Joh 20:1-18

Joh 20:1-18 Bibeli Mimọ (YBCV)

LI ọjọ ikini ọ̀sẹ ni kùtùkùtù nigbati ilẹ kò ti imọ́, ni Maria Magdalene wá si ibojì, o si ri pe, a ti gbé okuta kuro li ẹnu ibojì. Nitorina o sare, o si tọ̀ Simoni Peteru wá, ati ọmọ-ẹhin miran na ẹniti Jesu fẹran, o si wi fun wọn pe, Nwọn ti gbé Oluwa kuro ninu ibojì, awa kò si mọ̀ ibi ti nwọn gbé tẹ́ ẹ si. Nigbana ni Peteru jade, ati ọmọ-ẹhin miran na, nwọn si wá si ibojì. Awọn mejeji si jùmọ sare: eyi ọmọ-ẹhin miran nì si sare yà Peteru, o si tètekọ de ibojì. O si bẹ̀rẹ, o si wò inu rẹ̀, o ri aṣọ ọgbọ na lelẹ; ṣugbọn on kò wọ̀ inu rẹ̀. Nigbana ni Simoni Peteru ti mbọ̀ lẹhin rẹ̀ de, o si wọ̀ inu ibojì, o si ri aṣọ ọ̀gbọ na wà nilẹ̀. Ati pe gèle, ti o wà nibi ori rẹ̀, kò si wà pẹlu aṣọ ọgbọ na, ṣugbọn a ká a jọ ni ibikan fun ara rẹ̀. Nigbana li ọmọ-ẹhin miran na, ẹniti o kọ de ibojì, wọ̀ inu rẹ̀ pẹlu, o si ri, o si gbagbọ́. Nitoripe nwọn kò sá ti imọ̀ iwe-mimọ́ pe, on kò le ṣaima jinde kuro ninu okú. Bẹli awọn ọmọ-ẹhin na si tun pada lọ si ile wọn. Ṣugbọn Maria duro leti ibojì lode, o nsọkun: bi o ti nsọkun, bẹli o bẹ̀rẹ, o si wò inu ibojì. O si kiyesi awọn angẹli meji alaṣọ funfun, nwọn joko, ọkan niha ori, ati ọkan niha ẹsẹ̀, nibiti oku Jesu gbé ti sùn si. Nwọn si wi fun u pe, Obinrin yi, ẽṣe ti iwọ fi nsọkun? O si wi fun wọn pe, Nitoriti nwọn ti gbé Oluwa mi, emi kò si mọ̀ ibiti nwọn gbé tẹ́ ẹ si. Nigbati o si ti wi eyi tan, o yipada, o si ri Jesu duro, kò si mọ̀ pe Jesu ni. Jesu wi fun u pe, Obinrin yi, ẽṣe ti iwọ fi nsọkun? Ta ni iwọ nwá? On ṣebi oluṣọgba ni iṣe, o wi fun u pe, Alàgba, bi iwọ ba ti gbé e kuro nihin, sọ ibiti o gbé tẹ ẹ si fun mi, emi o si gbé e kuro. Jesu wi fun u pe, Maria. O si yipada, o wi fun u pe, Rabboni; eyi ti o jẹ Olukọni. Jesu wi fun u pe, Máṣe fi ọwọ́ kàn mi; nitoriti emi kò ti igòke lọ sọdọ Baba mi: ṣugbọn lọ sọdọ awọn arakunrin mi, si wi fun wọn pe, Emi ngòke lọ sọdọ Baba mi, ati Baba nyin; ati sọdọ Ọlọrun mi, ati Ọlọrun nyin. Maria Magdalene wá, o si sọ fun awọn ọmọ-ẹhin pe, on ti ri Oluwa, ati pe, o si ti sọ nkan wọnyi fun on.

