Joh 19:1-6
Joh 19:1-6 Bibeli Mimọ (YBCV)
NITORINA ni Pilatu mu Jesu, o si nà á. Awọn ọmọ-ogun si hun ade ẹgún, nwọn si fi de e li ori, nwọn si fi aṣọ igunwà elesè àluko wọ̀ ọ. Nwọn si wipe, Kabiyesi, Ọba awọn Ju! nwọn si fi ọwọ́ wọn gbá a loju. Pilatu si tún jade, o si wi fun wọn pe, Wo o, mo mu u jade tọ̀ nyin wá, ki ẹnyin ki o le mọ̀ pe, emi kò ri ẹ̀ṣẹ kan lọwọ rẹ̀. Nitorina Jesu jade wá, ti on ti ade ẹgún ati aṣọ elesè àluko. Pilatu si wi fun wọn pe, Ẹ wò ọkunrin na! Nitorina nigbati awọn olori alufa, ati awọn onṣẹ ri i, nwọn kigbe wipe, Kàn a mọ agbelebu, kàn a mọ agbelebu. Pilatu wi fun wọn pe, Ẹ mu u fun ara nyin, ki ẹ si kàn a mọ agbelebu: nitoriti emi ko ri ẹ̀ṣẹ lọwọ rẹ̀.
Joh 19:1-6 Yoruba Bible (YCE)
Nígbà náà ni Pilatu mú Jesu, ó ní kí wọ́n nà án. Àwọn ọmọ-ogun bá fi ìtàkùn ẹlẹ́gùn-ún hun adé, wọ́n fi dé e lórí; wọn wọ̀ ọ́ ní ẹ̀wù kan bíi ẹ̀wù àlàárì, wọ́n wá ń lọ sọ́dọ̀ rẹ̀, wọ́n ń kí i pé, “Kabiyesi! Ọba àwọn Juu!” Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ń gbá a létí. Pilatu tún jáde lọ sóde, ó sọ fún àwọn Juu pé, “Mò ń mú un tọ̀ yín bọ̀ wá sóde, kí ẹ lè mọ̀ pé èmi kò rí i pé ó jẹ̀bi ohunkohun.” Nígbà náà ni Jesu jáde pẹlu adé ẹ̀gún ati ẹ̀wù àlàárì. Pilatu wá sọ fún wọn pé, “Ẹ wò ó, ọkunrin náà nìyí.” Nígbà tí àwọn olórí alufaa ati àwọn ẹ̀ṣọ́ rí i, wọ́n kígbe pé, “Kàn án mọ́ agbelebu!” Pilatu sọ fún wọn pé, “Ẹ̀yin fúnra yín ẹ mú un, kí ẹ kàn án mọ́ agbelebu, nítorí ní tèmi, n kò rí ẹ̀bi kankan tí ó jẹ.”
Joh 19:1-6 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nítorí náà ni Pilatu mú Jesu, ó sì nà án. Àwọn ọmọ-ogun sì hun adé ẹ̀gún, wọ́n sì fi dé e ní orí, wọ́n sì fi aṣọ ìgúnwà elése àlùkò wọ̀ ọ́. Wọ́n sì wí pé, “Kábíyèsí, ọba àwọn Júù!” Wọ́n sì fi ọwọ́ wọn gbá a ní ojú. Pilatu sì tún jáde, ó sì wí fún wọn pé, “Wò ó, mo mú u jáde tọ̀ yín wá, kí ẹ̀yin kí ó lè mọ̀ pé, èmi kò rí ẹ̀ṣẹ̀ kan lọ́wọ́ rẹ̀.” Nítorí náà Jesu jáde wá, ti òun ti adé ẹ̀gún àti aṣọ elése àlùkò. Pilatu sì wí fún wọn pé, Ẹ wò ọkùnrin náà! Nítorí náà nígbà tí àwọn olórí àlùfáà, àti àwọn oníṣẹ́ rí i, wọ́n kígbe wí pé, “Kàn án mọ́ àgbélébùú, kàn án mọ́ àgbélébùú.” Pilatu wí fún wọn pé, “Ẹ mú un fún ara yín, kí ẹ sì kàn án mọ́ àgbélébùú: nítorí èmi kò rí ẹ̀ṣẹ̀ lọ́wọ́ rẹ̀.”