Joh 10:1-18
Joh 10:1-18 Bibeli Mimọ (YBCV)
LÕTỌ, lõtọ ni mo wi fun nyin, Ẹniti kò ba gbà ẹnu-ọ̀na wọ̀ inu agbo agutan, ṣugbọn ti o ba gbà ibomiran gùn oke, on na li olè ati ọlọṣà. Ṣugbọn ẹniti o ba ba ti ẹnu-ọ̀na wọle, on ni iṣe oluṣọ awọn agutan. On ni oludèna ṣilẹkun fun; awọn agutan si gbọ ohùn rẹ̀: o si pè awọn agutan tirẹ̀ li orukọ, o si ṣe amọ̀na wọn jade. Nigbati o si mu awọn agutan tirẹ̀ jade, o ṣiwaju wọn, awọn agutan si ntọ̀ ọ lẹhin: nitoriti nwọn mọ̀ ohùn rẹ̀. Nwọn kò jẹ tọ̀ alejò lẹhin, ṣugbọn nwọn a ma sá lọdọ rẹ̀: nitoriti nwọn kò mọ̀ ohùn alejò. Owe yi ni Jesu pa fun wọn: ṣugbọn òye ohun ti nkan wọnni jẹ ti o nsọ fun wọn kò yé wọn. Nitorina Jesu tún wi fun wọn pe, Lõtọ, lõtọ ni mo wi fun nyin, Emi ni ilẹkun awọn agutan. Olè ati ọlọṣà ni gbogbo awọn ti o ti wá ṣiwaju mi: ṣugbọn awọn agutan kò gbọ́ ti wọn. Emi ni ilẹkun: bi ẹnikan ba ba ọdọ mi wọle, on li a o gbà là, yio wọle, yio si jade, yio si ri koriko. Olè kì iwá bikoṣe lati jale, ati lati pa, ati lati parun: emi wá ki nwọn le ni ìye, ani ki nwọn le ni i lọpọlọpọ. Emi ni oluṣọ-agutan rere: oluṣọ-agutan rere fi ẹmí rẹ̀ lelẹ nitori awọn agutan. Ṣugbọn alagbaṣe, ti kì iṣe oluṣọ-agutan, ẹniti awọn agutan kì iṣe tirẹ̀, o ri ikõkò mbọ̀, o si fi awọn agutan silẹ, o si sá lọ: ikõkò si mu awọn agutan, o si fọn wọn ká kiri. Alagbaṣe sá lọ nitoriti iṣe alagbaṣe, kò si náni awọn agutan. Emi ni oluṣọ-agutan rere, mo si mọ̀ awọn temi, awọn temi si mọ̀ mi. Gẹgẹ bi Baba ti mọ̀ mi, ti emi si mọ̀ Baba; mo si fi ẹmí mi lelẹ nitori awọn agutan. Emi si ní awọn agutan miran, ti kì iṣe ti agbo yi: awọn li emi kò le ṣe alaimu wá pẹlu, nwọn ó si gbọ ohùn mi; nwọn o si jẹ agbo kan, oluṣọ-agutan kan. Nitorina ni Baba mi ṣe fẹran mi, nitoriti mo fi ẹmí mi lelẹ, ki emi ki o le tún gbà a. Ẹnikan kò gbà a lọwọ mi, ṣugbọn mo fi i lelẹ fun ara mi. Mo li agbara lati fi i lelẹ, mo si li agbara lati tún gbà a. Aṣẹ yi ni mo ti gbà lati ọdọ Baba mi wá.
Joh 10:1-18 Yoruba Bible (YCE)
“Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé ẹni tí kò bá gba ẹnu-ọ̀nà wọ àgbàlá ilé tí àwọn aguntan ń sùn sí, ṣugbọn tí ó bá fo ìgànná wọlé, olè ati ọlọ́ṣà ni. Ṣugbọn ẹni tí ó bá gba ẹnu ọ̀nà wọlé ni olùṣọ́-aguntan. Òun ni olùṣọ́nà ń ṣí ìlẹ̀kùn fún. Àwọn aguntan a máa gbọ́ ohùn rẹ̀, a sì máa pe àwọn aguntan rẹ̀ ní orúkọ, a máa kó wọn lọ jẹ. Nígbà tí gbogbo àwọn aguntan rẹ̀ bá jáde, a máa lọ níwájú wọn, àwọn aguntan a sì tẹ̀lé e nítorí wọ́n mọ ohùn rẹ̀. Aguntan kò jẹ́ tẹ̀lé àlejò, sísá ni wọ́n máa ń sá fún un, nítorí wọn kò mọ ohùn àlejò.” Òwe yìí ni Jesu fi bá wọn sọ̀rọ̀, ṣugbọn ohun tí ó ń bá wọn sọ kò yé wọn. Jesu tún sọ pé, “Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé, èmi ni ìlẹ̀kùn àwọn aguntan. Olè ati ọlọ́ṣà ni gbogbo àwọn tí wọ́n ti wá ṣiwaju mi. Ṣugbọn àwọn aguntan kò gbọ́ ti wọn. Èmi ni ìlẹ̀kùn. Ẹnikẹ́ni tí ó bá gba ọ̀dọ̀ mi wọlé yóo rí ìgbàlà, yóo máa wọlé, yóo máa jáde, yóo sì máa rí oúnjẹ jẹ. Olè kì í wá lásán, àfi kí ó wá jalè, kí ó wá pa eniyan, kí ó sì wá ba nǹkan jẹ́. Èmi wá kí