Joh 15:16-20
Joh 15:16-20 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ki iṣe ẹnyin li o yàn mi, ṣugbọn emi li o yàn nyin, mo si fi nyin sipo, ki ẹnyin ki o le lọ, ki ẹ si so eso, ati ki eso nyin le duro; ki ohunkohun ti ẹ ba bère lọwọ Baba li orukọ mi, ki o le fi i fun nyin. Nkan wọnyi ni mo palaṣẹ fun nyin pe, ki ẹnyin ki o fẹran ara nyin. Bi aiye ba korira nyin, ẹ mọ̀ pe, o ti korira mi ṣaju nyin. Ibaṣepe ẹnyin iṣe ti aiye, aiye iba fẹ awọn tirẹ̀; ṣugbọn nitoriti ẹnyin kì iṣe ti aiye, ṣugbọn emi ti yàn nyin kuro ninu aiye, nitori eyi li aiye ṣe korira nyin. Ẹ ranti ọ̀rọ ti mo ti sọ fun nyin pe, Ọmọ-ọdọ kò tobi jù oluwa rẹ̀ lọ. Bi nwọn ba ti ṣe inunibini si mi, nwọn ó ṣe inunibini si nyin pẹlu: bi nwọn ba ti pa ọ̀rọ mi mọ́, nwọn ó si pa ti nyin mọ́ pẹlu.
Joh 15:16-20 Yoruba Bible (YCE)
Kì í ṣe ẹ̀yin ni ẹ yàn mí. Èmi ni mo yàn yín, tí mo ran yín pé kí ẹ lọ máa so èso tí kò ní bàjẹ́, kí Baba lè fun yín ní ohunkohun tí ẹ bá bèèrè ní orúkọ mi. Àṣẹ yìí ni mo pa fun yín: ẹ fẹ́ràn ara yín. “Bí aráyé bá kórìíra yín, kí ẹ mọ̀ pé èmi ni wọ́n kọ́ kórìíra ṣáájú yín. Bí ó bá jẹ́ pé ti ayé ni yín, ayé ìbá fẹ́ràn yín bí àwọn ẹni tirẹ̀. Ṣugbọn ẹ kì í ṣe ti ayé nítorí mo ti yàn yín kúrò ninu ayé; ìdí rẹ̀ nìyí tí ayé fi kórìíra yín. Ẹ ranti ọ̀rọ̀ tí mo ti sọ fun yín, pé, ‘Ọmọ-ọ̀dọ̀ kò ju ọ̀gá rẹ̀ lọ.’ Bí wọ́n bá ṣe inúnibíni mi, wọn yóo ṣe inúnibíni yín. Bí wọ́n bá pa ọ̀rọ̀ mi mọ́, wọn yóo pa ti ẹ̀yin náà mọ́.
Joh 15:16-20 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Kì í ṣe ẹ̀yin ni ó yàn mí, ṣùgbọ́n èmi ni ó yàn yín, mo sì fi yín sípò, kí ẹ̀yin kí ó lè lọ, kí ẹ sì so èso, àti kí èso yín lè dúró; kí ohunkóhun tí ẹ bá béèrè lọ́wọ́ Baba ní orúkọ mi, kí ó lè fi í fún yín. Nǹkan wọ̀nyí ni mo pàṣẹ fún yín pé, kí ẹ̀yin kí ó fẹ́ràn ara yín. “Bí ayé bá kórìíra yín, ẹ mọ̀ pé, ó ti kórìíra mi ṣáájú yín. Ìbá ṣe pé ẹ̀yin ń ṣe ti ayé, ayé ìbá fẹ́ yin bi àwọn tirẹ̀; gẹ́gẹ́ bi o ṣe ri tí ẹ̀yin kì ń ṣe ti ayé, ṣùgbọ́n èmi ti yàn yín kúrò nínú ayé, nítorí èyí ni ayé ṣe kórìíra yín. Ẹ rántí ọ̀rọ̀ tí mo ti sọ fún yín pé, ‘Ọmọ ọ̀dọ̀ kò tóbi ju olúwa rẹ̀ lọ.’ Bí wọ́n bá ti ṣe inúnibíni sí mi, wọ́n ó ṣe inúnibíni sí yín pẹ̀lú: bí wọ́n bá ti pa ọ̀rọ̀ mi mọ́, wọ́n ó sì pa tiyín mọ́ pẹ̀lú.