Joh 1:1-4
Joh 1:1-4 Bibeli Mimọ (YBCV)
LI àtetekọṣe li Ọ̀rọ wà, Ọ̀rọ si wà pẹlu Ọlọrun, Ọlọrun si li Ọ̀rọ na. On na li o wà li àtetekọṣe pẹlu Ọlọrun. Nipasẹ̀ rẹ̀ li a ti da ohun gbogbo; lẹhin rẹ̀ a ko si da ohun kan ninu ohun ti a da. Ninu rẹ̀ ni ìye wà; ìye na si ni imọlẹ̀ araiye.
Joh 1:1-4 Yoruba Bible (YCE)
Ní ìbẹ̀rẹ̀, kí á tó dá ayé, ni Ọ̀rọ̀ ti wà, Ọ̀rọ̀ wà pẹlu Ọlọrun, Ọlọrun sì ni Ọ̀rọ̀ náà. Òun ni ó wà pẹlu Ọlọrun ní ìbẹ̀rẹ̀, kí á tó dá ayé. Nípasẹ̀ rẹ̀ ni a ti dá ohun gbogbo, ninu gbogbo ohun tí a dá, kò sí ohun kan tí a dá lẹ́yìn rẹ̀. Òun ni orísun ìyè, ìyè náà ni ìmọ́lẹ̀ aráyé.
Joh 1:1-4 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ní àtètèkọ́ṣe ni Ọ̀rọ̀ wà, Ọ̀rọ̀ sì wà pẹ̀lú Ọlọ́run, Ọlọ́run sì ni Ọ̀rọ̀ náà. Òun ni ó sì wà pẹ̀lú Ọlọ́run ní àtètèkọ́ṣe. Nípasẹ̀ rẹ̀ ni a dá ohun gbogbo; lẹ́yìn rẹ̀ a kò sì dá ohun kan nínú ohun tí a ti dá. Nínú rẹ̀ ni ìyè wà, ìyè yìí náà sì ni ìmọ́lẹ̀ aráyé