Joh 20:11-13
Joh 20:11-13 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ṣugbọn Maria duro leti ibojì lode, o nsọkun: bi o ti nsọkun, bẹli o bẹ̀rẹ, o si wò inu ibojì. O si kiyesi awọn angẹli meji alaṣọ funfun, nwọn joko, ọkan niha ori, ati ọkan niha ẹsẹ̀, nibiti oku Jesu gbé ti sùn si. Nwọn si wi fun u pe, Obinrin yi, ẽṣe ti iwọ fi nsọkun? O si wi fun wọn pe, Nitoriti nwọn ti gbé Oluwa mi, emi kò si mọ̀ ibiti nwọn gbé tẹ́ ẹ si.
Joh 20:11-13 Yoruba Bible (YCE)
Ṣugbọn Maria dúró lóde lẹ́bàá ibojì, ó ń sunkún. Bí ó ti ń sunkún, ó bẹ̀rẹ̀ ó yọjú wo inú ibojì, ó bá rí àwọn angẹli meji tí wọ́n wọ aṣọ funfun, ọ̀kan jókòó níbi orí, ekeji jókòó níbi ẹsẹ̀ ibi tí wọ́n tẹ́ òkú Jesu sí. Wọ́n bi í pé, “Obinrin, kí ló dé tí ò ń sunkún?” Ó dá wọn lóhùn pé, “Wọ́n ti gbé Oluwa mi lọ, n kò mọ ibi tí wọ́n tẹ́ ẹ sí.”
Joh 20:11-13 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ṣùgbọ́n Maria dúró létí ibojì lóde, ó ń sọkún: bí ó ti ń sọkún, bẹ́ẹ̀ ni ó bẹ̀rẹ̀, ó sì wo inú ibojì. Ó sì kíyèsi àwọn angẹli méjì aláṣọ funfun, wọ́n jókòó, ọ̀kan níhà orí àti ọ̀kan níhà ẹsẹ̀, níbi tí òkú Jesu gbé ti sùn sí. Wọ́n sì wí fún un pé, “Obìnrin yìí, èéṣe tí ìwọ fi ń sọkún?” Ó sì wí fún wọn pé, “Nítorí tí wọ́n ti gbé Olúwa mi, èmi kò sì mọ ibi tí wọ́n gbé tẹ́ ẹ sí.”