Joh 1:43-50
Joh 1:43-50 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ni ọjọ keji Jesu nfẹ jade lọ si Galili, o si ri Filippi, o si wi fun u pe, Mã tọ̀ mi lẹhin. Ara Betsaida ni Filippi iṣe, ilu Anderu ati Peteru. Filippi ri Natanaeli, o si wi fun u pe, Awa ti ri ẹniti Mose ninu ofin ati awọn woli ti kọwe rẹ̀, Jesu ti Nasareti, ọmọ Josefu. Natanaeli si wi fun u pe, Ohun rere kan ha le ti Nasareti jade? Filippi wi fun u pe, Wá wò o. Jesu ri Natanaeli mbọ̀ wá sọdọ rẹ̀, o si wi nipa rẹ̀ pe, Wo o, ọmọ Israelì nitõtọ, ninu ẹniti ẹ̀tan kò si! Natanaeli wi fun u pe, Nibo ni iwọ ti mọ̀ mi? Jesu dahùn, o si wi fun u pe, Ki Filippi to pè ọ, nigbati iwọ wà labẹ igi ọ̀pọ́tọ, mo ti ri ọ. Natanaeli dahùn, o si wi fun u pe, Rabbi, iwọ li Ọmọ Ọlọrun; iwọ li Ọba Israeli. Jesu dahùn, o si wi fun u pe, Nitori mo wi fun ọ pe, mo ri ọ labẹ igi ọpọtọ ni iwọ ṣe gbagbọ? iwọ ó ri ohun ti o pọ̀ju wọnyi lọ.
Joh 1:43-50 Yoruba Bible (YCE)
Ní ọjọ́ keji, bí Jesu ti fẹ́ máa lọ sí ilẹ̀ Galili, ó rí Filipi. Ó sọ fún un pé, “Máa tẹ̀lé mi.” Ará Bẹtisaida, ìlú Anderu ati ti Peteru, ni Filipi. Filipi wá rí Nataniẹli, ó wí fún un pé, “Àwa ti rí ẹni tí Mose kọ nípa rẹ̀ ninu Ìwé Òfin, tí àwọn wolii tún kọ nípa rẹ̀, Jesu ọmọ Josẹfu ará Nasarẹti.” Nataniẹli bi í pé, “Ṣé nǹkan rere kan lè ti Nasarẹti wá?” Filipi dá a lóhùn pé, “Wá wò ó.” Jesu rí Nataniẹli bí ó ti ń bọ̀ wá sọ́dọ̀ rẹ̀, ó sọ nípa rẹ̀ pé, “Wo ọmọlúwàbí, ọmọ Israẹli tí kò ní ẹ̀tàn ninu.” Nataniẹli bi í pé, “Níbo ni o ti mọ̀ mí?” Jesu dá a lóhùn pé, “Kí Filipi tó pè ọ́, nígbà tí o wà ní abẹ́ igi ọ̀pọ̀tọ́, mo ti rí ọ.” Nataniẹli wí fún un pé, “Olùkọ́ni, ìwọ ni ọmọ Ọlọrun, ìwọ ni ọba Israẹli.” Jesu wí fún un pé, “Nítorí mo wí fún ọ pé mo rí ọ ní abẹ́ igi ọ̀pọ̀tọ́ ni o ṣe gbàgbọ́? Ìwọ yóo rí ohun tí ó jù yìí lọ.”
Joh 1:43-50 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ní ọjọ́ kejì Jesu ń fẹ́ jáde lọ sí Galili, ó sì rí Filipi, ó sì wí fún un pé, “Máa tọ̀ mí lẹ́yìn.” Filipi gẹ́gẹ́ bí i Anderu àti Peteru, jẹ́ ará ìlú Betisaida. Filipi rí Natanaeli, ó sì wí fún un pé, “Àwa ti rí ẹni náà tí Mose kọ nípa rẹ̀ nínú òfin àti ẹni tí àwọn wòlíì ti kọ̀wé rẹ̀—Jesu ti Nasareti, ọmọ Josẹfu.” Natanaeli béèrè pé, “Nasareti? Ohun rere kan ha lè ti ibẹ̀ jáde?” Filipi wí fún un pé, “Wá wò ó.” Jesu rí Natanaeli ń bọ̀ wá sọ́dọ̀ rẹ̀, ó sì wí nípa rẹ̀ pé, “Èyí ni ọmọ Israẹli tòótọ́, nínú ẹni tí ẹ̀tàn kò sí.” Natanaeli béèrè pé, “Báwo ni ìwọ ti ṣe mọ̀ mí?” Jesu sì dáhùn pé, “Èmi rí ọ nígbà tí ìwọ wà lábẹ́ igi ọ̀pọ̀tọ́ kí Filipi tó pè ọ́.” Nígbà náà ni Natanaeli sọ ọ́ gbangba pé, “Rabbi, ìwọ ni ọmọ Ọlọ́run; Ìwọ ni ọba Israẹli.” Jesu sì wí fún un pé, “Ìwọ gbàgbọ́ nítorí mo wí fún ọ pé mo rí ọ lábẹ́ igi ọ̀pọ̀tọ́. Ìwọ ó rí ohun tí ó pọ̀jù ìwọ̀nyí lọ.”