Joh 17:20-26
Joh 17:20-26 Bibeli Mimọ (YBCV)
Kì si iṣe kìki awọn wọnyi ni mo ngbadura fun, ṣugbọn fun awọn pẹlu ti yio gbà mi gbọ́ nipa ọ̀rọ wọn; Ki gbogbo nwọn ki o le jẹ ọ̀kan; gẹgẹ bi iwọ, Baba, ti jẹ ninu mi, ati emi ninu rẹ, ki awọn pẹlu ki o le jẹ ọ̀kan ninu wa: ki aiye ki o le gbagbọ́ pe, iwọ li o rán mi. Ogo ti iwọ ti fifun mi li emi si ti fifun wọn; ki nwọn ki o le jẹ ọ̀kan, gẹgẹ bi awa ti jẹ ọ̀kan; Emi ninu wọn, ati iwọ ninu mi, ki a le ṣe wọn pé li ọ̀kan; ki aiye ki o le mọ̀ pe, iwọ li o rán mi, ati pe iwọ si fẹràn wọn gẹgẹ bi iwọ ti fẹràn mi. Baba, emi fẹ ki awọn ti iwọ fifun mi, ki o wà lọdọ mi, nibiti emi gbé wà; ki nwọn le mã wò ogo mi, ti iwọ ti fi fifun mi: nitori iwọ sá fẹràn mi ṣiwaju ipilẹṣẹ aiye. Baba olododo, aiye kò mọ̀ ọ: ṣugbọn emi mọ̀ ọ, awọn wọnyi si mọ̀ pe iwọ li o rán mi. Mo ti sọ orukọ rẹ di mimọ̀ fun wọn, emi ó si sọ ọ di mimọ̀: ki ifẹ ti iwọ fẹràn mi, le mã wà ninu wọn, ati emi ninu wọn.
Joh 17:20-26 Yoruba Bible (YCE)
“N kò gbadura fún àwọn wọnyi nìkan. Ṣugbọn mo tún ń gbadura fún àwọn tí yóo gbà mí gbọ́ nípa ọ̀rọ̀ wọn, pé kí gbogbo wọn lè jẹ́ ọ̀kan. Mo gbadura pé, gẹ́gẹ́ bí ìwọ, Baba, ti wà ninu mi, tí èmi náà sì wà ninu rẹ, kí àwọn náà lè wà ninu wa, kí ayé lè gbàgbọ́ pé ìwọ ni ó rán mi níṣẹ́. Ògo tí o fi fún mi ni mo fi fún wọn, kí wọ́n lè jẹ́ ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí àwa náà ti jẹ́ ọ̀kan; èmi ninu wọn ati ìwọ ninu mi, kí wọ́n lè jẹ́ ọ̀kan ṣoṣo, kí ayé lè mọ̀ pé ìwọ ni ó rán mi níṣẹ́, ati pé o fẹ́ràn wọn gẹ́gẹ́ bí o ti fẹ́ràn mi. “Baba, mo fẹ́ kí àwọn tí o fi fún mi wà pẹlu mi níbi tí èmi gan-an bá wà, kí wọ́n lè máa wo ògo tí o ti fi fún mi, nítorí o ti fẹ́ràn mi kí á tó fi ìpìlẹ̀ ayé sọlẹ̀. Baba mímọ́, ayé kò mọ̀ ọ́, ṣugbọn èmi mọ̀ ọ́, ó ti yé àwọn wọnyi pé ìwọ ni ó rán mi níṣẹ́. Mo ti mú kí orúkọ rẹ hàn sí wọn, n óo sì tún fihàn, kí ìfẹ́ tí o fẹ́ mi lè wà ninu wọn, kí èmi náà sì wà ninu wọn.”
Joh 17:20-26 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
“Kì sì í ṣe kìkì àwọn wọ̀nyí ni mo ń gbàdúrà fún, ṣùgbọ́n fún àwọn pẹ̀lú tí yóò gbà mí gbọ́ nípa ọ̀rọ̀ wọn; Kí gbogbo wọn kí ó lè jẹ́ ọ̀kan; gẹ́gẹ́ bí ìwọ, Baba, ti jẹ́ nínú mi, àti èmi nínú rẹ, kí àwọn pẹ̀lú kí ó lè jẹ́ ọ̀kan nínú wa: kí ayé kí ó lè gbàgbọ́ pé, ìwọ ni ó rán mi. Ògo tí ìwọ ti fi fún mi ni èmi sì ti fi fún wọn; kí wọn kí ó lè jẹ́ ọ̀kan, gẹ́gẹ́ bí àwa ti jẹ́ ọ̀kan; Èmi nínú wọn, àti ìwọ nínú mi, kí a lè ṣe wọ́n pé ní ọ̀kan; kí ayé kí ó lè mọ̀ pé, ìwọ ni ó rán mi, àti pé ìwọ sì fẹ́ràn wọn gẹ́gẹ́ bí ìwọ ti fẹ́ràn mi. “Baba, èmi fẹ́ kí àwọn tí ìwọ fi fún mi, kí ó wà lọ́dọ̀ mi, níbi tí èmi gbé wà; kí wọn lè máa wo ògo mi, tí ìwọ ti fi fún mi: nítorí ìwọ sá à fẹ́ràn mi síwájú ìpilẹ̀ṣẹ̀ ayé. “Baba olódodo, ayé kò mọ̀ ọ́n; ṣùgbọ́n èmi mọ̀ ọ́n, àwọn wọ̀nyí sì mọ̀ pé ìwọ ni ó rán mi. Mo ti sọ orúkọ rẹ di mí mọ̀ fún wọn, èmi ó sì sọ ọ́ di mí mọ̀: kí ìfẹ́ tí ìwọ fẹ́ràn mi, lè máa wà nínú wọn, àti èmi nínú wọn.”