Joh 17:1-26

Joh 17:1-26 Bibeli Mimọ (YBCV)

NKAN wọnyi ni Jesu sọ, o si gbé oju rẹ̀ soke ọrun, o si wipe, Baba, wakati na de: yìn Ọmọ rẹ logo, ki Ọmọ rẹ ki o le yìn ọ logo pẹlu: Gẹgẹ bi iwọ ti fun u li aṣẹ lori enia gbogbo, ki o le fi iye ainipẹkun fun gbogbo awọn ti o fifun u. Iye ainipẹkun na si li eyi, ki nwọn ki o le mọ̀ ọ, iwọ nikan Ọlọrun otitọ, ati Jesu Kristi, ẹniti iwọ rán. Emi ti yìn ọ logo li aiye: emi ti parí iṣẹ ti iwọ fifun mi lati ṣe. Njẹ nisisiyi, Baba, ṣe mi logo pẹlu ara rẹ, ogo ti mo ti ní pẹlu rẹ ki aiye ki o to wà. Emi ti fi orukọ rẹ hàn fun awọn enia ti iwọ ti fifun mi lati inu aiye wá: tirẹ ni nwọn ti jẹ ri, iwọ si ti fi wọn fun mi; nwọn si ti pa ọ̀rọ rẹ mọ́. Nisisiyi nwọn mọ̀ pe, ohunkohun gbogbo ti iwọ ti fifun mi, lati ọdọ rẹ wá ni. Nitori ọ̀rọ ti iwọ fifun mi, emi ti fifun wọn, nwọn si ti gbà a, nwọn si ti mọ̀ nitõtọ pe, lọdọ rẹ ni mo ti jade wá, nwọn si gbagbọ́ pe iwọ li o rán mi. Emi ngbadura fun wọn: emi kò gbadura fun araiye, ṣugbọn fun awọn ti iwọ ti fifun mi; nitoripe tirẹ ni nwọn iṣe. Tirẹ sá ni gbogbo ohun ti iṣe temi, ati temi si ni gbogbo ohun ti iṣe tirẹ; a si ti ṣe mi logo ninu wọn. Emi kò si si li aiye mọ́, awọn wọnyi si mbẹ li aiye, emi si mbọ̀ wá sọdọ rẹ. Baba mimọ́, pa awọn ti o ti fifun mi mọ́, li orukọ rẹ, ki nwọn ki o le jẹ ọ̀kan, ani gẹgẹ bi awa. Nigbati mo wà pẹlu wọn li aiye, mo pa wọn mọ li orukọ rẹ: awọn ti iwọ fifun mi, ni mo ti pamọ́, ẹnikan ninu wọn kò si ṣègbe bikoṣe ọmọ egbé; ki iwe-mimọ́ ki o le ṣẹ. Ṣugbọn nisisiyi emi si mbọ̀ wá sọdọ rẹ, nkan wọnyi ni mo si nsọ li aiye, ki nwọn ki o le ni ayọ̀ mi ni kikun ninu awọn tikarawọn. Emi ti fi ọ̀rọ rẹ fun wọn; aiye si ti korira wọn, nitoriti nwọn kì iṣe ti aiye, gẹgẹ bi emi kì iti iṣe ti aiye. Emi ko gbadura pe, ki iwọ ki o mu wọn kuro li aiye, ṣugbọn ki iwọ ki o pa wọn mọ́ kuro ninu ibi. Nwọn kì iṣe ti aiye, gẹgẹ bi emi kì ti iṣe ti aiye. Sọ wọn di mimọ́ ninu otitọ: otitọ li ọ̀rọ rẹ. Gẹgẹ bi iwọ ti rán mi wá si aiye, bẹ̃ li emi si rán wọn si aiye pẹlu. Emi si yà ara mi si mimọ́ nitori wọn, ki a le sọ awọn tikarawọn pẹlu di mimọ́ ninu otitọ. Kì si iṣe kìki awọn wọnyi ni mo ngbadura fun, ṣugbọn fun awọn pẹlu ti yio gbà mi gbọ́ nipa ọ̀rọ wọn; Ki gbogbo nwọn ki o le jẹ ọ̀kan; gẹgẹ bi iwọ, Baba, ti jẹ ninu mi, ati emi ninu rẹ, ki awọn pẹlu ki o le jẹ ọ̀kan ninu wa: ki aiye ki o le gbagbọ́ pe, iwọ li o rán mi. Ogo ti iwọ ti fifun mi li emi si ti fifun wọn; ki nwọn ki o le jẹ ọ̀kan, gẹgẹ bi awa ti jẹ ọ̀kan; Emi ninu wọn, ati iwọ ninu mi, ki a le ṣe wọn pé li ọ̀kan; ki aiye ki o le mọ̀ pe, iwọ li o rán mi, ati pe iwọ si fẹràn wọn gẹgẹ bi iwọ ti fẹràn mi. Baba, emi fẹ ki awọn ti iwọ fifun mi, ki o wà lọdọ mi, nibiti emi gbé wà; ki nwọn le mã wò ogo mi, ti iwọ ti fi fifun mi: nitori iwọ sá fẹràn mi ṣiwaju ipilẹṣẹ aiye. Baba olododo, aiye kò mọ̀ ọ: ṣugbọn emi mọ̀ ọ, awọn wọnyi si mọ̀ pe iwọ li o rán mi. Mo ti sọ orukọ rẹ di mimọ̀ fun wọn, emi ó si sọ ọ di mimọ̀: ki ifẹ ti iwọ fẹràn mi, le mã wà ninu wọn, ati emi ninu wọn.

