Joh 20:17-20
Joh 20:17-20 Bibeli Mimọ (YBCV)
Jesu wi fun u pe, Máṣe fi ọwọ́ kàn mi; nitoriti emi kò ti igòke lọ sọdọ Baba mi: ṣugbọn lọ sọdọ awọn arakunrin mi, si wi fun wọn pe, Emi ngòke lọ sọdọ Baba mi, ati Baba nyin; ati sọdọ Ọlọrun mi, ati Ọlọrun nyin. Maria Magdalene wá, o si sọ fun awọn ọmọ-ẹhin pe, on ti ri Oluwa, ati pe, o si ti sọ nkan wọnyi fun on. Lọjọ kanna, lọjọ ikini ọ̀sẹ nigbati alẹ́ lẹ́, ti a si ti tì ilẹkun ibiti awọn ọmọ-ẹhin gbé pejọ, nitori ìbẹru awọn Ju, bẹni Jesu de, o duro larin, o si wi fun wọn pe, Alafia fun nyin. Nigbati o si ti wi bẹ̃ tan, o fi ọwọ́ ati ìha rẹ̀ hàn wọn. Nitorina li awọn ọmọ-ẹhin yọ̀, nigbati nwọn ri Oluwa.
Joh 20:17-20 Yoruba Bible (YCE)
Jesu bá sọ fún un pé, “Mú ọwọ́ kúrò lára mi, nítorí n kò ì tíì gòkè tọ Baba mi lọ. Ṣugbọn lọ sọ́dọ̀ àwọn arakunrin mi, kí o sọ fún wọn pé, ‘Mò ń gòkè lọ sọ́dọ̀ Baba mi ati Baba yín, Ọlọrun mi ati Ọlọrun yín.’ ” Maria Magidaleni bá lọ sọ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn pé, “Mo ti rí Oluwa!” Ó bá sọ ohun tí Jesu sọ fún un fún wọn. Nígbà tí ó di alẹ́ ọjọ́ kinni ọ̀sẹ̀, níbi tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn wà, tí wọ́n ti ìlẹ̀kùn mọ́rí nítorí wọ́n bẹ̀rù àwọn Juu, Jesu dé, ó dúró láàrin wọn. Ó kí wọn pé, “Alaafia fun yín!” Nígbà tí ó ti sọ báyìí tán, ó fi ọwọ́ rẹ̀ ati ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ hàn wọ́n.
Joh 20:17-20 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Jesu wí fún un pé, “Má ṣe fi ọwọ́ kàn mí; nítorí tí èmi kò tí ì gòkè lọ sí ọ̀dọ̀ Baba mi: ṣùgbọ́n lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn arákùnrin mi, sì wí fún wọn pé, ‘Èmi ń gòkè lọ sí ọ̀dọ̀ Baba mi, àti Baba yín: àti sí ọ̀dọ̀ Ọlọ́run mi, àti Ọlọ́run yín.’ ” Maria Magdalene wá, ó sì sọ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, “Òun ti rí Olúwa!” Àti pé, ó sì ti fi nǹkan wọ̀nyí fún òun. Ní ọjọ́ kan náà, lọ́jọ́ kìn-ín-ní ọ̀sẹ̀ nígbà tí alẹ́ lẹ́, tí a sì ti ìlẹ̀kùn ibi tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn gbé péjọ, nítorí ìbẹ̀rù àwọn Júù, bẹ́ẹ̀ ni Jesu dé, ó dúró láàrín, ó sì wí fún wọn pé, “Àlàáfíà fún yín.” Nígbà tí ó sì ti wí bẹ́ẹ̀ tán, ó fi ọwọ́ àti ìhà rẹ̀ hàn wọ́n. Nígbà náà ni àwọn ọmọ-ẹ̀yìn yọ̀, nígbà tí wọ́n rí Olúwa.