Joh 12:23-36

Joh 12:23-36 Bibeli Mimọ (YBCV)

Jesu si da wọn lohùn wipe, Wakati na de, ti a o ṣe Ọmọ-enia logo. Lõtọ, lõtọ ni mo wi fun nyin, Bikoṣepe wóro alikama ba bọ́ si ilẹ̀, ti o ba si kú, o wà on nikan: ṣugbọn bi o ba kú, a si so ọ̀pọlọpọ eso. Ẹniti o ba fẹ ẹmí rẹ̀ yio sọ ọ nù; ẹniti o ba si korira ẹmi rẹ̀ li aiye yi ni yio si pa a mọ́ titi fi di ìye ainipẹkun. Bi ẹnikẹni ba nsìn mi, ki o ma tọ̀ mi lẹhin: ati nibiti emi ba wà, nibẹ̀ ni iranṣẹ mi yio wà pẹlu: bi ẹnikẹni ba nsìn mi, on ni Baba yio bù ọlá fun. Nisisiyi li a npọ́n ọkàn mi loju; kili emi o si wi? Baba, gbà mi kuro ninu wakati yi: ṣugbọn nitori eyi ni mo ṣe wá si wakati yi. Baba, ṣe orukọ rẹ logo. Nitorina ohùn kan ti ọrun wá, wipe, Emi ti ṣe e logo na, emi o si tún ṣe e logo. Nitorina ijọ enia ti o duro nibẹ̀, ti nwọn si gbọ́ ọ, wipe, Ãrá nsán: awọn ẹlomiran wipe, Angẹli kan li o mba a sọrọ. Jesu si dahùn wipe, Ki iṣe nitori mi li ohùn yi ṣe wá, bikoṣe nitori nyin. Nisisiyi ni idajọ aiye yi de: nisisiyi li a o lé alade aiye yi jade. Ati emi, bi a ba gbé mi soke kuro li aiye, emi o fà gbogbo enia sọdọ ara mi. Ṣugbọn o wi eyi, o nṣapẹrẹ irú ikú ti on o kú. Nitorina awọn ijọ enia da a lohùn wipe, Awa gbọ́ ninu ofin pe, Kristi wà titi lailai: iwọ ha ṣe wipe, A kò le ṣaima gbé Ọmọ-enia soke? Tani iṣe Ọmọ-enia yi? Nigbana ni Jesu wi fun wọn pe, Nigba diẹ si i ni imọlẹ wà lãrin nyin. Ẹ mã rìn nigbati ẹnyin ni imọlẹ, ki òkunkun máṣe ba le nyin: ẹniti o ba si nrìn li òkunkun kò mọ̀ ibiti on gbé nlọ. Nigbati ẹnyin ni imọlẹ, ẹ gbà imọlẹ gbọ́, ki ẹ le jẹ ọmọ imọlẹ. Nkan wọnyi ni Jesu sọ, o si jade lọ, o fi ara pamọ́ fun wọn.

Joh 12:23-36 Yoruba Bible (YCE)

Jesu dá wọn lóhùn pé, “Àkókò náà dé wàyí tí a óo ṣe Ọmọ-Eniyan lógo. Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé bí ẹyọ irúgbìn kan kò bá bọ́ sílẹ̀, kí ó kú, òun nìkan ni yóo dá wà. Ṣugbọn bí ó bá kú, á mú ọpọlọpọ èso wá. Ẹni tí ó bá fẹ́ràn ẹ̀mí rẹ̀ yóo pàdánù rẹ̀, ṣugbọn ẹni tí ó bá kórìíra ẹ̀mí rẹ̀ ní ayé yìí yóo pa á mọ́ títí di ìyè ainipẹkun. Bí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ jẹ́ iranṣẹ mi, ó níláti tẹ̀lé mi. Níbi tí èmi alára bá wà, níbẹ̀ ni iranṣẹ mi yóo wà. Bí ẹnikẹ́ni bá jẹ́ iranṣẹ mi, Baba mi yóo dá a lọ́lá.” Jesu bá tún sọ pé, “Ọkàn mí dàrú nisinsinyii. Kí ni ǹ bá wí? Ọkàn kan ń sọ pé kí n wí pé, ‘Baba, yọ mí kúrò ninu àkókò yìí.’ Ṣugbọn nítorí àkókò yìí gan-an ni mo ṣe wá sí ayé. Baba, ṣe orúkọ rẹ lógo.” Ohùn kan bá wá láti ọ̀run, ó ní, “Mo ti ṣe é lógo ná, èmi óo sì tún ṣe é lógo sí i.” Ọpọlọpọ ninu àwọn eniyan tí wọ́n dúró, tí wọ́n gbọ́, ń sọ pé, “Ààrá sán!” Àwọn ẹlòmíràn ń sọ pé, “Angẹli ló bá a sọ̀rọ̀.” Jesu wí fún wọn pé, “Ohùn yìí kò wá nítorí tèmi bí kò ṣe nítorí tiyín. Àkókò tó fún ìdájọ́ ayé yìí. Nisinsinyii ni a óo lé aláṣẹ ayé yìí jáde. Ní tèmi, bí a bá gbé mi sókè kúrò láyé, n óo fa gbogbo eniyan sọ́dọ̀ mi.” Ó sọ èyí, ó fi ṣe àkàwé irú ikú tí yóo kú. Àwọn eniyan bi í pé, “A gbọ́ ninu òfin pé Mesaya wà títí lae. Kí ni ìtumọ̀ ohun tí o sọ pé dandan ni kí á gbé Ọmọ-Eniyan sókè? Ta ni ń jẹ́ Ọmọ-Eniyan?” Jesu dá wọn lóhùn pé, “Ìmọ́lẹ̀ wà láàrin yín fún àkókò díẹ̀ sí i. Ẹ máa rìn níwọ̀n ìgbà tí ẹ ní ìmọ́lẹ̀, kí òkùnkùn má baà bò yín mọ́lẹ̀. Ẹni tí ó bá ń rìn ninu òkùnkùn kò mọ ibi tí ó ń lọ. Níwọ̀n ìgbà tí ẹ ní ìmọ́lẹ̀, ẹ gba ìmọ́lẹ̀ náà gbọ́, kí ẹ lè jẹ́ ọmọ ìmọ́lẹ̀.” Nígbà tí Jesu sọ báyìí tán, ó fara pamọ́ fún wọn.

