Joh 11:41-44
Joh 11:41-44 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nigbana ni nwọn gbé okuta na kuro nibiti a gbe tẹ́ okú na si. Jesu si gbé oju rẹ̀ soke, o si wipe, Baba, mo dupẹ lọwọ rẹ, nitoriti iwọ gbọ́ ti emi. Emi si ti mọ̀ pe, iwọ a ma gbọ́ ti emi nigbagbogbo: ṣugbọn nitori ijọ enia ti o duro yi ni mo ṣe wi i, ki nwọn ki o le gbagbọ́ pe iwọ li o rán mi. Nigbati o si ti wi bẹ̃ tan, o kigbe li ohùn rara pe, Lasaru, jade wá. Ẹniti o kú na si jade wá, ti a fi aṣọ okú dì tọwọ tẹsẹ a si fi gèle dì i loju. Jesu wi fun wọn pe, Ẹ tú u, ẹ si jẹ ki o mã lọ.
Joh 11:41-44 Yoruba Bible (YCE)
Wọ́n bá gbé òkúta náà kúrò. Jesu gbé ojú sókè, ó ní, “Baba, mo dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ nítorí ò ń gbọ́ tèmi. Mo mọ̀ pé nígbà gbogbo ni ò ń gbọ́ tèmi, ṣugbọn nítorí ti àwọn eniyan tí ó dúró yíká ni mo ṣe sọ èyí kí wọ́n lè gbàgbọ́ pé ìwọ ni o rán mi níṣẹ́.” Nígbà tí ó ti sọ báyìí tán, ó kígbe sókè pé, “Lasaru, jáde wá!” Ẹni tí ó ti kú náà bá jáde pẹlu aṣọ òkú tí wọ́n fi wé e lọ́wọ́ ati lẹ́sẹ̀ ati ọ̀já tí wọ́n fi dì í lójú. Jesu wí fún wọn pé, “Ẹ tú aṣọ kúrò lára rẹ̀, kí ẹ jẹ́ kí ó máa lọ.”
Joh 11:41-44 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nígbà náà ni wọ́n gbé òkúta náà kúrò (níbi tí a tẹ́ ẹ sí). Jesu sì gbé ojú rẹ̀ sókè, ó sì wí pé, “Baba, mo dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ nítorí tí ìwọ gbọ́ tèmi. Èmi sì ti mọ̀ pé, ìwọ a máa gbọ́ ti èmi nígbà gbogbo: ṣùgbọ́n nítorí ìjọ ènìyàn tí ó dúró yìí ni mo ṣe wí i, kí wọn ba à lè gbàgbọ́ pé ìwọ ni ó rán mi.” Nígbà tí ó sì wí bẹ́ẹ̀ tan, ó kígbe lóhùn rara pé, “Lasaru, jáde wá.” Ẹni tí ó kú náà sì jáde wá, tí a fi aṣọ òkú dì tọwọ́ tẹsẹ̀ a sì fi gèlè dì í lójú. Jesu wí fún wọn pé, “Ẹ tú u, ẹ sì jẹ́ kí ó máa lọ!”