Joh 17:1-26 Yoruba Bible (YCE)

Lẹ́yìn tí Jesu ti sọ ọ̀rọ̀ wọnyi tán, ó gbé ojú sókè ọ̀run, ó ní, “Baba, àkókò náà dé! Jẹ́ kí ògo rẹ hàn lára Ọmọ, kí ògo Ọmọ náà lè hàn lára rẹ. Gẹ́gẹ́ bí o ti fún un ní àṣẹ lórí ẹ̀dá gbogbo, pé kí ó lè fi ìyè ainipẹkun fún gbogbo ẹni tí o ti fún un. Ìyè ainipẹkun náà ni pé, kí wọ́n mọ̀ ọ́, ìwọ Ọlọrun tòótọ́ kanṣoṣo, kí wọ́n sì mọ Jesu Kristi ẹni tí o rán níṣẹ́. Èmi ti fi ògo fún ọ ninu ayé, mo ti parí iṣẹ́ tí o fún mi ṣe. Nisinsinyii, Baba, jẹ́ kí ògo rẹ hàn lára mi; àní kí irú ògo tí mo ti ní pẹlu rẹ kí a tó dá ayé tún hàn lára mi. “Mo ti fi orúkọ rẹ han àwọn eniyan tí o fún mi ninu ayé. Tìrẹ ni wọ́n, ìwọ ni o wá fi wọ́n fún mi. Wọ́n sì ti pa ọ̀rọ̀ rẹ mọ́. Nisinsinyii ó ti yé wọn pé láti ọ̀dọ̀ rẹ ni ohun gbogbo tí o fún mi ti wá. Nítorí àwọn ọ̀rọ̀ tí o fún mi ni mo ti fún wọn. Wọ́n ti gba àwọn ọ̀rọ̀ náà, ó ti wá yé wọn pé nítòótọ́, láti ọ̀dọ̀ rẹ ni mo ti wá, wọ́n sì gbàgbọ́ pé ìwọ ni ó rán mi níṣẹ́. “Àwọn ni mò ń gbadura fún, n kò gbadura fún aráyé; ṣugbọn mò ń gbadura fún àwọn tí o ti fún mi, nítorí tìrẹ ni wọ́n. Ohun gbogbo tí mo ní, tìrẹ ni; ohun gbogbo tí ìwọ náà sì ní, tèmi ni. Wọ́n ti jẹ́ kí ògo mi yọ. Èmi kò ní sí ninu ayé mọ́, ṣugbọn àwọn wà ninu ayé. Èmi ń bọ̀ wá sọ́dọ̀ rẹ. Baba mímọ́, fi agbára orúkọ rẹ pa àwọn tí o ti fi fún mi mọ́, kí wọ́n lè jẹ́ ọ̀kan, gẹ́gẹ́ bí àwa náà ti jẹ́ ọ̀kan. Nígbà tí mo wà lọ́dọ̀ wọn, mo fi agbára orúkọ rẹ pa àwọn tí o ti fi fún mi mọ́. Mo pa wọ́n mọ́, ọ̀kan ninu wọn kò ṣègbé àfi ọmọ ègbé, kí Ìwé Mímọ́ lè ṣẹ. Ṣugbọn nisinsinyii mò ń bọ̀ wá sọ́dọ̀ rẹ. Mò ń sọ ọ̀rọ̀ wọnyi ninu ayé, kí wọ́n lè ní ayọ̀ mi lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́ ninu ọkàn wọn. Mo ti fi ọ̀rọ̀ rẹ fún wọn. Ayé kórìíra wọn nítorí wọn kì í ṣe ti ayé, gẹ́gẹ́ bí èmi náà kì í ti ṣe tíí ayé. N kò bẹ̀bẹ̀ pé kí o mú wọn kúrò ninu ayé. Ẹ̀bẹ̀ mi ni pé kí o pa wọ́n mọ́ kúrò lọ́wọ́ Èṣù. Wọn kì í ṣe ti ayé, gẹ́gẹ́ bí èmi kì í tíí ṣe ti ayé. Fi òtítọ́ yà wọ́n sí mímọ́ fún ara rẹ; òtítọ́ ni ọ̀rọ̀ rẹ. Gẹ́gẹ́ bí o ti rán mi sí ayé, bẹ́ẹ̀ ni mo rán wọn lọ sinu ayé. Nítorí