Jer 40:3-4
Jer 40:3-4 Bibeli Mimọ (YBCV)
Oluwa si ti mu u wá, o si ṣe gẹgẹ bi o ti wi: nitoripe ẹnyin ti ṣẹ̀ si Oluwa, ẹ kò si gbọ́ ohùn rẹ̀, nitorina ni nkan yi ṣe de ba nyin. Njẹ nisisiyi, wò o, mo tú ọ silẹ li oni kuro ninu ẹ̀wọn ti o wà li ọwọ rẹ: bi o ba dara li oju rẹ lati ba mi lọ si Babeli, kalọ, emi o boju to ọ: ṣugbọn bi kò ba dara li oju rẹ lati ba mi lọ si Babeli, jọwọ rẹ̀; wò o, gbogbo ilẹ li o wà niwaju rẹ, ibi ti o ba dara ti o ba si tọ li oju rẹ lati lọ, lọ sibẹ.
Jer 40:3-4 Yoruba Bible (YCE)
Ó sì ti ṣe bí ó ti pinnu nítorí pé ẹ dẹ́ṣẹ̀ sí i, ẹ kò sì fetí sí ohùn rẹ̀, nítorí náà ni ibi ṣe dé ba yín. Nisinsinyii, wò ó, mo tú ṣẹ́kẹ́ṣẹkẹ̀ ọwọ́ rẹ sílẹ̀, bí o bá fẹ́ bá mi lọ sí Babiloni, máa bá mi kálọ, n óo tọ́jú rẹ dáradára; bí o kò bá sì fẹ́ lọ, dúró. Wò ó, gbogbo ilẹ̀ nìyí níwájú rẹ yìí, ibi tí o bá fẹ́ tí ó dára lójú rẹ ni kí o lọ.
Jer 40:3-4 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nísinsin yìí, OLúWA ti mú un jáde; ó ti ṣe gẹ́gẹ́ bí ó ti sọ pé òun yóò ṣe. Gbogbo èyí ṣẹlẹ̀ nítorí wí pé ẹ̀yin ènìyàn ṣẹ̀ sí OLúWA, àti pé ẹ kò gbọ́rọ̀ sí àṣẹ rẹ̀. Ṣùgbọ́n, ní òní yìí mò ń tú ọ sílẹ̀ kúrò nínú ẹ̀wọ̀n tí ó wà ní ọwọ́ rẹ. Bí o bá fẹ́, tẹ̀lé mi ká lọ sí Babeli, èmi yóò sì bojútó ọ; ṣùgbọ́n bí ìwọ kò bá fẹ́, dúró síbí. Wò ó, gbogbo orílẹ̀-èdè wà níwájú rẹ, lọ sí ibikíbi tí ó bá tẹ́ ọ lọ́rùn.”