Joh 17:13-23

Joh 17:13-23 Yoruba Bible (YCE)

Ṣugbọn nisinsinyii mò ń bọ̀ wá sọ́dọ̀ rẹ. Mò ń sọ ọ̀rọ̀ wọnyi ninu ayé, kí wọ́n lè ní ayọ̀ mi lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́ ninu ọkàn wọn. Mo ti fi ọ̀rọ̀ rẹ fún wọn. Ayé kórìíra wọn nítorí wọn kì í ṣe ti ayé, gẹ́gẹ́ bí èmi náà kì í ti ṣe tíí ayé. N kò bẹ̀bẹ̀ pé kí o mú wọn kúrò ninu ayé. Ẹ̀bẹ̀ mi ni pé kí o pa wọ́n mọ́ kúrò lọ́wọ́ Èṣù. Wọn kì í ṣe ti ayé, gẹ́gẹ́ bí èmi kì í tíí ṣe ti ayé. Fi òtítọ́ yà wọ́n sí mímọ́ fún ara rẹ; òtítọ́ ni ọ̀rọ̀ rẹ. Gẹ́gẹ́ bí o ti rán mi sí ayé, bẹ́ẹ̀ ni mo rán wọn lọ sinu ayé. Nítorí tiwọn ni mo ṣe ya ara mi sí mímọ́, kí àwọn fúnra wọn lè di mímọ́ ninu òtítọ́. “N kò gbadura fún àwọn wọnyi nìkan. Ṣugbọn mo tún ń gbadura fún àwọn tí yóo gbà mí gbọ́ nípa ọ̀rọ̀ wọn, pé kí gbogbo wọn lè jẹ́ ọ̀kan. Mo gbadura pé, gẹ́gẹ́ bí ìwọ, Baba, ti wà ninu mi, tí èmi náà sì wà ninu rẹ, kí àwọn náà lè wà ninu wa, kí ayé lè gbàgbọ́ pé ìwọ ni ó rán mi níṣẹ́. Ògo tí o fi fún mi ni mo fi fún wọn, kí wọ́n lè jẹ́ ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí àwa náà ti jẹ́ ọ̀kan; èmi ninu wọn ati ìwọ ninu mi, kí wọ́n lè jẹ́ ọ̀kan ṣoṣo, kí ayé lè mọ̀ pé ìwọ ni ó rán mi níṣẹ́, ati pé o fẹ́ràn wọn gẹ́gẹ́ bí o ti fẹ́ràn mi.

Joh 17:13-23 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

“Ṣùgbọ́n nísinsin yìí èmi sì ń bọ̀ wá sọ́dọ̀ rẹ, nǹkan wọ̀nyí ni mo sì ń sọ ní ayé, kí wọn kí ó lè ní ayọ̀ mi ní kíkún nínú àwọn tìkára wọn. Èmi ti fi ọ̀rọ̀ rẹ fún wọn; ayé sì ti kórìíra wọn, nítorí tí wọn kì í ṣe ti ayé, gẹ́gẹ́ bí èmi kì í ti í ṣe ti ayé. Èmi kò gbàdúrà pé, kí ìwọ kí ó mú wọn kúrò ní ayé, ṣùgbọ́n kí ìwọ kí ó pa wọ́n mọ́ kúrò nínú ibi. Wọn kì í ṣe ti ayé, gẹ́gẹ́ bí èmi kì í ti í ṣe ti ayé. Sọ wọ́n di mímọ́ nínú òtítọ́: òtítọ́ ni ọ̀rọ̀ rẹ. Gẹ́gẹ́ bí ìwọ ti rán mi wá sí ayé, bẹ́ẹ̀ ni èmi sì rán wọn sí ayé pẹ̀lú. Èmi sì ya ara mi sí mímọ́ nítorí wọn, kí a lè sọ àwọn tìkára wọn pẹ̀lú di mímọ́ nínú òtítọ́. “Kì sì í ṣe kìkì àwọn wọ̀nyí ni mo ń gbàdúrà fún, ṣùgbọ́n fún àwọn pẹ̀lú tí yóò gbà mí gbọ́ nípa ọ̀rọ̀ wọn; Kí gbogbo wọn kí ó lè jẹ́ ọ̀kan; gẹ́gẹ́ bí ìwọ, Baba, ti jẹ́ nínú mi, àti èmi nínú rẹ, kí àwọn pẹ̀lú kí ó lè jẹ́ ọ̀kan nínú wa: kí ayé kí ó lè gbàgbọ́ pé, ìwọ ni ó rán mi. Ògo tí ìwọ ti fi fún mi ni èmi sì ti fi fún wọn; kí wọn kí ó lè jẹ́ ọ̀kan, gẹ́gẹ́ bí àwa ti jẹ́ ọ̀kan; Èmi nínú wọn, àti ìwọ nínú mi, kí a lè ṣe wọ́n pé ní ọ̀kan; kí ayé kí ó lè mọ̀ pé, ìwọ ni ó rán mi, àti pé ìwọ sì fẹ́ràn wọn gẹ́gẹ́ bí ìwọ ti fẹ́ràn mi.