Joh 20:1-18 Yoruba Bible (YCE)

Ní kutukutu ọjọ́ kinni ọ̀sẹ̀, kí ilẹ̀ tó mọ́, Maria Magidaleni lọ sí ibojì náà, ó rí i pé wọ́n ti yí òkúta kúrò lẹ́nu rẹ̀. Ó bá sáré lọ sọ́dọ̀ Simoni Peteru ati ọmọ-ẹ̀yìn tí Jesu fẹ́ràn, ó sọ fún wọn pé, “Wọ́n ti gbé Oluwa kúrò ninu ibojì, a kò sì mọ ibi tí wọ́n tẹ́ ẹ sí.” Peteru ati ọmọ-ẹ̀yìn náà bá jáde, wọ́n lọ sí ibojì náà. Àwọn mejeeji bẹ̀rẹ̀ sí sáré; ṣugbọn ọmọ-ẹ̀yìn keji ya Peteru sílẹ̀, òun ni ó kọ́ dé ibojì. Ó bẹ̀rẹ̀ ó yọjú wo inú ibojì, ó rí aṣọ-ọ̀gbọ̀ tí ó wà nílẹ̀, ṣugbọn kò wọ inú ibojì. Nígbà tí Simoni Peteru tí ó tẹ̀lé e dé, ó wọ inú ibojì lọ tààrà. Ó rí aṣọ-ọ̀gbọ̀ nílẹ̀, ó rí aṣọ tí wọ́n fi wé orí òkú lọ́tọ̀, kò sí lára aṣọ-ọ̀gbọ̀, ó dá wà níbìkan ní wíwé. Ọmọ-ẹ̀yìn keji tí ó kọ́kọ́ dé ẹnu ibojì náà bá wọ inú ibojì; òun náà rí i, ó wá gbàgbọ́. (Nítorí ohun tí Ìwé Mímọ́ wí kò tíì yé wọn pé dandan ni kí ó jí dìde ninu òkú.) Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn bá tún pada lọ sí ilé wọn. Ṣugbọn Maria dúró lóde lẹ́bàá ibojì, ó ń sunkún. Bí ó ti ń sunkún, ó bẹ̀rẹ̀ ó yọjú wo inú ibojì, ó bá rí àwọn angẹli meji tí wọ́n wọ aṣọ funfun, ọ̀kan jókòó níbi orí, ekeji jókòó níbi ẹsẹ̀ ibi tí wọ́n tẹ́ òkú Jesu sí. Wọ́n bi í pé, “Obinrin, kí ló dé tí ò ń sunkún?” Ó dá wọn lóhùn pé, “Wọ́n ti gbé Oluwa mi lọ, n kò mọ ibi tí wọ́n tẹ́ ẹ sí.” Bí ó ti sọ báyìí tán, ó bojú wẹ̀yìn, ó bá rí Jesu tí ó dúró, ṣugbọn kò mọ̀ pé òun ni. Jesu bi í pé, “Obinrin, kí ní dé tí ò ń sunkún? Ta ni ò ń wá?” Maria ṣebí olùṣọ́gbà ni. Ó sọ fún un pé, “Alàgbà, bí o bá ti gbé e lọ, sọ ibi tí o tẹ́ ẹ sí fún mi, kí n lè lọ gbé e.” Jesu bá pè é lórúkọ, ó ní, “Maria!” Maria bá yipada sí i, ó pè é ní èdè Heberu pé, “Raboni!” (Ìtumọ̀ èyí ni “Olùkọ́ni.”) Jesu bá sọ fún un pé, “Mú ọwọ́ kúrò lára mi, nítorí n kò ì tíì gòkè tọ Baba mi lọ. Ṣugbọn lọ sọ́dọ̀ àwọn arakunrin mi, kí o sọ fún wọn pé, ‘Mò ń gòkè lọ sọ́dọ̀ Baba mi ati Baba yín, Ọlọrun mi ati Ọlọrun yín.’ ” Maria Magidaleni bá lọ sọ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn pé, “Mo ti rí Oluwa!” Ó bá sọ ohun tí Jesu sọ fún un fún wọn.

