Joh 12:37-43
Joh 12:37-43 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ṣugbọn bi o ti ṣe ọ̀pọlọpọ iṣẹ ami to bayi li oju wọn, nwọn kò gbà a gbọ́; Ki ọ̀rọ woli Isaiah lè ṣẹ, eyiti o sọ pe, Oluwa, tali o gbà iwasu wa gbọ́? ati tali a si fi apá Oluwa hàn fun? Nitori eyi ni nwọn kò fi le gbagbọ́, nitori Isaiah si tún sọ pe, O ti fọ́ wọn loju, o si ti se àiya wọn le; ki nwọn má ba fi oju wọn ri, ki nwọn má ba fi ọkàn wọn mọ̀, ki nwọn má ba yipada, ki emi má ba mu wọn larada. Nkan wọnyi ni Isaiah wi, nitori o ti ri ogo rẹ̀, o si sọ̀rọ rẹ̀. Sibẹ ọ̀pọ ninu awọn olori gbà a gbọ́ pẹlu; ṣugbọn nitori awọn Farisi nwọn kò jẹwọ rẹ̀, ki a má bà yọ wọn kuro ninu sinagogu: Nitori nwọn fẹ iyìn enia jù iyìn ti Ọlọrun lọ.
Joh 12:37-43 Yoruba Bible (YCE)
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Jesu ti ṣe ọpọlọpọ iṣẹ́ ìyanu lójú wọn, sibẹ wọn kò gbà á gbọ́. Èyí mú kí ọ̀rọ̀ wolii Aisaya ṣẹ nígbà tí ó sọ pé, “Oluwa, ta ni ó gba ìròyìn wa gbọ́? Ta ni a fi agbára Oluwa hàn fún?” Nítorí èyí ni wọn kò fi lè gbàgbọ́, nítorí Aisaya tún sọ pé, “Ojú wọn ti fọ́, ọkàn wọn sì ti le; kí wọn má baà fi ojú wọn ríran, kí òye má baà yé wọn. Kí wọn má baà yipada, kí n má baà wò wọ́n sàn.” Aisaya sọ nǹkan wọnyi nítorí ó rí ògo Jesu, ó wá sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa rẹ̀. Sibẹ ọpọlọpọ ninu àwọn aṣaaju gbà á gbọ́; ṣugbọn wọn kò jẹ́wọ́ nítorí wọ́n bẹ̀rù àwọn Farisi, kí wọn má baà yọ wọ́n kúrò ninu àwùjọ; nítorí wọ́n fẹ́ràn ìyìn eniyan ju ìyìn Ọlọrun lọ.
Joh 12:37-43 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ṣùgbọ́n bí ó ti ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ iṣẹ́ ààmì tó báyìí lójú wọn, wọn kò gbà á gbọ́. Kí ọ̀rọ̀ wòlíì Isaiah lè ṣẹ, èyí tí ó sọ pé: “Olúwa, ta ni ó gba ìwàásù wa gbọ́ Àti ta ni a sì fi apá Olúwa hàn fún?” Nítorí èyí ni wọn kò fi lè gbàgbọ́, nítorí Isaiah sì tún sọ pé: “Ó ti fọ́ wọn lójú, Ó sì ti sé àyà wọn le; kí wọn má ba à fi ojú wọn rí, kí wọn má ba à fi ọkàn wọn mọ̀, kí wọn má ba à yípadà, kí èmi má ba à mú wọn láradá.” Nǹkan wọ̀nyí ni Isaiah wí, nítorí ó ti rí ògo rẹ̀, ó sì sọ̀rọ̀ rẹ̀. Síbẹ̀ ọ̀pọ̀ nínú àwọn olórí gbà á gbọ́ pẹ̀lú; ṣùgbọ́n nítorí àwọn Farisi wọn kò jẹ́wọ́ rẹ̀, kí a má ba à yọ wọ́n kúrò nínú Sinagọgu: Nítorí wọ́n fẹ́ ìyìn ènìyàn ju ìyìn ti Ọlọ́run lọ.