Joh 19:25-27
Joh 19:25-27 Bibeli Mimọ (YBCV)
Iya Jesu ati arabinrin iya rẹ̀ Maria aya Klopa, ati Maria Magdalene, si duro nibi agbelebu. Nitorina nigbati Jesu ri iya rẹ̀, ati ọmọ-ẹhin na duro, ẹniti Jesu fẹràn, o wi fun iya rẹ̀ pe, Obinrin, wò ọmọ rẹ! Lẹhin na li o si wi fun ọmọ-ẹhin na pe, Wò iya rẹ! Lati wakati na lọ li ọmọ-ẹhin na si ti mu u lọ si ile ara rẹ̀.
Joh 19:25-27 Yoruba Bible (YCE)
Ìyá Jesu ati arabinrin ìyá rẹ̀ ati Maria aya Kilopasi ati Maria Magidaleni dúró lẹ́bàá agbelebu Jesu. Nígbà tí Jesu rí ìyá rẹ̀ ati ọmọ-ẹ̀yìn tí ó fẹ́ràn tí wọ́n dúró, ó wí fún ìyá rẹ̀ pé, “Obinrin, wo ọmọ rẹ.” Ó bá sọ fún ọmọ-ẹ̀yìn náà pé, “Wo ìyá rẹ.” Láti ìgbà náà ni ọmọ-ẹ̀yìn náà ti mú ìyá Jesu lọ sílé ara rẹ̀.
Joh 19:25-27 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ìyá Jesu àti arábìnrin ìyá rẹ̀ Maria aya Kilopa, àti Maria Magdalene sì dúró níbi àgbélébùú, Nígbà tí Jesu rí ìyá rẹ̀ àti ọmọ-ẹ̀yìn náà dúró, ẹni tí Jesu fẹ́ràn, ó wí fún ìyá rẹ̀ pé, “Obìnrin, wo ọmọ rẹ!” Lẹ́yìn náà ni ó sì wí fún ọmọ-ẹ̀yìn náà pé, “Wo ìyá rẹ!” Láti wákàtí náà lọ ni ọmọ-ẹ̀yìn náà sì ti mú un lọ sí ilé ara rẹ̀.