Joh 20:1-18 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Ní kùtùkùtù ọjọ́ kìn-ín-ní ọ̀sẹ̀, nígbà tí ilẹ̀ kò tí ì mọ́, ni Maria Magdalene wá sí ibojì, ó sì rí i pé, a ti gbé òkúta kúrò lẹ́nu ibojì. Nítorí náà, ó sáré, ó sì tọ Simoni Peteru àti ọmọ-ẹ̀yìn mìíràn wá, ẹni tí Jesu fẹ́ràn, ó sì wí fún wọn pé, “Wọ́n ti gbé Olúwa kúrò nínú ibojì, àwa kò sì mọ ibi tí wọ́n gbé tẹ́ ẹ sí.” Nígbà náà ni Peteru àti ọmọ-ẹ̀yìn mìíràn náà jáde, wọ́n sì wá sí ibojì. Àwọn méjèèjì sì jùmọ̀ sáré: èyí ọmọ-ẹ̀yìn náà sì sáré ya Peteru, ó sì kọ́kọ́ dé ibojì. Ó sì bẹ̀rẹ̀ láti wo inú rẹ̀, ó rí aṣọ ọ̀gbọ̀ náà ní ilẹ̀; ṣùgbọ́n òun kò wọ inú rẹ̀. Nígbà náà ni Simoni Peteru tí ń bọ̀ lẹ́yìn rẹ̀ dé, ó sì wọ inú ibojì, ó sì rí aṣọ ọ̀gbọ̀ náà ní ilẹ̀. Àti pé, gèlè tí ó wà níbi orí rẹ̀ kò sì wà pẹ̀lú aṣọ ọ̀gbọ̀ náà, ṣùgbọ́n ó ká jọ ní ibìkan fúnrarẹ̀. Nígbà náà ni ọmọ-ẹ̀yìn mìíràn náà, ẹni tí ó kọ́ dé ibojì wọ inú rẹ̀ pẹ̀lú, ó sì rí i, ó sì gbàgbọ́. (Nítorí tí wọn kò sá à tí mọ ìwé mímọ́ pé, Jesu ní láti jíǹde kúrò nínú òkú.) Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọ-ẹ̀yìn náà sì tún padà lọ sí ilé wọn. Ṣùgbọ́n Maria dúró létí ibojì lóde, ó ń sọkún: bí ó ti ń sọkún, bẹ́ẹ̀ ni ó bẹ̀rẹ̀, ó sì wo inú ibojì. Ó sì kíyèsi àwọn angẹli méjì aláṣọ funfun, wọ́n jókòó, ọ̀kan níhà orí àti ọ̀kan níhà ẹsẹ̀, níbi tí òkú Jesu gbé ti sùn sí. Wọ́n sì wí fún un pé, “Obìnrin yìí, èéṣe tí ìwọ fi ń sọkún?” Ó sì wí fún wọn pé, “Nítorí tí wọ́n ti gbé Olúwa mi, èmi kò sì mọ ibi tí wọ́n gbé tẹ́ ẹ sí.” Nígbà tí ó sì ti wí èyí tan, ó yípadà, ó sì rí Jesu dúró, kò sì mọ̀ pé Jesu ni. Jesu wí fún un pé, “Obìnrin yìí, èéṣe tí ìwọ fi ń sọkún? Ta ni ìwọ ń wá?” Òun ṣe bí olùṣọ́gbà ní í ṣe, ó wí fún un pé, “Alàgbà, bí ìwọ bá ti gbé e kúrò níhìn-ín yìí, sọ ibi tí ìwọ tẹ́ ẹ sí fún mi, èmi yóò sì gbé e kúrò.” Jesu wí fún un pé, “Maria!” Ó sì yípadà, ó wí fún un ní èdè Heberu pé, “Rabboni!” (èyí tí ó túmọ̀ sí “Olùkọ́”). Jesu wí fún un pé, “Má ṣe fi ọwọ́ kàn mí; nítorí tí èmi kò tí ì gòkè lọ sí ọ̀dọ̀ Baba mi: ṣùgbọ́n lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn arákùnrin mi, sì wí fún wọn pé, ‘Èmi ń gòkè lọ sí ọ̀dọ̀ Baba mi, àti Baba yín: àti sí ọ̀dọ̀ Ọlọ́run mi, àti Ọlọ́run yín.’ ” Maria Magdalene wá, ó sì sọ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, “Òun ti rí Olúwa!” Àti pé, ó sì ti fi nǹkan wọ̀nyí fún òun.