Jer 32:37-41
Jer 32:37-41 Bibeli Mimọ (YBCV)
Wò o, emi o kó wọn jọ lati gbogbo ilẹ jade, nibiti emi ti le wọn si ninu ibinu mi, ati ninu irunu mi, ati ninu ikannu nla; emi o si jẹ ki nwọn ki o mã gbe lailewu: Nwọn o si jẹ enia mi, emi o si jẹ Ọlọrun wọn. Emi o si fun wọn li ọkàn kan, ati ọ̀na kan, ki nwọn ki o le bẹ̀ru mi li ọjọ gbogbo, fun rere wọn, ati ti awọn ọmọ wọn lẹhin wọn: Emi o si ba wọn dá majẹmu aiyeraiye, pe emi kì o yipada lẹhin wọn lati ṣe wọn ni rere, emi o fi ibẹ̀ru mi si ọkàn wọn, ti nwọn kì o lọ kuro lọdọ mi. Lõtọ, emi o yọ̀ lori wọn lati ṣe wọn ni rere, emi o si gbìn wọn si ilẹ yi li otitọ tinutinu mi ati tọkàntọkàn mi.
Jer 32:37-41 Yoruba Bible (YCE)
n óo kó àwọn eniyan ibẹ̀ jọ láti gbogbo orílẹ̀-èdè tí mo ti fi ibinu, ìrúnú, ati ìkanra lé wọn lọ; n óo kó wọn pada sí ibí yìí, n óo sì mú kí wọn máa gbé ní àìléwu. Wọn yóo máa jẹ́ eniyan mi, Èmi náà óo sì máa jẹ́ Ọlọrun wọn. N óo fún wọn ní ọkàn ati ẹ̀mí kan, kí wọn lè máa bẹ̀rù mi nígbà gbogbo, kí ó lè dára fún àwọn ati àwọn ọmọ wọn lẹ́yìn wọn. N óo bá wọn dá majẹmu ayérayé, pé n kò ní dẹ́kun ati máa ṣe wọ́n lóore. N óo fi ẹ̀rù mi sí wọn lọ́kàn, kí wọn má baà yapa kúrò lọ́dọ̀ mi mọ́. Yóo máa jẹ́ ohun ayọ̀ fún mi láti ṣe wọ́n lóore, n óo fi tẹ̀mítẹ̀mí ati tọkàntọkàn fi ìdí wọn múlẹ̀ ninu jíjẹ́ olóòótọ́ ní ilẹ̀ yìí.
Jer 32:37-41 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Èmi ó kó wọn jọ láti gbogbo ilẹ̀ tí mo ti lé wọn kúrò ní ìgbà ìbínú àti ìkáàánú ńlá mi. Èmi yóò mú wọn padà wá sí ilẹ̀ yìí; èmi ó sì jẹ́ kí wọn ó máa gbé láìléwu. Wọn yóò jẹ́ ènìyàn mi, èmi yóò sì jẹ́ Ọlọ́run wọn. Èmi ó fún wọn ní ọkàn kan àti ìṣe kí wọn kí ó lè máa bẹ̀rù mi fún rere wọn àti fún rere àwọn ọmọ wọn tí ó tẹ̀lé wọn. Èmi ò bá wọn dá májẹ̀mú ayérayé, èmi kò ní dúró láti ṣe rere fún wọn: Èmi ó sì jẹ́ kí wọ́n bẹ̀rù mi, wọn kì yóò sì padà lẹ́yìn mi. Lóòtítọ́, èmi ó yọ̀ nípa ṣíṣe wọ́n ní rere, èmi ó sì fi dá wọn lójú nípa gbígbìn wọ́n sí ilẹ̀ yìí tọkàntọkàn mi.