Joh 19:16-18
Joh 19:16-18 Bibeli Mimọ (YBCV)
Awa kò li ọba bikoṣe Kesari. Nigbana li o fà a le wọn lọwọ lati kàn a mọ agbelebu. Wọ́n bá gba Jesu lọ́wọ́ Pilatu. Nitorina nwọn mu Jesu, o si jade lọ, o rù agbelebu fun ara rẹ̀ si ibi ti a npè ni Ibi-agbari, li ede Heberu ti a npè ni Golgota: Nibiti nwọn gbé kàn a mọ agbelebu, ati awọn meji miran pẹlu rẹ̀, niha ikini ati nìha keji, Jesu si wà larin.
Joh 19:16-18 Yoruba Bible (YCE)
Pilatu bá fa Jesu fún wọn láti kàn mọ́ agbelebu. Wọ́n bá gba Jesu lọ́wọ́ Pilatu. Ó ru agbelebu rẹ̀ jáde lọ sí ibìkan tí ó ń jẹ́ “Ibi Agbárí,” tí wọn ń pè ní “Gọlgọta” ní èdè Heberu. Níbẹ̀ ni wọ́n ti kàn án mọ́ agbelebu, òun ati àwọn meji kan, ọ̀kan ní ẹ̀gbẹ́ ọ̀tún, ọ̀kan ní ẹ̀gbẹ́ òsì, Jesu wá wà láàrin.
Joh 19:16-18 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nítorí náà ni Pilatu fà á lé wọn lọ́wọ́ láti kàn án mọ́ àgbélébùú. Àwọn ológun gba Jesu lọ́wọ́ Pilatu. Nítorí náà, wọ́n mú Jesu, ó sì jáde lọ, ó ru àgbélébùú fúnrarẹ̀ sí ibi tí à ń pè ní ibi agbárí, ní èdè Heberu tí à ń pè ní Gọlgọta: Níbi tí wọ́n gbé kàn án mọ́ àgbélébùú, àti àwọn méjì mìíràn pẹ̀lú rẹ̀, níhà ìhín àti níhà kejì, Jesu sì wà láàrín.