Jer 6:13-14
Jer 6:13-14 Bibeli Mimọ (YBCV)
Lati kekere wọn titi de nla wọn, gbogbo wọn li o fi ara wọn fun ojukokoro, ati lati woli titi de alufa, gbogbo wọn ni nṣe eke. Nwọn si ti wo ọgbẹ ọmọbinrin enia mi fẹrẹ̀; nwọn wipe, Alafia! Alafia! nigbati kò si alafia.
Jer 6:13-14 Yoruba Bible (YCE)
OLUWA ní, “Láti orí àwọn mẹ̀kúnnù títí dé orí àwọn eniyan pataki pataki, gbogbo wọn ni wọ́n fẹ́ràn èrè àjẹjù; láti orí àwọn wolii títí dé orí àwọn alufaa, èké ni gbogbo wọn. Wọn kò wẹ egbò àwọn eniyan mi jiná, wọ́n ń kígbe pé: ‘Alaafia ni, alaafia ni’, nígbà tí kò sí alaafia.
Jer 6:13-14 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
“Láti orí ẹni tí ó kéré sí orí ẹni tí ó tóbi ju, gbogbo wọn ni ó sì ní ojúkòkòrò fún èrè, àwọn wòlíì àti àlùfáà lápapọ̀ sì kún fún ẹ̀tàn. Wọ́n sì ń wo ọgbẹ́ àwọn ènìyàn mi bí ẹni pé kò tó nǹkan. Wọ́n ń wí pé, ‘Àlàáfíà, Àlàáfíà,’ nígbà tí kò sì sí àlàáfíà.