Joh 14:27-29
Joh 14:27-29 Bibeli Mimọ (YBCV)
Alafia ni mo fi silẹ fun nyin, alafia mi ni mo fifun nyin: kì iṣe gẹgẹ bi aiye iti fi funni li emi fifun nyin. Ẹ máṣe jẹ ki okàn nyin daru, ẹ má si jẹ ki o warìri. Ẹnyin sá ti gbọ́ bi mo ti wi fun nyin pe, Emi nlọ, emi ó si tọ̀ nyin wá. Ibaṣepe ẹnyin fẹràn mi, ẹnyin iba yọ̀ nitori emi nlọ sọdọ Baba: nitori Baba mi tobi jù mi lọ. Emi si ti sọ fun nyin nisisiyi ki o to ṣẹ, pe nigbati o ba ṣẹ, ki ẹ le gbagbọ́.

Joh 14:27-29 Yoruba Bible (YCE)
“Alaafia ni mo fi sílẹ̀ fun yín. Alaafia mi ni mo fun yín. Kì í ṣe bí ayé ti í fúnni ni mo fun yín. Ẹ má jẹ́ kí ọkàn yín dàrú, ẹ má sì jẹ́ kí ẹ̀rù bà yín. Ẹ gbọ́ nígbà tí mo sọ fun yín pé, ‘Mò ń lọ, ṣugbọn n óo tún pada wá sọ́dọ̀ yín.’ Bí ẹ bá fẹ́ràn mi ni, yíyọ̀ ni ẹ̀ bá máa yọ̀ pé, mò ń lọ sọ́dọ̀ Baba, nítorí Baba jù mí lọ. Mo wí fun yín nisinsinyii kí ó tó ṣẹlẹ̀, kí ẹ lè gbàgbọ́ nígbà tí ó bá ṣẹlẹ̀ tán.
Joh 14:27-29 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Àlàáfíà ni mo fi sílẹ̀ fún yín pé, àlàáfíà mi ni mo fi fún yin, kì í ṣe bí ayé ti fi fún ni. Ẹ má ṣe jẹ́ kí ọkàn yín dàrú, ẹ má sì jẹ́ kí ó wárìrì. “Ẹ̀yin sá ti gbọ́ bí mo ti wí fún yín pé, ‘Èmi ń lọ, èmi ó sì tọ̀ yín wá.’ Ìbá ṣe pé ẹ̀yin fẹ́ràn mi, ẹ̀yin ìbá yọ̀ nítorí èmi ń lọ sọ́dọ̀ Baba; nítorí Baba mi tóbi jù mí lọ. Èmi sì ti sọ fún yín nísinsin yìí kí ó tó ṣẹ, pé nígbà tí ó bá ṣẹ, kí ẹ lè gbàgbọ́.