Jer 25:8-11
Jer 25:8-11 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nitorina, bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi: nitori ti ẹnyin kò gbọ́ ọ̀rọ mi. Sa wò o, emi o ranṣẹ, emi o si mu gbogbo idile orilẹ-ède ariwa wá, li Oluwa wi, emi o si ranṣẹ si Nebukadnessari, ọba Babeli, ọmọ-ọdọ mi, emi o si mu wọn wá si ilẹ yi, ati olugbe rẹ̀, ati si gbogbo awọn orilẹ-ède yikakiri, emi o si pa wọn patapata, emi o si sọ wọn di iyanu ati iyọṣuti si, ati ahoro ainipẹkun. Pẹlupẹlu emi o mu ohùn inudidùn, ati ohùn ayọ, ohùn ọkọ-iyawo, ati ohùn iyawo, iro okuta ọlọ, ati imọlẹ fitila kuro lọdọ wọn. Gbogbo ilẹ yi yio si di iparun ati ahoro: orilẹ-ède wọnyi yio si sìn ọba Babeli li ãdọrin ọdun.
Jer 25:8-11 Yoruba Bible (YCE)
Ó ní, “Nítorí pé ẹ kò gbọ́ràn sí mi lẹ́nu, n óo ranṣẹ lọ kó gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè àríwá wá. N óo ranṣẹ sí Nebukadinesari ọba Babiloni, iranṣẹ mi, n óo jẹ́ kí wọn wá dó ti ilẹ̀ yìí, ati àwọn tí ń gbé ibẹ̀. Gbogbo orílẹ̀-èdè tí ó wà ní agbègbè ilẹ̀ yìí ni n óo parun patapata, tí n óo sọ di àríbẹ̀rù, ati àrípòṣé, ati ohun ẹ̀gàn títí lae. N óo pa ìró ayọ̀ ati ẹ̀rín rẹ́ láàrin wọn, ẹnìkan kò sì ní gbọ́ ohùn ọkọ iyawo ati ohùn iyawo tuntun mọ́. A kò ní gbọ́ ìró ọlọ mọ́, bẹ́ẹ̀ ni kò ní sí iná fìtílà mọ́. Gbogbo ilẹ̀ yìí yóo di àlàpà ati aṣálẹ̀. Àwọn orílẹ̀-èdè wọnyi yóo sì sin ọba Babiloni fún aadọrin ọdún.
Jer 25:8-11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nítorí náà, Ọlọ́run alágbára sọ èyí: “Nítorí wí pé ẹ̀yin kò fetí sí ọ̀rọ̀ mi, Èmi yóò pe gbogbo àwọn ènìyàn àríwá, àti ìránṣẹ́ mi Nebukadnessari ọba Babeli,” ni OLúWA wí. “Èmi yóò sì mú wọn dìde lòdì sí ilẹ̀ náà àti àwọn olùgbé rẹ̀ àti sí gbogbo orílẹ̀-èdè àyíká rẹ̀. Èmi yóò pa wọ́n run pátápátá, Èmi yóò sọ wọ́n di nǹkan ẹ̀rù àti yẹ̀yẹ́ àti ìparun ayérayé. Èmi yóò sì mú ìró ayọ̀ àti inú dídùn kúrò lọ́dọ̀ wọn; ohùn ìyàwó àti ọkọ ìyàwó, ìró ọlọ òkúta àti ìmọ́lẹ̀ fìtílà. Gbogbo orílẹ̀-èdè yìí yóò sì di ahoro, orílẹ̀-èdè yìí yóò sì sìn ọba Babeli ní àádọ́rin ọdún.