Joh 17:1-3
Joh 17:1-3 Bibeli Mimọ (YBCV)
NKAN wọnyi ni Jesu sọ, o si gbé oju rẹ̀ soke ọrun, o si wipe, Baba, wakati na de: yìn Ọmọ rẹ logo, ki Ọmọ rẹ ki o le yìn ọ logo pẹlu: Gẹgẹ bi iwọ ti fun u li aṣẹ lori enia gbogbo, ki o le fi iye ainipẹkun fun gbogbo awọn ti o fifun u. Iye ainipẹkun na si li eyi, ki nwọn ki o le mọ̀ ọ, iwọ nikan Ọlọrun otitọ, ati Jesu Kristi, ẹniti iwọ rán.
Joh 17:1-3 Yoruba Bible (YCE)
Lẹ́yìn tí Jesu ti sọ ọ̀rọ̀ wọnyi tán, ó gbé ojú sókè ọ̀run, ó ní, “Baba, àkókò náà dé! Jẹ́ kí ògo rẹ hàn lára Ọmọ, kí ògo Ọmọ náà lè hàn lára rẹ. Gẹ́gẹ́ bí o ti fún un ní àṣẹ lórí ẹ̀dá gbogbo, pé kí ó lè fi ìyè ainipẹkun fún gbogbo ẹni tí o ti fún un. Ìyè ainipẹkun náà ni pé, kí wọ́n mọ̀ ọ́, ìwọ Ọlọrun tòótọ́ kanṣoṣo, kí wọ́n sì mọ Jesu Kristi ẹni tí o rán níṣẹ́.
Joh 17:1-3 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nǹkan wọ̀nyí ni Jesu sọ, ó sì gbé ojú rẹ̀ sókè ọ̀run, ó sì wí pé: “Baba, wákàtí náà dé, yin ọmọ rẹ lógo, kí ọmọ rẹ kí ó lè yìn ọ́ lógo pẹ̀lú. Gẹ́gẹ́ bí ìwọ ti fún un ní àṣẹ lórí ènìyàn gbogbo, kí ó lè fi ìyè àìnípẹ̀kun fún gbogbo àwọn tí ó fi fún un. Ìyè àìnípẹ̀kun náà sì ni èyí, kí wọn kí ó lè mọ ìwọ nìkan Ọlọ́run òtítọ́, àti Jesu Kristi, ẹni tí ìwọ rán.