tiwọn ni mo ṣe ya ara mi sí mímọ́, kí àwọn fúnra wọn lè di mímọ́ ninu òtítọ́. “N kò gbadura fún àwọn wọnyi nìkan. Ṣugbọn mo tún ń gbadura fún àwọn tí yóo gbà mí gbọ́ nípa ọ̀rọ̀ wọn, pé kí gbogbo wọn lè jẹ́ ọ̀kan. Mo gbadura pé, gẹ́gẹ́ bí ìwọ, Baba, ti wà ninu mi, tí èmi náà sì wà ninu rẹ, kí àwọn náà lè wà ninu wa, kí ayé lè gbàgbọ́ pé ìwọ ni ó rán mi níṣẹ́. Ògo tí o fi fún mi ni mo fi fún wọn, kí wọ́n lè jẹ́ ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí àwa náà ti jẹ́ ọ̀kan; èmi ninu wọn ati ìwọ ninu mi, kí wọ́n lè jẹ́ ọ̀kan ṣoṣo, kí ayé lè mọ̀ pé ìwọ ni ó rán mi níṣẹ́, ati pé o fẹ́ràn wọn gẹ́gẹ́ bí o ti fẹ́ràn mi. “Baba, mo fẹ́ kí àwọn tí o fi fún mi wà pẹlu mi níbi tí èmi gan-an bá wà, kí wọ́n lè máa wo ògo tí o ti fi fún mi, nítorí o ti fẹ́ràn mi kí á tó fi ìpìlẹ̀ ayé sọlẹ̀. Baba mímọ́, ayé kò mọ̀ ọ́, ṣugbọn èmi mọ̀ ọ́, ó ti yé àwọn wọnyi pé ìwọ ni ó rán mi níṣẹ́. Mo ti mú kí orúkọ rẹ hàn sí wọn, n óo sì tún fihàn, kí ìfẹ́ tí o fẹ́ mi lè wà ninu wọn, kí èmi náà sì wà ninu wọn.”

Joh 17:1-26 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Nǹkan wọ̀nyí ni Jesu sọ, ó sì gbé ojú rẹ̀ sókè ọ̀run, ó sì wí pé: “Baba, wákàtí náà dé, yin ọmọ rẹ lógo, kí ọmọ rẹ kí ó lè yìn ọ́ lógo pẹ̀lú. Gẹ́gẹ́ bí ìwọ ti fún un ní àṣẹ lórí ènìyàn gbogbo, kí ó lè fi ìyè àìnípẹ̀kun fún gbogbo àwọn tí ó fi fún un. Ìyè àìnípẹ̀kun náà sì ni èyí, kí wọn kí ó lè mọ ìwọ nìkan Ọlọ́run òtítọ́, àti Jesu Kristi, ẹni tí ìwọ rán. Èmi ti yìn ọ́ lógo ní ayé: èmi ti parí iṣẹ́ tí ìwọ fi fún mi láti ṣe. Ǹjẹ́ nísinsin yìí, Baba, ṣe mí lógo pẹ̀lú ara rẹ, ògo tí mo ti ní pẹ̀lú rẹ kí ayé kí ó tó wà. “Èmi ti fi orúkọ rẹ hàn fún àwọn ènìyàn tí ìwọ ti fún mi láti inú ayé wá: tìrẹ ni wọ́n ti jẹ́, ìwọ sì ti fi wọ́n fún mi; wọ́n sì ti pa ọ̀rọ̀ rẹ mọ́. Nísinsin yìí, wọ́n mọ̀ pé ohunkóhun gbogbo tí ìwọ ti fi fún mi, láti ọ̀dọ̀ rẹ wá ni. Nítorí ọ̀rọ̀ tí ìwọ fi fún mi, èmi ti fi fún wọn, wọ́n sì ti gbà á, wọ́n sì ti mọ̀ nítòótọ́ pé, lọ́dọ̀ rẹ ni mo ti jáde wá, wọ́n sì gbàgbọ́ pé ìwọ ni ó rán mi. Èmi ń gbàdúrà fún wọn: èmi kò gbàdúrà fún aráyé, ṣùgbọ́n fún àwọn tí