Jer 4:1-2
Jer 4:1-2 Bibeli Mimọ (YBCV)
Israeli bi iwọ o ba yipada, li Oluwa wi, yipada sọdọ mi; ati bi iwọ o ba mu irira rẹ kuro niwaju mi, iwọ kì o si rìn kiri: Iwọ o si bura pe, Oluwa mbẹ ni otitọ, ni idajọ, ati ni ododo; ati nipasẹ rẹ̀ ni gbogbo orilẹ-ède yio fi ibukun fun ara wọn, nwọn o si ṣe ogo ninu rẹ̀.
Jer 4:1-2 Yoruba Bible (YCE)
OLUWA ní, “Ẹ̀yin ọmọ Israẹli, bí ẹ bá fẹ́ yipada, ọ̀dọ̀ mi ni kí ẹ pada sí. Mo kórìíra ìbọ̀rìṣà; nítorí náà bí ẹ bá jáwọ́ ninu rẹ̀, tí ẹ kò bá ṣìnà kiri mọ́, tí ẹ bá ń búra pẹlu òtítọ́ pé, ‘Bí OLUWA ti wà láàyè,’ lórí ẹ̀tọ́ ati òdodo, àwọn orílẹ̀-èdè yòókù yóo máa fi orúkọ mi súre fún ara wọn, wọn yóo sì máa ṣògo ninu mi.”
Jer 4:1-2 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
“Tí ìwọ yóò bá yí padà, Ìwọ Israẹli, padà tọ̀ mí wá,” ni OLúWA wí. “Tí ìwọ yóò bá sì mú ìríra rẹ kúrò níwájú mi, ìwọ kí ó sì rìn kiri. Tí ó bá jẹ́ lóòtítọ́ àti òdodo ni ìwọ búra. Nítòótọ́ bí OLúWA ti wà láààyè, nígbà náà ni orílẹ̀-èdè yóò di alábùkún fún nípasẹ̀ rẹ, àti nínú rẹ̀ ni wọn yóò ṣògo.”