Joh 1:29-34
Joh 1:29-34 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ni ijọ keji Johanu ri Jesu mbọ̀ wá sọdọ rẹ̀; o wipe, Wò o, Ọdọ-agutan Ọlọrun, ẹniti o kó ẹ̀ṣẹ aiye lọ! Eyi li ẹniti mo ti wipe, ọkunrin kan mbọ̀ wá lẹhin mi, ẹniti o pọ̀ju mi lọ: nitoriti o ti wà ṣiwaju mi. Emi kò si mọ̀ ọ: ṣugbọn ki a le fi i hàn fun Israeli, nitorina li emi ṣe wá ti mo nfi omi baptisi. Johanu si jẹri, o wipe, mo ri Ẹmi sọkalẹ lati ọrun wá bi àdaba, o si bà le e. Emi kò si mọ̀ ọ: ṣugbọn ẹniti o rán mi wá, lati fi omi baptisi, on na li o wi fun mi pe, Lori ẹniti iwọ ba ri, ti Ẹmí sọkalẹ si, ti o si bà le e, on na li ẹniti nfi Ẹmí Mimọ́ baptisi. Emi si ti ri, emi si ti njẹri pe, Eyi li Ọmọ Ọlọrun.
Joh 1:29-34 Yoruba Bible (YCE)
Ní ọjọ́ keji, Johanu rí Jesu tí ó ń bọ̀ wá sọ́dọ̀ rẹ̀, ó ní, “Wo ọ̀dọ́ aguntan Ọlọrun, tí ó kó ẹ̀ṣẹ̀ aráyé lọ. Òun ni mo sọ nípa rẹ̀ pé, ‘Ẹnìkan ń bọ̀ lẹ́yìn mi, ẹni tí ó jù mí lọ, nítorí ó ti wà kí á tó bí mi.’ Èmi alára kò mọ̀ ọ́n, ṣugbọn kí á lè fi í han Israẹli ni mo ṣe wá, tí mò ń fi omi ṣe ìwẹ̀mọ́.” Johanu tún jẹ́rìí pé, “Mo ti rí Ẹ̀mí tí ó sọ̀kalẹ̀ bí àdàbà láti ọ̀run tí ó bà lé e, tí ó sì ń bá a gbé. Èmi alára kò mọ̀ ọ́n, ṣugbọn ẹni tí ó rán mi láti máa ṣe ìrìbọmi ti sọ fún mi pé, ẹni tí mo bá rí tí Ẹ̀mí bá sọ̀kalẹ̀ lé lórí, tí ó bá ń bá a gbé, òun ni ẹni tí ó ń fi Ẹ̀mí Mímọ́ ṣe ìwẹ̀mọ́. Mo ti rí i, mo wá ń jẹ́rìí pé òun ni Ọmọ Ọlọrun.”
Joh 1:29-34 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ní ọjọ́ kejì, Johanu rí Jesu tí ó ń bọ̀ wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀, ó sì wí pé, “Wò ó, Ọ̀dọ́-àgùntàn Ọlọ́run, ẹni tí ó kó ẹ̀ṣẹ̀ ayé lọ! Èyí ni ẹni tí mo ń sọ nígbà tí mo wí pé, ‘Ọkùnrin kan tí ń bọ̀ wá lẹ́yìn mi, tí ó pọ̀jù mí lọ, nítorí tí ó ti wà ṣáájú mi.’ Èmi gan an kò sì mọ̀ ọ́n, ṣùgbọ́n ìdí tí mo fi wá ń fi omi ṣe ìtẹ̀bọmi ni kí a lè fi í hàn fún Israẹli.” Nígbà náà ni Johanu jẹ́rìí sí i pé: “Mo rí Ẹ̀mí sọ̀kalẹ̀ láti ọ̀run wá bí àdàbà, tí ó sì bà lé e. Èmí kì bá tí mọ̀ ọ́n, bí kò ṣe pé ẹni tí ó rán mi láti fi omi bamitiisi sọ fún mi pé, ‘Ọkùnrin tí ìwọ rí tí Ẹ̀mí sọ̀kalẹ̀ tí ó bà lé lórí ni ẹni tí yóò fi Ẹ̀mí Mímọ́ bamitiisi.’ Èmi ti rí i, mo sì jẹ́rìí pé, èyí ni Ọmọ Ọlọ́run.”