ìwọ ti fi fún mi; nítorí pé tìrẹ ni wọ́n í ṣe. Tìrẹ sá à ni gbogbo ohun tí í ṣe tèmi, àti tèmi sì ni gbogbo ohun tí í ṣe tìrẹ, a sì ti ṣe mí lógo nínú wọn. Èmi kò sí ní ayé mọ́, àwọn wọ̀nyí sì ń bẹ ní ayé, èmi sì ń bọ̀ wá sọ́dọ̀ rẹ. Baba mímọ́, pa àwọn tí o ti fi fún mi mọ́, ní orúkọ rẹ, kí wọn kí ó lè jẹ́ ọ̀kan, àní gẹ́gẹ́ bí àwa. Nígbà tí mo wà pẹ̀lú wọn ní ayé, mo pa wọ́n mọ́ ní orúkọ rẹ; àwọn tí ìwọ fi fún mi, ni mo ti pamọ́, ẹnìkan nínú wọn kò sọnù bí kò ṣe ọmọ ègbé; kí ìwé mímọ́ kí ó le ṣẹ. “Ṣùgbọ́n nísinsin yìí èmi sì ń bọ̀ wá sọ́dọ̀ rẹ, nǹkan wọ̀nyí ni mo sì ń sọ ní ayé, kí wọn kí ó lè ní ayọ̀ mi ní kíkún nínú àwọn tìkára wọn. Èmi ti fi ọ̀rọ̀ rẹ fún wọn; ayé sì ti kórìíra wọn, nítorí tí wọn kì í ṣe ti ayé, gẹ́gẹ́ bí èmi kì í ti í ṣe ti ayé. Èmi kò gbàdúrà pé, kí ìwọ kí ó mú wọn kúrò ní ayé, ṣùgbọ́n kí ìwọ kí ó pa wọ́n mọ́ kúrò nínú ibi. Wọn kì í ṣe ti ayé, gẹ́gẹ́ bí èmi kì í ti í ṣe ti ayé. Sọ wọ́n di mímọ́ nínú òtítọ́: òtítọ́ ni ọ̀rọ̀ rẹ. Gẹ́gẹ́ bí ìwọ ti rán mi wá sí ayé, bẹ́ẹ̀ ni èmi sì rán wọn sí ayé pẹ̀lú. Èmi sì ya ara mi sí mímọ́ nítorí wọn, kí a lè sọ àwọn tìkára wọn pẹ̀lú di mímọ́ nínú òtítọ́. “Kì sì í ṣe kìkì àwọn wọ̀nyí ni mo ń gbàdúrà fún, ṣùgbọ́n fún àwọn pẹ̀lú tí yóò gbà mí gbọ́ nípa ọ̀rọ̀ wọn; Kí gbogbo wọn kí ó lè jẹ́ ọ̀kan; gẹ́gẹ́ bí ìwọ, Baba, ti jẹ́ nínú mi, àti èmi nínú rẹ, kí àwọn pẹ̀lú kí ó lè jẹ́ ọ̀kan nínú wa: kí ayé kí ó lè gbàgbọ́ pé, ìwọ ni ó rán mi. Ògo tí ìwọ ti fi fún mi ni èmi sì ti fi fún wọn; kí wọn kí ó lè jẹ́ ọ̀kan, gẹ́gẹ́ bí àwa ti jẹ́ ọ̀kan; Èmi nínú wọn, àti ìwọ nínú mi, kí a lè ṣe wọ́n pé ní ọ̀kan; kí ayé kí ó lè mọ̀ pé, ìwọ ni ó rán mi, àti pé ìwọ sì fẹ́ràn wọn gẹ́gẹ́ bí ìwọ ti fẹ́ràn mi. “Baba, èmi fẹ́ kí àwọn tí ìwọ fi fún mi, kí ó wà lọ́dọ̀ mi, níbi tí èmi gbé wà; kí wọn lè máa wo ògo mi, tí ìwọ ti fi fún mi: nítorí ìwọ sá à fẹ́ràn mi síwájú ìpilẹ̀ṣẹ̀ ayé. “Baba olódodo, ayé kò mọ̀ ọ́n; ṣùgbọ́n èmi mọ̀ ọ́n, àwọn wọ̀nyí sì mọ̀ pé ìwọ ni ó rán mi. Mo ti sọ orúkọ rẹ di mí mọ̀ fún wọn, èmi ó sì sọ ọ́ di mí mọ̀: kí ìfẹ́ tí ìwọ fẹ́ràn mi, lè máa wà nínú wọn, àti èmi nínú wọn.”