Joh 10:12-14
Joh 10:12-14 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ṣugbọn alagbaṣe, ti kì iṣe oluṣọ-agutan, ẹniti awọn agutan kì iṣe tirẹ̀, o ri ikõkò mbọ̀, o si fi awọn agutan silẹ, o si sá lọ: ikõkò si mu awọn agutan, o si fọn wọn ká kiri. Alagbaṣe sá lọ nitoriti iṣe alagbaṣe, kò si náni awọn agutan. Emi ni oluṣọ-agutan rere, mo si mọ̀ awọn temi, awọn temi si mọ̀ mi.
Joh 10:12-14 Yoruba Bible (YCE)
Alágbàṣe tí kì í ṣe olùṣọ́-aguntan, tí kì í sìí ṣe olówó aguntan, bí ó bá rí ìkookò tí ń bọ̀, a fi àwọn aguntan sílẹ̀, a sálọ. Ìkookò a gbé ninu àwọn aguntan lọ, a sì tú wọn ká, nítorí alágbàṣe lásán ni, kò bìkítà fún àwọn aguntan. Èmi ni olùṣọ́-aguntan rere. Mo mọ àwọn tèmi, àwọn tèmi náà sì mọ̀ mí
Joh 10:12-14 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ṣùgbọ́n alágbàṣe, tí kì í ṣe olùṣọ́-àgùntàn, ẹni tí àwọn àgùntàn kì í ṣe tirẹ̀, ó rí ìkookò ń bọ̀, ó sì fi àgùntàn sílẹ̀, ó sì fọ́n wọn ká kiri. Òun sálọ nítorí tí ó jẹ́ alágbàṣe, kò sì náání àwọn àgùntàn. “Èmi ni olùṣọ́-àgùntàn rere, mo sì mọ àwọn tèmi, àwọn tèmi sì mọ̀ mí.