Joh 1:13-14
Joh 1:13-14 Yoruba Bible (YCE)
A kò bí wọn bí eniyan ṣe ń bímọ nípa ìfẹ́ ara tabi ìfẹ́ eniyan, ṣugbọn nípa ìfẹ́ Ọlọrun ni a bí wọn. Ọ̀rọ̀ náà wá di eniyan, ó ń gbé ààrin wa, a rí ògo rẹ̀, ògo bíi ti Ọmọ bíbí kan ṣoṣo tí ó ti ọ̀dọ̀ Baba wá, tí ó kún fún oore-ọ̀fẹ́ ati òtítọ́.
Joh 1:13-14 Bibeli Mimọ (YBCV)
Awọn ẹniti a bí, kì iṣe nipa ti ẹ̀jẹ, tabi nipa ti ifẹ ara, bẹ̃ni kì iṣe nipa ifẹ ti enia, bikoṣe nipa ifẹ ti Ọlọrun. Ọ̀rọ na si di ara, on si mba wa gbé, (awa si nwò ogo rẹ̀, ogo bi ti ọmọ bíbi kanṣoṣo lati ọdọ Baba wá,) o kún fun ore-ọfẹ ati otitọ.
Joh 1:13-14 Yoruba Bible (YCE)
A kò bí wọn bí eniyan ṣe ń bímọ nípa ìfẹ́ ara tabi ìfẹ́ eniyan, ṣugbọn nípa ìfẹ́ Ọlọrun ni a bí wọn. Ọ̀rọ̀ náà wá di eniyan, ó ń gbé ààrin wa, a rí ògo rẹ̀, ògo bíi ti Ọmọ bíbí kan ṣoṣo tí ó ti ọ̀dọ̀ Baba wá, tí ó kún fún oore-ọ̀fẹ́ ati òtítọ́.
Joh 1:13-14 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Àwọn ọmọ tí kì í ṣe nípa ẹ̀jẹ̀, tàbí nípa ti ìfẹ́ ara, bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe nípa ìfẹ́ ti ènìyàn, bí kò ṣe láti ọwọ́ Ọlọ́run. Ọ̀rọ̀ náà sì di ara, òun sì ń bá wa gbé. Àwa sì ti rí ògo rẹ̀, àní ògo ọmọ rẹ kan ṣoṣo, tí ó ti ọ̀dọ̀ Baba wá, ó kún fún oore-ọ̀fẹ́ àti òtítọ́.