Jer 32:17-19
Jer 32:17-19 Bibeli Mimọ (YBCV)
A! Oluwa Ọlọrun! wò o, iwọ ti o da ọrun on aiye nipa agbara nla rẹ ati ninà apa rẹ: kò si ohun-kohun ti o ṣoro fun ọ. Iwọ ṣe ãnu fun ẹgbẹgbẹrun, o si san aiṣedede awọn baba si aiya awọn ọmọ lẹhin wọn: Ọlọrun titobi, Alagbara! Oluwa awọn ọmọ-ogun li orukọ rẹ̀. Titobi ni igbimọ, ati alagbara ni iṣe; oju rẹ ṣí si gbogbo ọ̀na awọn ọmọ enia: lati fi fun olukuluku gẹgẹ bi ọ̀na rẹ̀ ati gẹgẹ bi eso iṣe rẹ̀
Jer 32:17-19 Yoruba Bible (YCE)
‘OLUWA, Ọlọrun! Ìwọ tí o dá ọ̀run ati ayé pẹlu agbára ńlá ati ipá rẹ! Kò sí ohun tí ó ṣòro fún ọ, ìwọ tí ò ń fi ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ hàn fún ẹgbẹẹgbẹrun eniyan, ṣugbọn tí ò ń gba ẹ̀san àwọn baba lára àwọn ọmọ wọn lẹ́yìn ikú wọn, ìwọ Ọlọrun alágbára ńlá tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ OLUWA àwọn ọmọ ogun, ìwọ Olùdámọ̀ràn ńlá, tí ó lágbára ní ìṣe; ìwọ tí ojú rẹ ń rí sí gbogbo ọ̀nà àwọn ọmọ eniyan, tí o sì ń san ẹ̀san fún olukuluku gẹ́gẹ́ bí ìwà ati iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀
Jer 32:17-19 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
“Háà! OLúWA Olódùmarè, ìwọ tí o dá ọ̀run àti ayé pẹ̀lú títóbi agbára rẹ àti gbogbo ọ̀rọ̀ apá rẹ. Kò sí ohun tí ó ṣòro fún ọ láti ṣe. O fi ìfẹ́ hàn sí ẹgbẹgbẹ̀rún àwọn ènìyàn, ṣùgbọ́n o gbé ìyà ẹ̀ṣẹ̀ àwọn baba lé àwọn ọmọ lẹ́yìn wọn. Ọlọ́run títóbi àti alágbára, OLúWA àwọn ọmọ-ogun ni orúkọ rẹ. Títóbi ni ìgbìmọ̀, àti alágbára ní í ṣe, ojú rẹ̀ ṣì sí gbogbo ọ̀nà àwọn ọmọ ènìyàn; láti fi fún olúkúlùkù gẹ́gẹ́ ọ̀nà rẹ̀ àti gẹ́gẹ́ bí èso iṣẹ́ rẹ̀.