Joh 19:29-31
Joh 19:29-31 Bibeli Mimọ (YBCV)
A gbé ohun èlo kan kalẹ nibẹ̀ ti o kún fun ọti kikan: nwọn si fi sponge ti o kun fun ọti kikan, sori igi hissopu, nwọn si fi si i li ẹnu. Nitorina nigbati Jesu si ti gbà ọti kikan na, o wipe, O pari: o si tẹ ori rẹ̀ ba, o jọwọ ẹmí rẹ̀ lọwọ. Nitori o jẹ ọjọ Ipalẹmọ, ki okú wọn ma bà wà lori agbelebu li ọjọ isimi, (nitori ojọ nla ni ọjọ isimi na) nitorina awọn Ju bẹ̀ Pilatu pe ki a ṣẹ egungun itan wọn, ki a si gbe wọn kuro.
Joh 19:29-31 Yoruba Bible (YCE)
Àwo ọtí kan wà níbẹ̀. Wọ́n bá fi kinní kan bíi kànìnkànìn bọ inú ọtí náà, wọ́n fi sórí ọ̀pá gígùn kan, wọ́n nà án sí i lẹ́nu. Lẹ́yìn tí Jesu ti gba ọtí náà tán, ó wí pé, “Ó ti parí!” Lẹ́yìn náà ó tẹrí ba, ó bá dákẹ́. Nítorí ọjọ́ náà jẹ́ ìpalẹ̀mọ́ Àjọ̀dún Ìrékọjá, kí òkú má baà wà lórí agbelebu ní Ọjọ́ Ìsinmi, àwọn Juu bẹ Pilatu pé kí ó jẹ́ kí wọ́n dá àwọn tí wọ́n kàn mọ́ agbelebu ní ojúgun, kí wọ́n gbé wọn kúrò lórí agbelebu nítorí pé Ọjọ́ Ìsinmi pataki ni Ọjọ́ Ìsinmi náà.
Joh 19:29-31 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ohun èlò kan tí ó kún fún ọtí kíkan wà níbẹ̀, wọ́n tẹ kànìnkànìn tí ó kún fún ọtí kíkan bọ inú rẹ̀, wọ́n sì fi lé orí igi hísópù, wọ́n sì nà án sí i lẹ́nu. Nígbà tí Jesu sì ti gba ọtí kíkan náà, ó wí pé, “Ó parí!” Ó sì tẹ orí rẹ̀ ba, ó jọ̀wọ́ ẹ̀mí rẹ̀. Nítorí ó jẹ́ ọjọ́ ìpalẹ̀mọ́, kí òkú wọn má ba à wà lórí àgbélébùú ní ọjọ́ ìsinmi, (nítorí ọjọ́ ńlá ni ọjọ́ ìsinmi náà) nítorí náà, àwọn Júù bẹ Pilatu pé kí a ṣẹ́ egungun itan wọn, kí a sì gbé wọn kúrò.