Jer 38:9-10
Jer 38:9-10 Yoruba Bible (YCE)
“Kabiyesi, oluwa mi, gbogbo nǹkan tí àwọn eniyan wọnyi ṣe sí wolii Jeremaya kò dára. Inú kànga ni wọ́n jù ú sí, ebi ni yóo sì pa á sibẹ nítorí pé kò sí burẹdi ní ìlú mọ́.” Ọba bá pàṣẹ fún Ebedimeleki ará Etiopia, ó ní, “Mú eniyan mẹta lọ́wọ́, kí ẹ lọ yọ Jeremaya wolii kúrò ninu kànga náà kí ó tó kú.”
Jer 38:9-10 Bibeli Mimọ (YBCV)
Oluwa mi, ọba! awọn ọkunrin wọnyi ti ṣe ibi ni gbogbo eyi ti nwọn ti ṣe si Jeremiah woli pe, nwọn ti sọ ọ sinu iho; ebi yio si fẹrẹ pa a kú ni ibi ti o gbe wà: nitori onjẹ kò si mọ ni ilu. Nigbana ni ọba paṣẹ fun Ebedmeleki, ara Etiopia, wipe, Mu ọgbọ̀n enia lọwọ lati ihin lọ, ki o si fà Jeremiah soke lati inu iho, ki o to kú.
Jer 38:9-10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
“Olúwa mi ọba, àwọn ènìyàn wọ̀nyí ti ṣe ohun búburú sí Jeremiah wòlíì Ọlọ́run. Wọ́n ti gbé e sọ sínú kànga níbi tí kò sí oúnjẹ kankan nínú ìlú mọ́.” Nígbà náà ni ọba pàṣẹ fún Ebedimeleki ará Kuṣi pé, “Mú ọgbọ̀n ọkùnrin láti ibí pẹ̀lú rẹ, kí ẹ sì fa wòlíì Jeremiah sókè láti inú ihò, kí ó tó kú.”