Joh 12:23-36 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Jesu sì dá wọn lóhùn pé, “Wákàtí náà dé, tí a ó ṣe Ọmọ ènìyàn lógo. Lóòótọ́, lóòótọ́ ni mo wí fún yín, bí kò ṣe pé alikama bá bọ́ sí ilẹ̀, tí ó bá sì kú, ó wà ní òun nìkan; ṣùgbọ́n bí ó bá kú, yóò sì so ọ̀pọ̀lọpọ̀ èso. Ẹni tí ó bá fẹ́ ẹ̀mí rẹ̀ yóò sọ ọ́ nù; ẹni tí ó bá sì kórìíra ẹ̀mí rẹ̀ láyé yìí ni yóò sì pa á mọ́ títí ó fi di ìyè àìnípẹ̀kun. Bí ẹnikẹ́ni bá ń sìn mí, kí ó máa tọ̀ mí lẹ́yìn: àti pe níbi tí èmi bá wà, níbẹ̀ ni ìránṣẹ́ mi yóò wà pẹ̀lú: bí ẹnikẹ́ni bá ń sìn mí, òun ni Baba yóò bu ọlá fún. “Ní ìsinsin yìí ni a ń pọ́n ọkàn mi lójú; kín ni èmi ó sì wí? ‘Baba, gbà mí kúrò nínú wákàtí yìí’? Rárá, ṣùgbọ́n nítorí èyí ni mo ṣe wá sí wákàtí yìí. Baba, ṣe orúkọ rẹ lógo!” Nígbà náà ni ohùn kan ti ọ̀run wá, wí pé, “Èmi ti ṣe é lógo!” Nítorí náà ìjọ ènìyàn tí ó dúró níbẹ̀, tí wọ́n sì gbọ́ ọ, wí pé, àrá ń sán: àwọn ẹlòmíràn wí pé, “angẹli kan ni ó ń bá a sọ̀rọ̀.” Jesu sì dáhùn wí pé, “Kì í ṣe nítorí mi ni ohùn yìí ṣe wá, bí kò ṣe nítorí yín. Ní ìsinsin yìí ni ìdájọ́ ayé yìí dé: nísinsin yìí ni a ó lé aládé ayé yìí jáde. Àti èmi, bí a bá gbé mi sókè kúrò ní ayé, èmi ó fa gbogbo ènìyàn sọ́dọ̀ ara mi!” Ṣùgbọ́n ó wí èyí, ó ń ṣe àpẹẹrẹ irú ikú tí òun yóò kú. Nítorí náà àwọn ìjọ ènìyàn dá a lóhùn pé, “Àwa gbọ́ nínú òfin pé, Kristi wà títí láéláé: ìwọ ha ṣe wí pé, ‘A ó gbé ọmọ ènìyàn sókè? Ta ni ó ń jẹ́ ọmọ ènìyàn yìí’?” Nígbà náà ni Jesu wí fún wọn pé, “Nígbà díẹ̀ sí i ni ìmọ́lẹ̀ wà láàrín yín, ẹ máa rìn nígbà tí ẹ̀yin ní ìmọ́lẹ̀, kí òkùnkùn má ṣe bá yín: ẹni tí ó bá sì ń rìn ní òkùnkùn kò mọ ibi òun ń lọ. Nígbà tí ẹ̀yin ní ìmọ́lẹ̀, ẹ gba ìmọ́lẹ̀ gbọ́, kí ẹ lè jẹ́ ọmọ ìmọ́lẹ̀!” Nǹkan wọ̀nyí ni Jesu sọ, ó sì jáde lọ, ó fi ara pamọ́ fún wọn.