Joh 14:15-24

Joh 14:15-24 Yoruba Bible (YCE)

“Bí ẹ bá fẹ́ràn mi, ẹ óo pa òfin mi mọ́. N óo bèèrè lọ́wọ́ Baba, yóo wá fun yín ní Alátìlẹ́yìn mìíràn tí yóo wà pẹlu yín títí lae. Òun ni Ẹ̀mí tí ń fi òtítọ́ Ọlọrun hàn. Ayé kò lè gbà á nítorí ayé kò rí i, bẹ́ẹ̀ ni kò mọ̀ ọ́n. Ṣugbọn ẹ̀yin mọ̀ ọ́n, nítorí ó ń ba yín gbé, ó sì wà ninu yín. “Èmi kò ní fi yín sílẹ̀ bí aláìlárá. Mò ń pada bọ̀ wá sọ́dọ̀ yín. Láìpẹ́, ayé kò ní rí mi mọ́, ṣugbọn ẹ̀yin yóo rí mi. Nítorí èmi wà láàyè, ẹ̀yin náà yóo wà láàyè. Ní ọjọ́ náà, ẹ̀yin yóo mọ̀ pé èmi wà ninu Baba mi, ati pé ẹ̀yin wà ninu mi, èmi náà sì wà ninu yín. “Ẹni tí ó bá gba òfin mi, tí ó sì pa wọ́n mọ́, òun ni ó fẹ́ràn mi. Ẹni tí ó bá fẹ́ràn mi, Baba mi yóo fẹ́ràn rẹ̀, èmi náà yóo fẹ́ràn rẹ̀, n óo sì fi ara mi hàn án.” Judasi keji, (kì í ṣe Judasi Iskariotu), bi í pé, “Oluwa, kí ló dé tí o ṣe wí pé o kò ní fi ara rẹ han aráyé, ṣugbọn àwa ni ìwọ óo fi ara hàn?” Jesu dá a lóhùn pé, “Ẹnikẹ́ni tí ó bá fẹ́ràn mi yóo tẹ̀lé ọ̀rọ̀ mi. Baba mi yóo fẹ́ràn rẹ̀, èmi ati Baba mi yóo wá sọ́dọ̀ rẹ̀, a óo fi ọ̀dọ̀ rẹ̀ ṣe ibùgbé. Ẹni tí kò bá fẹ́ràn mi kò ní tẹ̀lé ọ̀rọ̀ mi. Ọ̀rọ̀ tí ẹ ń gbọ́ kì í ṣe tèmi, ti Baba tí ó rán mi níṣẹ́ ni.

Joh 14:15-24 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

“Bí ẹ̀yin bá fẹ́ràn mi, ẹ ó pa òfin mi mọ́. Nígbà náà èmi yóò wá béèrè lọ́wọ́ Baba. Òun yóò sì fún yín ní olùtùnú mìíràn. Olùtùnú náà yóò máa bá yín gbé títí láé Òun ni Ẹ̀mí òtítọ́. Ayé kò le gbà á. Nítorí ayé kò mọ̀ ọ́n, bẹ́ẹ̀ ni kò rí i rí. Ẹ̀yin mọ̀ ọn nítorí láti ìgbà tí ẹ ti wà pẹ̀lú mí. Òun náà ti wà pẹ̀lú yín. Ṣùgbọ́n ní ọjọ́ kan yóò wọ inú yín láti máa gbé ibẹ̀. Èmi kò ní fi yín sílẹ̀ láìní Olùtùnú, kí ẹ ma dàbí ọmọ tí kò ní òbí. Rárá o! Mo tún ń tọ̀ yín bọ̀. Nígbà díẹ̀ sí i, ayé kì yóò rí mi mọ́; ṣùgbọ́n ẹ̀yin yóò rí mi: nítorí tí èmi wà láààyè, ẹ̀yin yóò wà láààyè pẹ̀lú. Ní ọjọ́ náà ni ẹ̀yin yóò mọ̀ pé, èmi wà nínú Baba mi, àti ẹ̀yin nínú mi, àti èmi nínú yín. Ẹni tí ó bá ní òfin mi, tí ó bá sì ń pa wọ́n mọ́, òun ni ẹni tí ó fẹ́ràn mi: ẹni tí ó bá sì fẹ́ràn mi, a ó fẹ́ràn rẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Baba mi, èmi ó sì fẹ́ràn rẹ̀, èmi ó sì fi ara mi hàn fún un.” Judasi (kì í ṣe Judasi Iskariotu) wí fún un pé, “Olúwa, èéha ti ṣe tí ìwọ ó fi ara rẹ hàn fún àwa, tí kì yóò sì ṣe fún aráyé?” Jesu dáhùn ó sì wí fún un pé, “Bí ẹnìkan bá fẹ́ràn mi, yóò pa ọ̀rọ̀ mi mọ́; Baba mi yóò sì fẹ́ràn rẹ̀, àwa ó sì tọ̀ ọ́ wá, a ó sì ṣe ibùgbé wa pẹ̀lú rẹ̀. Ẹni tí kò fẹ́ràn mi ni kò pa ọ̀rọ̀ mi mọ́; ọ̀rọ̀ tí ẹ̀yin ń gbọ́ kì í ṣe ti èmi, ṣùgbọ́n ti Baba tí ó rán mi.

YouVersion nlo awọn kuki lati ṣe adani iriri rẹ. Nipa lilo oju opo wẹẹbu wa, o gba lilo awọn kuki wa gẹgẹbi a ti ṣalaye ninu Eto Afihan wa