bá fẹ́ kí ó dúró títí èmi ó fi dé, kín ni èyí jẹ́ sí ọ? Ìwọ máa tọ̀ mí lẹ́yìn.” Ọ̀rọ̀ yìí sì tàn ká láàrín àwọn arákùnrin pé, ọmọ-ẹ̀yìn náà kì yóò kú: ṣùgbọ́n Jesu kò wí fún un pé, òun kì yóò kú; ṣùgbọ́n, “Bí èmi bá fẹ́ kí ó dúró títí èmi ó fi dé, kín ni èyí jẹ́ sí ọ?”