Joh 11:32-39
Joh 11:32-39 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nigbati Maria si de ibiti Jesu gbé wà, ti o si ri i, o wolẹ lẹba ẹsẹ rẹ̀, o wi fun u pe, Oluwa, ibaṣepe iwọ ti wà nihin, arakunrin mi kò ba má kú. Njẹ nigbati Jesu ri i, ti o nsọkun, ati awọn Ju ti o ba a wá nsọkun pẹlu rẹ̀, o kerora li ọkàn rẹ̀, inu rẹ̀ si bajẹ, O si wipe, Nibo li ẹnyin gbé tẹ́ ẹ si? Nwọn si wi fun u pe, Oluwa, wá wò o. Jesu sọkun. Nitorina awọn Ju wipe, sa wo o bi o ti fẹràn rẹ̀ to! Awọn kan ninu wọn si wipe, Ọkunrin yi, ẹniti o là oju afọju, kò le ṣe ki ọkunrin yi má ku bi? Nigbana ni Jesu tún kerora ninu ara rẹ̀, o wá si ibojì. O si jẹ ihò, a si gbé okuta le ẹnu rẹ̀. Jesu wipe, Ẹ gbé okuta na kuro. Marta, arabinrin ẹniti o kú na wi fun u pe, Oluwa, o ti nrùn nisisiyi: nitoripe o di ijọ mẹrin ti o ti kú.
Joh 11:32-39 Yoruba Bible (YCE)
Nígbà tí Maria dé ibi tí Jesu wà, bí ó ti rí i, ó kúnlẹ̀ níwájú rẹ̀, ó ní, “Oluwa, ìbá jẹ́ pé o wà níhìn-ín, arakunrin mi kì bá tí kú.” Nígbà tí Jesu rí i tí ó ń sunkún, tí àwọn Juu tí ó bá a jáde tún ń sunkún, orí rẹ̀ wú, ọkàn rẹ̀ wá bàjẹ́. Ó bi wọ́n pé, “Níbo ni ẹ tẹ́ ẹ sí?” Wọ́n sọ fún un pé, “Oluwa, wá wò ó.” Ni Jesu bá bú sẹ́kún. Nígbà náà ni àwọn Juu sọ pé, “Ẹ ò rí i bí ó ti fẹ́ràn rẹ̀ tó!” Àwọn kan ninu wọn ń sọ pé, “Ọkunrin yìí tí ó la ojú afọ́jú, ǹjẹ́ kò lè ṣe é kí ọkunrin yìí má fi kú?” Orí Jesu tún wú, ó bá lọ síbi ibojì. Ninu ihò òkúta ni ibojì náà wà, òkúta sì wà ní ẹnu ọ̀nà rẹ̀. Jesu wí fún wọn pé, “Ẹ gbé òkúta náà kúrò.” Mata, arabinrin ẹni tí ó kú, sọ fún un pé, “Oluwa, ó ti ń rùn, nítorí ó ti di òkú ọjọ́ mẹrin!”
Joh 11:32-39 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nígbà tí Maria sì dé ibi tí Jesu wà, tí ó sì rí i, ó wólẹ̀ lẹ́bàá ẹsẹ̀ rẹ̀, ó wí fún un pé, “Olúwa, ìbá ṣe pé ìwọ ti wà níhìn-ín, arákùnrin mi kì bá kú.” Nígbà tí Jesu rí i, tí ó ń sọkún, àti àwọn Júù tí ó bá a wá ń sọkún pẹ̀lú rẹ̀, ó kérora nínú ẹ̀mí, inú rẹ̀ sì bàjẹ́. Ó sì wí pé, “Níbo ni ẹ̀yin gbé tẹ́ ẹ sí?” Wọ́n sì wí fún un pé, “Olúwa, wá wò ó.” Jesu sọkún. Nítorí náà àwọn Júù wí pé, “Sá wò ó bí ó ti fẹ́ràn rẹ̀ tó!” Àwọn kan nínú wọn sì wí pé, “Ọkùnrin yìí, ẹni tí ó la ojú afọ́jú, kò lè ṣe é kí ọkùnrin yìí má kú bí?” Nígbà náà ni Jesu tún kérora nínú ara rẹ̀, ó wá sí ibojì, ó sì jẹ́ ihò, a sì gbé òkúta lé ẹnu rẹ̀. Jesu wí pé, “Ẹ gbé òkúta náà kúrò!” Marta, arábìnrin ẹni tí ó kú náà wí fún un pé, “Olúwa, ó ti ń rùn nísinsin yìí: nítorí pé ó di ọjọ́ kẹrin tí ó tí kú.”