Joh 11:1-16

Joh 11:1-16 Bibeli Mimọ (YBCV)

ARA ọkunrin kan si ṣe alaidá, Lasaru, ara Betani, ti iṣe ilu Maria ati Marta arabinrin rẹ̀. (Maria na li ẹniti o fi ororo ikunra kùn Oluwa, ti o si fi irun ori rẹ̀ nù ẹsẹ rẹ̀ nù, arakunrin rẹ̀ ni Lasaru iṣe, ara ẹniti kò dá.) Nitorina awọn arabinrin rẹ̀ ranṣẹ si i, wipe, Oluwa, wo o, ara ẹniti iwọ fẹran kò da. Nigbati Jesu si gbọ́, o wipe, Aisan yi kì iṣe si ikú, ṣugbọn fun ogo Ọlọrun, ki a le yìn Ọmọ Ọlọrun logo nipasẹ rẹ̀. Jesu si fẹran Marta, ati arabinrin rẹ̀, ati Lasaru. Nitorina nigbati o ti gbọ́ pe, ara rẹ̀ kò da, o gbé ijọ meji si i nibikanna ti o gbé wà. Njẹ lẹhin eyi li o wi fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ pe, Ẹ jẹ ki a tún pada lọ si Judea. Awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ si wi fun u pe, Rabbi, ni lọ̃lọ̃ yi li awọn Ju nwá ọ̀na ati sọ ọ li okuta; iwọ si ntún pada lọ sibẹ̀? Jesu dahún pe, Wakati mejila ki mbẹ ninu ọsán kan? Bi ẹnikan ba rìn li ọsán, kì yio kọsẹ̀, nitoriti o ri imọlẹ aiye yi. Ṣugbọn bi ẹnikan ba rìn li oru, yio kọsẹ̀, nitoriti kò si imọlẹ ninu rẹ̀. Nkan wọnyi li o sọ: lẹhin eyini o si wi fun wọn pe, Lasaru ọrẹ́ wa sùn; ṣugbọn emi nlọ ki emi ki o le jí i dide ninu orun rẹ̀. Nitorina awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ wi fun u pe, Oluwa, bi o ba ṣe pe o sùn, yio sàn. Ṣugbọn Jesu nsọ ti ikú rẹ̀: ṣugbọn nwọn rò pe, o nsọ ti orun sisun. Nigbana ni Jesu wi fun wọn gbangba pe, Lasaru kú. Emi si yọ̀ nitori nyin, ti emi kò si nibẹ̀, Ki ẹ le gbagbọ́; ṣugbọn ẹ jẹ ki a lọ sọdọ rẹ̀. Nitorina Tomasi, ẹniti a npè ni Didimu, wi fun awọn ọmọ-ẹhin ẹgbẹ rẹ̀ pe, Ẹ jẹ ki awa na lọ, ki a le ba a kú pẹlu.

Joh 11:1-16 Yoruba Bible (YCE)

Ọkunrin kan tí ń jẹ́ Lasaru ń ṣàìsàn. Ní Bẹtani ni ó ń gbé, ní ìlú kan náà pẹlu Maria ati Mata arabinrin rẹ̀. Maria yìí ni obinrin tí ó tú òróró olóòórùn dídùn sára Oluwa ní ọjọ́ kan, tí ó fi irun orí rẹ̀ nu ẹsẹ̀ Jesu. Lasaru tí ó ń ṣàìsàn jẹ́ arakunrin Maria yìí. Àwọn arabinrin mejeeji yìí ranṣẹ lọ sọ́dọ̀ Jesu pé, “Oluwa, ẹni tí o fẹ́ràn ń ṣàìsàn.” Nígbà tí Jesu gbọ́, ó ní, “Àìsàn yìí kì í ṣe ti ikú, fún ògo Ọlọrun ni, kí á lè ṣe Ọmọ Ọlọrun lógo nípa rẹ̀ ni.” Jesu fẹ́ràn Mata ati arabinrin rẹ̀ ati Lasaru. Nígbà tí Jesu gbọ́ pé Lasaru ń ṣàìsàn, kò kúrò ní ibi tí ó wà fún ọjọ́ meji. Lẹ́yìn náà ni ó ṣẹ̀ṣẹ̀ wá wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “Ẹ jẹ́ kí á tún pada lọ sí Judia.” Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sọ fún un pé, “Olùkọ́ni, láìpẹ́ yìí ni àwọn Juu ń fẹ́ sọ ọ́ ní òkúta, o tún fẹ́ lọ sibẹ?” Jesu ní, “Ṣebí wakati mejila ni ó wà ninu ọjọ́ kan? Bí ẹnikẹ́ni bá rìn ní ọ̀sán kò ní kọsẹ̀, nítorí ó ń fi ìmọ́lẹ̀ ayé yìí ríran. Ṣugbọn ẹnikẹ́ni tí ó bá ń rìn lálẹ́ níí kọsẹ̀, nítorí kò sí ìmọ́lẹ̀ ninu rẹ̀.” Lẹ́yìn tí ó ti sọ báyìí tán, ó sọ fún wọn pé, “Lasaru ọ̀rẹ́ wa ti sùn, mò ń lọ jí i.” Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sọ fún un pé, “Oluwa, bí ó bá sùn, yóo tún jí.” Ohun tí Jesu ń sọ̀rọ̀ bá ni ikú Lasaru, ṣugbọn wọ́n rò pé nípa oorun sísùn ni ó ń sọ. Nígbà náà ni Jesu wá wí fún wọn pàtó pé, “Lasaru ti kú. Ó dùn mọ́ mi nítorí yín pé n kò sí níbẹ̀, kí ẹ lè gbàgbọ́. Ẹ jẹ́ kí á lọ sọ́dọ̀ rẹ̀.” Nígbà náà ni Tomasi tí wọn ń pè ní Didimu (tí ìtumọ̀ rẹ̀ jẹ́ “Ìbejì”) sọ fún àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ pé, “Ẹ jẹ́ kí á lọ kí àwa náà lè bá a kú.”