eniyan lè ní ìyè, kí wọn lè ní i lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́. “Èmi ni olùṣọ́-aguntan rere. Gẹ́gẹ́ bí olùṣọ́-aguntan rere, mo ṣetán láti kú nítorí àwọn aguntan. Alágbàṣe tí kì í ṣe olùṣọ́-aguntan, tí kì í sìí ṣe olówó aguntan, bí ó bá rí ìkookò tí ń bọ̀, a fi àwọn aguntan sílẹ̀, a sálọ. Ìkookò a gbé ninu àwọn aguntan lọ, a sì tú wọn ká, nítorí alágbàṣe lásán ni, kò bìkítà fún àwọn aguntan. Èmi ni olùṣọ́-aguntan rere. Mo mọ àwọn tèmi, àwọn tèmi náà sì mọ̀ mí, gẹ́gẹ́ bí Baba ti mọ̀ mí, tí èmi náà sì mọ Baba. Mo ṣetán láti kú nítorí àwọn aguntan. Mo tún ní àwọn aguntan mìíràn tí kò sí ninu agbo yìí. Mo níláti dà wọ́n wá. Wọn yóo gbọ́ ohùn mi. Wọn yóo wá di agbo kan lábẹ́ olùṣọ́-aguntan kan. “Ìdí rẹ̀ nìyí tí Baba fi fẹ́ràn mi nítorí mo ṣetán láti kú, kí n lè tún wà láàyè. Ẹnikẹ́ni kò gba ẹ̀mí mi, ṣugbọn èmi fúnra mi ni mo yọ̀ǹda rẹ̀. Mo ní àṣẹ láti yọ̀ǹda rẹ̀, mo ní àṣẹ láti tún gbà á pada. Àṣẹ yìí ni mo rí gbà láti ọ̀dọ̀ Baba mi.”
Joh 10:1-18 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
“Lóòótọ́, lóòótọ́ ni mo wí fún yín, Ẹni tí kò bá gba ẹnu-ọ̀nà wọ inú agbo àgùntàn, ṣùgbọ́n tí ó bá gba ibòmíràn gun òkè, òun náà ni olè àti ọlọ́ṣà. Ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá ti ẹnu-ọ̀nà wọlé, Òun ni olùṣọ́ àwọn àgùntàn. Òun ni aṣọ́nà yóò ṣílẹ̀kùn fún; àwọn àgùntàn gbọ́ ohùn rẹ̀: ó sì pe àwọn àgùntàn tirẹ̀ lórúkọ, ó sì ṣe amọ̀nà wọn jáde. Nígbà tí ó bá sì ti mú àwọn àgùntàn tirẹ̀ jáde, yóò síwájú wọn, àwọn àgùntàn yóò sì máa tọ̀ ọ́ lẹ́yìn: nítorí tí wọ́n mọ ohùn rẹ̀. Wọn kò jẹ́ tọ àlejò lẹ́yìn, ṣùgbọ́n wọn a sá kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀: nítorí tí wọn kò mọ ohùn àlejò.” Òwe yìí ni Jesu pa fún wọn: ṣùgbọ́n òye ohun tí nǹkan wọ̀nyí tí ó ń sọ fún wọn kò yé wọn. Nítorí náà Jesu tún wí fún wọn pé, “Lóòótọ́, lóòótọ́ ni mo wí fún yín, Èmi ni ìlẹ̀kùn àwọn àgùntàn. Olè àti ọlọ́ṣà ni gbogbo àwọn tí ó ti wà ṣáájú mi: ṣùgbọ́n àwọn àgùntàn kò gbọ́ tiwọn. Èmi ni ìlẹ̀kùn: bí ẹnìkan bá bá ọ̀dọ̀ mi wọlé, òun ni a ó gbàlà, yóò wọlé, yóò sì jáde, yóò sì rí koríko. Olè kì í wá bí kò ṣe láti jalè, láti pa, àti láti parun: èmi wá kí wọn lè ní ìyè, àní kí wọn lè ní i lọ́pọ̀lọpọ̀. “Èmi ni olùṣọ́-àgùntàn rere: olùṣọ́-àgùntàn rere fi ọkàn rẹ̀ lélẹ̀ nítorí àwọn àgùntàn. Ṣùgbọ́n alágbàṣe, tí kì í ṣe olùṣọ́-àgùntàn, ẹni tí àwọn àgùntàn kì í ṣe tirẹ̀, ó rí ìkookò ń bọ̀, ó sì fi àgùntàn sílẹ̀, ó sì fọ́n wọn ká kiri. Òun sálọ nítorí tí ó jẹ́ alágbàṣe, kò sì náání àwọn àgùntàn. “Èmi ni olùṣọ́-àgùntàn rere, mo sì mọ àwọn tèmi, àwọn tèmi sì mọ̀ mí. Gẹ́gẹ́ bí Baba ti mọ̀ mí, tí èmi sì mọ Baba; mo sì fi ọkàn mi lélẹ̀ nítorí àwọn àgùntàn. Èmi sì ní àwọn àgùntàn mìíràn, tí kì í ṣe agbo yìí: àwọn ni èmi yóò mú wá pẹ̀lú, wọn yóò sì gbọ́ ohùn mi; wọn ó sì jẹ́ agbo kan, olùṣọ́-àgùntàn kan. Nítorí náà ni Baba mi ṣe fẹ́ràn mi, nítorí tí mo fi ẹ̀mí mi lélẹ̀, kí èmi lè tún gbà á. Ẹnìkan kò gbà á lọ́wọ́ mi, ṣùgbọ́n mo fi í lélẹ̀, mo sì lágbára láti tún gbà á. Àṣẹ yìí ni mo ti gbà wá láti ọ̀dọ̀ Baba mi.”