Joh 2:19-22
Joh 2:19-22 Bibeli Mimọ (YBCV)
Jesu dahùn o si wi fun wọn pe, Ẹ wó tẹmpili yi palẹ̀, ni ijọ mẹta Emi o si gbé e ró. Nigbana li awọn Ju wipe, Ọdún mẹrindiladọta li a fi kọ́ tẹmpili yi, iwọ o ha si gbé e ró ni ijọ mẹta? Ṣugbọn on nsọ ti tẹmpili ara rẹ̀. Nitorina nigbati o jinde kuro ninu okú, awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ ranti pe, o ti sọ eyi fun wọn; nwọn si gbà iwe-mimọ́ gbọ́, ati ọ̀rọ ti Jesu ti sọ.
Joh 2:19-22 Yoruba Bible (YCE)
Jesu dá wọn lóhùn pé, “Bí ẹ bá wó Tẹmpili yìí, èmi yóo tún un kọ́ ní ọjọ́ mẹta.” Àwọn Juu wí fún un pé, “Aadọta ọdún ó dín mẹrin ni ó gbà wá láti kọ́ Tẹmpili yìí, ìwọ yóo wá kọ́ ọ ní ọjọ́ mẹta?” Ṣugbọn ara rẹ̀ ni ó ń sọ̀rọ̀ bá, tí ó pè ní Tẹmpili. Nítorí náà, nígbà tí a ti jí i dìde kúrò ninu òkú, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ ranti pé ó ti sọ èyí fún wọn, wọ́n wá gba Ìwé Mímọ́ gbọ́ ati ọ̀rọ̀ tí Jesu ti sọ.
Joh 2:19-22 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Jesu dáhùn ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ wó tẹmpili yìí palẹ̀, Èmi ó sì tún un kọ ní ọjọ́ mẹ́ta.” Nígbà náà ní àwọn Júù wí pé, “Ọdún mẹ́rìn-dínláàádọ́ta ni a fi kọ́ tẹmpili yìí, ìwọ ó ha sì tún un kọ ní ọjọ́ mẹ́ta?” Ṣùgbọ́n òun ń sọ ti tẹmpili ara rẹ̀. Nítorí náà nígbà tí ó jíǹde kúrò nínú òkú, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ rántí pé, ó ti sọ èyí fún wọn; wọ́n sì gba ìwé Mímọ́, àti ọ̀rọ̀ tí Jesu ti sọ gbọ́.