Joh 11:5-9
Joh 11:5-9 Bibeli Mimọ (YBCV)
Jesu si fẹran Marta, ati arabinrin rẹ̀, ati Lasaru. Nitorina nigbati o ti gbọ́ pe, ara rẹ̀ kò da, o gbé ijọ meji si i nibikanna ti o gbé wà. Njẹ lẹhin eyi li o wi fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ pe, Ẹ jẹ ki a tún pada lọ si Judea. Awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ si wi fun u pe, Rabbi, ni lọ̃lọ̃ yi li awọn Ju nwá ọ̀na ati sọ ọ li okuta; iwọ si ntún pada lọ sibẹ̀? Jesu dahún pe, Wakati mejila ki mbẹ ninu ọsán kan? Bi ẹnikan ba rìn li ọsán, kì yio kọsẹ̀, nitoriti o ri imọlẹ aiye yi.
Joh 11:5-9 Yoruba Bible (YCE)
Jesu fẹ́ràn Mata ati arabinrin rẹ̀ ati Lasaru. Nígbà tí Jesu gbọ́ pé Lasaru ń ṣàìsàn, kò kúrò ní ibi tí ó wà fún ọjọ́ meji. Lẹ́yìn náà ni ó ṣẹ̀ṣẹ̀ wá wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “Ẹ jẹ́ kí á tún pada lọ sí Judia.” Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sọ fún un pé, “Olùkọ́ni, láìpẹ́ yìí ni àwọn Juu ń fẹ́ sọ ọ́ ní òkúta, o tún fẹ́ lọ sibẹ?” Jesu ní, “Ṣebí wakati mejila ni ó wà ninu ọjọ́ kan? Bí ẹnikẹ́ni bá rìn ní ọ̀sán kò ní kọsẹ̀, nítorí ó ń fi ìmọ́lẹ̀ ayé yìí ríran.
Joh 11:5-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (BMYO)
Jesu sì fẹ́ràn Marta, àti arábìnrin rẹ̀ àti Lasaru. Nítorí náà, nígbà tí ó ti gbọ́ pé, ara rẹ̀ kò dá, ó gbé ọjọ́ méjì sí i níbìkan náà tí ó gbé wà. Ǹjẹ́ lẹ́yìn èyí ni ó wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “Ẹ jẹ́ kí a tún padà lọ sí Judea.” Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sì wí fún un pé, “Rabbi, ní àìpẹ́ yìí ni àwọn Júù ń wá ọ̀nà láti sọ ọ́ ní òkúta; ìwọ sì tún padà lọ síbẹ̀?” Jesu dáhùn pé, “Wákàtí méjìlá kọ́ ni ó bẹ nínú ọ̀sán kan bí? Bí ẹnìkan bá rìn ní ọ̀sán, kì yóò kọsẹ̀, nítorí tí ó rí ìmọ́lẹ̀ ayé yìí.