Joh 11:1-16 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Ara ọkùnrin kan kò sì dá, Lasaru, ará Betani, tí í ṣe ìlú Maria àti Marta arábìnrin rẹ̀. Maria náà ni ẹni tí ó fi òróró ìkunra kun Olúwa, tí ó sì fi irun orí rẹ̀ nù ún, arákùnrin rẹ̀ ni Lasaru í ṣe, ara ẹni tí kò dá. Nítorí náà, àwọn arábìnrin rẹ̀ ránṣẹ́ sí i, wí pé, “Olúwa, wò ó, ara ẹni tí ìwọ fẹ́ràn kò dá.” Nígbà tí Jesu sì gbọ́, ó wí pé, “Àìsàn yìí kì í ṣe sí ikú, ṣùgbọ́n fún Ògo Ọlọ́run, kí a lè yin Ọmọ Ọlọ́run lógo nípasẹ̀ rẹ̀.” Jesu sì fẹ́ràn Marta, àti arábìnrin rẹ̀ àti Lasaru. Nítorí náà, nígbà tí ó ti gbọ́ pé, ara rẹ̀ kò dá, ó gbé ọjọ́ méjì sí i níbìkan náà tí ó gbé wà. Ǹjẹ́ lẹ́yìn èyí ni ó wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “Ẹ jẹ́ kí a tún padà lọ sí Judea.” Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sì wí fún un pé, “Rabbi, ní àìpẹ́ yìí ni àwọn Júù ń wá ọ̀nà láti sọ ọ́ ní òkúta; ìwọ sì tún padà lọ síbẹ̀?” Jesu dáhùn pé, “Wákàtí méjìlá kọ́ ni ó bẹ nínú ọ̀sán kan bí? Bí ẹnìkan bá rìn ní ọ̀sán, kì yóò kọsẹ̀, nítorí tí ó rí ìmọ́lẹ̀ ayé yìí. Ṣùgbọ́n bí ẹnìkan bá rìn ní òru, yóò kọsẹ̀, nítorí tí kò sí ìmọ́lẹ̀ nínú rẹ̀.” Nǹkan wọ̀nyí ni ó sọ: lẹ́yìn èyí nì ó sì wí fún wọn pé, “Lasaru ọ̀rẹ́ wa sùn; ṣùgbọ́n èmi ń lọ kí èmi kí ó lè jí i dìde nínú orun rẹ̀.” Nítorí náà àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ wí fún un pé, “Olúwa, bí ó bá ṣe pé ó sùn, yóò sàn.” Ṣùgbọ́n Jesu ń sọ ti ikú rẹ̀: ṣùgbọ́n wọ́n rò pé, ó ń sọ ti orun sísùn. Nígbà náà ni Jesu wí fún wọn gbangba pé, “Lasaru ti kú. Èmi sì yọ̀ nítorí yín, tí èmi kò sí níbẹ̀. Kí ẹ le gbàgbọ́; ṣùgbọ́n ẹ jẹ́ kí a lọ sọ́dọ̀ rẹ̀.” Nítorí náà Tomasi, ẹni tí à ń pè ní Didimu, wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn ẹgbẹ́ rẹ̀ pé, “Ẹ jẹ́ kí àwa náà lọ, kí a lè bá a kú pẹ̀lú.”