Joh 11:45-54
Joh 11:45-54 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nitorina li ọ̀pọ awọn Ju ti o wá sọdọ Maria, ti nwọn ri ohun ti Jesu ṣe, nwọn gbà a gbọ. Ṣugbọn awọn ẹlomiran ninu wọn tọ̀ awọn Farisi lọ, nwọn si sọ fun wọn ohun ti Jesu ṣe. Nigbana li awọn olori alufa ati awọn Farisi pè igbimọ jọ, nwọn si wipe, Kili awa nṣe? nitori ọkunrin yi nṣe ọ̀pọlọpọ iṣẹ àmi. Bi awa ba jọwọ rẹ̀ bẹ̃, gbogbo enia ni yio gbà a gbọ́: awọn ará Romu yio si wá gbà ilẹ ati orilẹ-ède wa pẹlu. Ṣugbọn Kaiafa, ọkan ninu wọn, ẹniti iṣe olori alufa li ọdún na, o wi fun wọn pe, Ẹnyin kò mọ̀ ohunkohun rara. Bẹ̃ni ẹ kò si ronu pe, o ṣànfani fun wa, ki enia kan kú fun awọn enia, ki gbogbo orilẹ-ède ki o má bà ṣegbé. Ki iṣe fun ara rẹ̀ li o sọ eyi: ṣugbọn bi o ti jẹ olori alufa li ọdún na, o sọtẹlẹ pe, Jesu yio kú fun orilẹ-ède na: Ki si iṣe kìki fun orilẹ-ède na nikan, ṣugbọn pẹlu ki o le kó awọn ọmọ Ọlọrun ti a ti fọnka kiri jọ li ọkanṣoṣo. Nitorina lati ọjọ na lọ ni nwọn ti jọ gbìmọ pọ̀ lati pa a. Nitorina Jesu kò rìn ni gbangba larin awọn Ju mọ́; ṣugbọn o ti ibẹ̀ lọ si igberiko kan ti o sunmọ aginjù, si ilu nla ti à npè ni Efraimu, nibẹ̀ li o si wà pẹlu awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀.
Joh 11:45-54 Yoruba Bible (YCE)
Ọpọlọpọ ninu àwọn Juu tí ó wá sọ́dọ̀ Maria gba Jesu gbọ́ nígbà tí wọ́n rí ohun tí ó ṣe. Ṣugbọn àwọn kan ninu wọn lọ sọ́dọ̀ àwọn Farisi, wọ́n lọ sọ ohun gbogbo tí Jesu ṣe. Àwọn olórí alufaa ati àwọn Farisi bá pe ìgbìmọ̀, wọ́n ní, “Kí ni a óo ṣe o, nítorí ọkunrin yìí ń ṣe iṣẹ́ ìyanu pupọ? Bí a bá fi í sílẹ̀ báyìí, gbogbo eniyan ni yóo gbà á gbọ́, àwọn ará Romu yóo bá wá, wọn yóo wo Tẹmpili yìí, bẹ́ẹ̀ ni wọn yóo pa orílẹ̀-èdè wa run.” Nígbà náà ni ọ̀kan ninu wọn, Kayafa, tí ó jẹ́ Olórí Alufaa ní ọdún náà, sọ fún wọn pé, “Ẹ kò mọ nǹkankan! Ẹ kò rí i pé ó sàn kí ẹnìkan kú fún àwọn eniyan jù pé kí gbogbo orílẹ̀-èdè ṣègbé!” Kì í ṣe àròsọ ti ara rẹ̀ ni ó fi sọ gbolohun yìí, ṣugbọn nítorí ó jẹ́ olórí alufaa ní ọdún náà, ó sọ àsọtẹ́lẹ̀ ni, pé Jesu yóo kú fún orílẹ̀-èdè wọn. Kì í wá ṣe fún orílẹ̀-èdè wọn nìkan, ṣugbọn kí àwọn ọmọ Ọlọrun tí ó fọ́nká lè papọ̀ di ọ̀kan. Láti ọjọ́ náà ni wọ́n ti ń gbèrò ọ̀nà tí wọn yóo fi pa Jesu. Nítorí náà, Jesu kò rìn ní gbangba mọ́ láàrin àwọn Juu, ṣugbọn ó kúrò níbẹ̀, ó lọ sí ìlú kan lẹ́bàá aṣálẹ̀, tí ó ń jẹ́ Efuraimu. Níbẹ̀ ni ó ń gbé pẹlu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀.
Joh 11:45-54 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nítorí náà ni ọ̀pọ̀ àwọn Júù tí ó wá sọ́dọ̀ Maria, tí wọ́n rí ohun tí Jesu ṣe, ṣe gbà á gbọ́. Ṣùgbọ́n àwọn ẹlòmíràn nínú wọn tọ àwọn Farisi lọ, wọ́n sì sọ fún wọn ohun tí Jesu ṣe. Nígbà náà ni àwọn olórí àlùfáà àti àwọn Farisi pe ìgbìmọ̀ jọ. Wọ́n sì wí pé, “Kín ni yóò jẹ àṣeyọrí wa? Nítorí ọkùnrin yìí ń ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ iṣẹ́ ààmì. Bí àwa bá fi í sílẹ̀ bẹ́ẹ̀, gbogbo ènìyàn ni yóò gbà á gbọ́: àwọn ará Romu yóò sì wá gba ilẹ̀ àti orílẹ̀-èdè wa pẹ̀lú.” Ṣùgbọ́n Kaiafa, ọ̀kan nínú wọn, ẹni tí í ṣe olórí àlùfáà ní ọdún náà, ó wí fún wọn pé, “Ẹ̀yin kò mọ ohunkóhun rárá! Bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò sì ronú pé, ó ṣàǹfààní fún wa, kí ènìyàn kan kú fún àwọn ènìyàn kí gbogbo orílẹ̀-èdè má ba à ṣègbé.” Kì í ṣe fún ara rẹ̀ ni ó sọ èyí ṣùgbọ́n bí ó ti jẹ́ olórí àlùfáà ní ọdún náà, ó sọtẹ́lẹ̀ pé, Jesu yóò kú fún orílẹ̀-èdè náà: Kì sì í ṣe kìkì fún orílẹ̀-èdè náà nìkan, ṣùgbọ́n fún àwọn ọmọ Ọlọ́run tí ó fọ́nká kiri, kí ó le kó wọn papọ̀, kí ó sì sọ wọ́n di ọ̀kan. Nítorí náà, láti ọjọ́ náà lọ ni wọ́n ti jọ gbìmọ̀ pọ̀ láti pa á. Nítorí náà Jesu kò rìn ní gbangba láàrín àwọn Júù mọ́; ṣùgbọ́n ó ti ibẹ̀ lọ sí ìgbèríko kan tí ó súnmọ́ aginjù, sí ìlú ńlá kan tí a ń pè ní Efraimu, níbẹ̀ ni ó sì wà pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀.