Joh 2:13-17
Joh 2:13-17 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ajọ irekọja awọn Ju si sunmọ etile, Jesu si goke lọ si Jerusalemu, O si ri awọn ti ntà malu, ati agutan, ati àdaba ni tẹmpili, ati awọn onipaṣipàrọ owo joko: O si fi okùn tẹrẹ ṣe paṣan, o si lé gbogbo wọn jade kuro ninu tẹmpili, ati agutan ati malu; o si dà owo awọn onipaṣipàrọ owo nù, o si bì tabili wọn ṣubu. O si wi fun awọn ti ntà àdaba pe, Ẹ gbe nkan wọnyi kuro nihin; ẹ máṣe sọ ile Baba mi di ile ọjà tità. Awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ si ranti pe, a ti kọ ọ pe, Itara ile rẹ jẹ mi run.
Joh 2:13-17 Yoruba Bible (YCE)
Nígbà tí ó fẹ́rẹ̀ tó àkókò Àjọ̀dún Ìrékọjá àwọn Juu, Jesu gòkè lọ sí Jerusalẹmu. Ó rí àwọn tí ń ta mààlúù, aguntan, ati ẹyẹlé ninu àgbàlá Tẹmpili, ati àwọn tí ń ṣe pàṣípààrọ̀ owó. Jesu bá fi okùn kan ṣe ẹgba, ó bẹ̀rẹ̀ sí lé gbogbo wọn jáde kúrò ninu àgbàlá Ilé Ìrúbọ. Ó lé àwọn tí ń ta aguntan ati mààlúù jáde. Ó da gbogbo owó àwọn onípàṣípààrọ̀ nù, ó sì ti tabili wọn ṣubú. Ó sọ fún àwọn tí ń ta ẹyẹlé pé, “Ẹ gbé gbogbo nǹkan wọnyi kúrò níhìn-ín, ẹ má ṣe sọ ilé Baba mi di ilé ìtajà!” Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ ranti àkọsílẹ̀ kan tí ó kà báyìí, “Ìtara ilé rẹ ti jẹ mí lógún patapata.”
Joh 2:13-17 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Àjọ ìrékọjá àwọn Júù sì súnmọ́ etílé, Jesu sì gòkè lọ sí Jerusalẹmu, Ó sì rí àwọn tí n ta màlúù, àti àgùntàn, àti àdàbà, àti àwọn onípàṣípàrọ̀ owó nínú tẹmpili wọ́n jókòó: Ó sì fi okùn tẹ́ẹ́rẹ́ ṣe pàṣán, ó sì lé gbogbo wọn jáde kúrò nínú tẹmpili, àti àgùntàn àti màlúù; ó sì da owó àwọn onípàṣípàrọ̀ owó nù, ó si ti tábìlì wọn ṣubú. Ó sì wí fún àwọn tí ń ta àdàbà pé, “Ẹ gbé nǹkan wọ̀nyí kúrò níhìn-ín; ẹ má ṣe sọ ilé Baba mi di ilé ọjà títà.” Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sì rántí pé, a ti kọ ọ́ pé, “Ìtara ilé rẹ jẹ mí run.”