Joh 21:1-7
Joh 21:1-7 Bibeli Mimọ (YBCV)
LẸHIN nkan wọnyi, Jesu tún fi ara rẹ̀ hàn fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ leti okun Tiberia; bayi li o si farahàn. Simoni Peteru, ati Tomasi ti a npè ni Didimu, ati Natanaeli ara Kana ti Galili, ati awọn ọmọ Sebede, ati awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ meji miran jùmọ wà pọ̀. Simoni Peteru wi fun wọn pe, Emi nlọ ipẹja. Nwọn wi fun u pe, Awa pẹlu mba ọ lọ. Nwọn jade, nwọn si wọ̀ inú ọkọ̀; li oru na nwọn kò si mú ohunkohun. Ṣugbọn nigbati ilẹ bẹrẹ si imọ́, Jesu duro leti okun: ṣugbọn awọn ọmọ-ẹhin kò mọ̀ pe Jesu ni. Nitorina Jesu wi fun wọn pe, Ẹnyin ọmọde, ẹ li onjẹ diẹ bi? Nwọn da a lohùn wipe, Rára o. O si wi fun wọn pe, Ẹ sọ àwọn si apa ọtùn ọkọ̀, ẹnyin ó si ri. Nitorina nwọn sọ ọ, nwọn kò si le fà a jade nitori ọpọ ẹja. Nitorina li ọmọ-ẹhin na ti Jesu fẹran wi fun Peteru pe, Oluwa ni. Nigbati Simoni Peteru gbọ́ pe Oluwa ni, bẹli o di amure ẹ̀wu rẹ̀ mọra, (nitori o wà ni ìhoho), o si gbé ara rẹ̀ sọ sinu okun.
Joh 21:1-7 Yoruba Bible (YCE)
Lẹ́yìn èyí, Jesu tún fara han àwọn ọmọ-ẹ̀yìn ní òkun Tiberiasi. Bí ó ṣe farahàn wọ́n nìyí: Simoni Peteru, ati Tomasi tí wọn ń pè ní Didimu (èyí ni “Ìbejì”) ati Nataniẹli ará Kana, ni ilẹ̀ Galili, ati àwọn ọmọ Sebede ati àwọn meji mìíràn ninu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ wà ní ibìkan. Simoni Peteru sọ fún wọn pé, “Mò ń lọ pa ẹja.” Wọ́n dá a lóhùn pé, “Àwa náà yóo bá ọ lọ.” Wọ́n bá jáde lọ, wọ́n wọ ọkọ̀ ojú omi. Ní gbogbo alẹ́ ọjọ́ náà wọn kò rí ẹja kankan pa. Nígbà tí ó di àfẹ̀mọ́jú Jesu dúró ní èbúté, ṣugbọn àwọn ọmọ-ẹ̀yìn kò mọ̀ pé Jesu ni. Jesu bi wọ́n pé, “Ẹ̀yin ọmọde, ǹjẹ́ ẹ ní ohunkohun fún jíjẹ?” Wọ́n bá dá a lóhùn pé, “Rárá o!” Ó wí fún wọn pé, “Ẹ ju àwọ̀n sí apá ọ̀tún ọkọ̀, ẹ óo rí ẹja pa.” Wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀, ni wọn kò bá lè fa àwọ̀n mọ́, nítorí ọ̀pọ̀ ẹja. Ọmọ-ẹ̀yìn tí Jesu fẹ́ràn sọ fún Peteru pé, “Oluwa ni!” Nígbà tí Simoni Peteru gbọ́ pé Oluwa ni, ó wọ ẹ̀wù rẹ̀, nítorí ó ti bọ́ra sílẹ̀ fún iṣẹ́, ó bá bẹ́ sinu òkun, ó ń lúwẹ̀ẹ́ lọ sébùúté.
Joh 21:1-7 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí, Jesu tún fi ara rẹ̀ hàn fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ létí Òkun Tiberia; báyìí ni ó sì farahàn. Simoni Peteru, àti Tomasi tí a ń pè ní Didimu, àti Natanaeli ará Kana ti Galili, àti àwọn ọmọ Sebede, àti àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ méjì mìíràn jùmọ̀ wà pọ̀. Simoni Peteru wí fún wọn pé, “Èmi ń lọ pẹja!” Wọ́n wí fún un pé, “Àwa pẹ̀lú ń bá ọ lọ.” Wọ́n jáde, wọ́n sì wọ inú ọkọ̀ ojú omi; ní òru náà wọn kò sì mú ohunkóhun. Ṣùgbọ́n nígbà tí ilẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí mọ́, Jesu dúró létí Òkun: ṣùgbọ́n àwọn ọmọ-ẹ̀yìn kò mọ̀ pé Jesu ni. Jesu wí fún wọn pé, “Ẹ̀yin ọmọdé, ẹ ní ẹja díẹ̀ bí?” Wọ́n dá a lóhùn pé, “Rárá o.” Ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ sọ àwọ̀n sí apá ọ̀tún ọkọ̀ ojú omi, ẹ̀yin yóò sì rí.” Nígbà tí wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀, wọn kò sì lè fà á jáde nítorí ọ̀pọ̀ ẹja. Nígbà náà ni ọmọ-ẹ̀yìn náà tí Jesu fẹ́ràn wí fún Peteru pé, “Olúwa ni!” Nígbà tí Simoni Peteru gbọ́ pé Olúwa ni, bẹ́ẹ̀ ni ó di àmùrè ẹ̀wù rẹ̀ mọ́ra, nítorí tí ó wà ní ìhòhò, ó sì gbé ara rẹ̀ sọ sínú Òkun.