Joh 14:22-27
Joh 14:22-27 Bibeli Mimọ (YBCV)
Judasi wi fun u pe, (kì iṣe Iskariotu) Oluwa, ẽhatiṣe ti iwọ ó fi ara rẹ hàn fun awa, ti kì yio si ṣe fun araiye? Jesu dahùn o si wi fun u pe, Bi ẹnikan ba fẹràn mi, yio pa ọ̀rọ mi mọ́: Baba mi yio si fẹran rẹ̀, awa o si tọ̀ ọ wá, a o si ṣe ibugbe wa pẹlu rẹ̀. Ẹniti kò fẹràn mi ni ko pa ọ̀rọ mi mọ́: ọ̀rọ ti ẹnyin ngbọ́ kì si iṣe ti emi, ṣugbọn ti Baba ti o rán mi. Nkan wọnyi li emi ti sọ fun nyin, nigbati mo mba nyin gbe. Ṣugbọn Olutunu na, Ẹmí Mimọ́, ẹniti Baba yio rán li orukọ mi, on ni yio kọ́ nyin li ohun gbogbo, yio si rán nyin leti ohun gbogbo ti mo ti sọ fun nyin. Alafia ni mo fi silẹ fun nyin, alafia mi ni mo fifun nyin: kì iṣe gẹgẹ bi aiye iti fi funni li emi fifun nyin. Ẹ máṣe jẹ ki okàn nyin daru, ẹ má si jẹ ki o warìri.
Joh 14:22-27 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Judasi (kì í ṣe Judasi Iskariotu) wí fún un pé, “Olúwa, èéha ti ṣe tí ìwọ ó fi ara rẹ hàn fún àwa, tí kì yóò sì ṣe fún aráyé?” Jesu dáhùn ó sì wí fún un pé, “Bí ẹnìkan bá fẹ́ràn mi, yóò pa ọ̀rọ̀ mi mọ́; Baba mi yóò sì fẹ́ràn rẹ̀, àwa ó sì tọ̀ ọ́ wá, a ó sì ṣe ibùgbé wa pẹ̀lú rẹ̀. Ẹni tí kò fẹ́ràn mi ni kò pa ọ̀rọ̀ mi mọ́; ọ̀rọ̀ tí ẹ̀yin ń gbọ́ kì í ṣe ti èmi, ṣùgbọ́n ti Baba tí ó rán mi. “Nǹkan wọ̀nyí ni èmi ti sọ fún yín, nígbà tí mo ń bá yín gbé. Ṣùgbọ́n Olùtùnú náà, Ẹ̀mí Mímọ́, ẹni tí Baba yóò rán ní orúkọ mi, òun ni yóò kọ́ yín ní ohun gbogbo, yóò sì rán yín létí ohun gbogbo tí mo ti sọ fún yín. Àlàáfíà ni mo fi sílẹ̀ fún yín pé, àlàáfíà mi ni mo fi fún yin, kì í ṣe bí ayé ti fi fún ni. Ẹ má ṣe jẹ́ kí ọkàn yín dàrú, ẹ má sì jẹ́ kí ó wárìrì.
Joh 14:22-27 Yoruba Bible (YCE)
Judasi keji, (kì í ṣe Judasi Iskariotu), bi í pé, “Oluwa, kí ló dé tí o ṣe wí pé o kò ní fi ara rẹ han aráyé, ṣugbọn àwa ni ìwọ óo fi ara hàn?” Jesu dá a lóhùn pé, “Ẹnikẹ́ni tí ó bá fẹ́ràn mi yóo tẹ̀lé ọ̀rọ̀ mi. Baba mi yóo fẹ́ràn rẹ̀, èmi ati Baba mi yóo wá sọ́dọ̀ rẹ̀, a óo fi ọ̀dọ̀ rẹ̀ ṣe ibùgbé. Ẹni tí kò bá fẹ́ràn mi kò ní tẹ̀lé ọ̀rọ̀ mi. Ọ̀rọ̀ tí ẹ ń gbọ́ kì í ṣe tèmi, ti Baba tí ó rán mi níṣẹ́ ni. “Mo ti sọ nǹkan wọnyi fun yín nígbà tí mo ṣì wà lọ́dọ̀ yín. Ṣugbọn Alátìlẹ́yìn náà, Ẹ̀mí Mímọ́ tí Baba yóo rán wá ní orúkọ mi, ni yóo kọ yín, tí yóo sì ran yín létí ohun gbogbo tí mo sọ fun yín. “Alaafia ni mo fi sílẹ̀ fun yín. Alaafia mi ni mo fun yín. Kì í ṣe bí ayé ti í fúnni ni mo fun yín. Ẹ má jẹ́ kí ọkàn yín dàrú, ẹ má sì jẹ́ kí ẹ̀rù bà yín.